Mak 6:17-29

Mak 6:17-29 Bibeli Mimọ (YBCV)

Herodu tikararẹ̀ sá ti ranṣẹ mu Johanu, o si dè e sