Mak 6:30-46

Mak 6:30-46 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Àwọn aposteli kó ara wọn jọ sí ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n sí ròyìn ohun gbogbo tí wọ́n ti ṣe àti ohun gbogbo tí wọ́n ti kọ́ni. Nígbà tí Jesu rí i pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ń lọ tí wọ́n sì ń bọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí kò sí ààyè fún wọn láti jẹun, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí a kúrò láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn wọ̀nyí fún ìgbà díẹ̀, kí a sì sinmi.” Nítorí náà, wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi kúrò níbẹ̀ lọ sí ibi tí ó parọ́rọ́. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ènìyàn ni o rí wọn nígbà tí wọ́n ń lọ. Àwọn wọ̀nyí sì tún wá láti ìlú ńlá gbogbo wọn sáré gba etí Òkun, wọ́n ṣáájú wọn gúnlẹ̀ ní èbúté. Bí Jesu ti ń sọ̀kalẹ̀ láti inú ọkọ̀ náà, ó bá ọ̀pọ̀ ènìyàn bí i tí àtẹ̀yìnwá, tí wọ́n ti ń dúró dè e. Ó káàánú fún wọn, nítorí wọ́n dàbí àgùntàn tí kò ní olùtọ́jú. Ó sì kọ́ wọn ni ọ̀pọ̀ nǹkan tí ó yẹ kí wọ́n mọ̀. Nígbà tí ọjọ́ sì ti bù lọ tán, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n wí fún un pé, ibi aṣálẹ̀ ni ìbí yìí, ọjọ́ sì bù lọ tán. “Rán àwọn ènìyàn wọ̀nyí láti lọ sí àwọn abúlé àti ìlú láti ra oúnjẹ fún ara wọn.” Ṣùgbọ́n Jesu sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ fún wọn ní oúnjẹ.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wí fún pé, “Èyí yóò ná wa tó owó iṣẹ́ ọya oṣù mẹ́jọ, Ṣe kí a lọ fi èyí ra àkàrà fún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn yìí láti jẹ.” Jesu tún béèrè pé, “Ìṣù àkàrà mélòó ni ẹ̀yin ni lọ́wọ́? Ẹ lọ wò ó.” Wọ́n padà wá jíṣẹ́ pé, “Ìṣù àkàrà márùn-ún àti ẹja méjì.” Nígbà náà ni Jesu sọ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn náà kí a mú wọn jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ lórí koríko. Lẹ́sẹ̀kan náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jókòó, ní àádọ́ta tàbí ọgọọgọ́rùn-ún. Nígbà tí ó sì mú ìṣù àkàrà márùn-ún àti ẹja méjì náà, ó gbé ojú rẹ̀ sókè ọ̀run. Ó dúpẹ́ fún oúnjẹ náà, ó bù wọ́n sí wẹ́wẹ́, ó fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti gbé e kalẹ̀ síwájú àwọn ènìyàn náà àti àwọn ẹja méjì náà ni ó pín fún gbogbo wọn. Gbogbo wọn sì jẹ àjẹyó. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì kó agbọ̀n méjìlá tí ó kún fún àjẹkù àkàrà àti ti ẹja pẹ̀lú. Àwọn tí ó sì jẹ́ àkàrà náà tó ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọkùnrin. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn èyí, Jesu pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti padà sínú ọkọ̀ kí wọn sì ṣáájú rékọjá sí Betisaida. Níbẹ̀ ni òun yóò ti wà pẹ̀lú wọn láìpẹ́. Nítorí òun fúnra a rẹ̀ yóò dúró sẹ́yìn láti rí i pé àwọn ènìyàn túká lọ ilé wọn. Lẹ́yìn náà, ó lọ sórí òkè láti lọ gbàdúrà.

Mak 6:30-46 Bibeli Mimọ (YBCV)

Awọn aposteli si kó ara wọn jọ sọdọ Jesu, nwọn si ròhin ohungbogbo ti nwọn ti ṣe fun u, ati ohungbogbo ti nwọn ti kọni. O si wi fun wọn pe, Ẹ wá ẹnyin tikaranyin si ibi ijù li apakan, ki ẹ si simi diẹ: nitori ọ̀pọlọpọ li awọn ti nwá ti nwọn si nlọ, nwọn kò tilẹ ri ãye tobẹ̃ ti nwọn iba fi jẹun. Nwọn si ba ti ọkọ̀ lọ si ibi ijù awọn nikan. Awọn enia si ri wọn nigbati nwọn nlọ, ọ̀pọlọpọ si mọ̀ ọ, nwọn si sare ba ti ẹsẹ lọ sibẹ̀ lati ilu nla gbogbo wá, nwọn si ṣiwaju wọn, nwọn si jùmọ wá sọdọ rẹ̀. Nigbati Jesu jade, o ri ọ̀pọ enia, ãnu wọn ṣe e, nitoriti nwọn dabi awọn agutan ti kò li oluṣọ: o si bẹ̀rẹ si ima kọ́ wọn li ohun pipọ. Nigbati ọjọ si bù lọ tan, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ tọ̀ ọ wá, wipe, Ibi ijù li eyi, ọjọ si bù lọ tan: Rán wọn lọ, ki nwọn ki o le lọ si àgbegbe ilu, ati si iletò ti o yiká, ki nwọn ki o le rà onjẹ fun ara wọn: nitoriti nwọn kò li ohun ti nwọn o jẹ. Ṣugbọn o dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹ fun wọn li onjẹ. Nwọn si wi fun u pe, Awa o ha lọ irà akara igba owo idẹ ki a si fifun wọn jẹ? O si wi fun wọn pe, Iṣu akara melo li ẹnyin ni? Ẹ lọ wò o. Nigbati nwọn si mọ̀, nwọn wipe, Marun, pẹlu ẹja meji. O si wi fun wọn pe, ki nwọn ki o mu gbogbo wọn joko li ẹgbẹgbẹ lori koriko. Nwọn si joko li ẹgbẹgbẹ li ọrọrun ati li aradọta. Nigbati o si mu iṣu akara marun ati ẹja meji na, o gbé oju soke, o si sure, o si bù iṣu akara na, o si fifun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ki nwọn ki o gbé e kalẹ niwaju wọn; ati awọn ẹja meji na li o si pín fun gbogbo wọn. Gbogbo wọn si jẹ, nwọn si yó. Nwọn si kó agbọ̀n mejila kún fun ajẹkù, ati ti ẹja pẹlu. Awọn ti o si jẹ ìṣu akara na to iwọn ẹgbẹdọgbọn ọkunrin. Lojukanna li o si rọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lati bọ sinu ọkọ̀, ki nwọn ki o si ṣiwaju lọ si apa keji si Betsaida, nigbati on tikararẹ̀ tú awọn enia ká. Nigbati o si rán wọn lọ tan, o gùn ori òke lọ igbadura.

Mak 6:30-46 Yoruba Bible (YCE)

Àwọn aposteli Jesu pé jọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n ròyìn gbogbo nǹkan tí wọ́n ti ṣe ati bí wọ́n ti kọ́ àwọn eniyan. Ó bá wí fún wọn pé, “Ẹ wá kí á lọ sí ibìkan níkọ̀kọ̀, níbi tí kò sí eniyan, kí ẹ sinmi díẹ̀.” Nítorí ọpọlọpọ eniyan ni wọ́n ń lọ, tí wọn ń bọ̀, tóbẹ́ẹ̀ tí kò fi sí àyè láti jẹun. Wọ́n bá bọ́ sinu ọkọ̀ ojú omi kan, wọ́n fẹ́ yọ́ lọ sí ibi tí kò sí eniyan. Ṣugbọn ọpọlọpọ eniyan rí wọn bí wọ́n ti ń lọ, wọ́n mọ̀ wọ́n, wọ́n bá fi ẹsẹ̀ rìn, wọ́n sáré láti inú gbogbo ìlú wọn lọ sí ibi tí ọkọ̀ darí sí, wọ́n sì ṣáájú wọn dé ibẹ̀. Nígbà tí Jesu jáde ninu ọkọ̀ ó rí ọpọlọpọ eniyan, àánú ṣe é nítorí wọ́n dàbí aguntan tí kò ní olùṣọ́. Ó bá bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn ní ọpọlọpọ nǹkan. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá, wọ́n wí fún un pé, “Aṣálẹ̀ nìhín yìí, ilẹ̀ sì ń ṣú lọ. Jẹ́ kí àwọn eniyan túká, kí wọn lè lọ sí àwọn abà ati abúlé tí ó wà yíká láti ra oúnjẹ fún ara wọn.” Ṣugbọn Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni kí ẹ fún wọn ní ohun tí wọn óo jẹ.” Wọ́n ní, “Ṣé kí á wá lọ ra oúnjẹ igba owó fadaka ni, kí a lè fún wọn jẹ!” Ó bi wọ́n pé, “Ìba oúnjẹ wo ni ẹ ní? Ẹ lọ wò ó.” Lẹ́yìn tí wọ́n wádìí, wọ́n ní “Burẹdi marun-un ni ati ẹja meji.” Ó bá pàṣẹ fún wọn kí gbogbo àwọn eniyan jókòó ní ìṣọ̀wọ́, ìṣọ̀wọ́ lórí koríko. Wọ́n bá jókòó lọ́wọ̀ọ̀wọ́, ní ọgọọgọrun-un ati ní aadọtọọta. Jesu bá mú burẹdi marun-un ati ẹja meji náà, ó gbé ojú sókè ọ̀run, ó dúpẹ́. Ó bá bu burẹdi náà, ó fi fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kí wọn pín in fún àwọn eniyan. Bẹ́ẹ̀ náà ni ó pín ẹja meji náà fún gbogbo wọn. Gbogbo wọn jẹ, wọ́n yó. Wọ́n bá kó àjẹkù burẹdi ati ẹja jọ, ó kún agbọ̀n mejila. Iye àwọn ọkunrin tí ó jẹ oúnjẹ náà jẹ́ ẹgbẹẹdọgbọn (5000). Lẹsẹkẹsẹ ó ní kí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ ọkọ̀ ojú omi, kí wọn ṣiwaju rẹ̀ lọ sí òdìkejì òkun ní agbègbè Bẹtisaida. Lẹ́yìn náà ó ní kí àwọn eniyan túká. Nígbà tí ó ti dágbére fún wọn, ó lọ sí orí òkè, ó lọ gbadura.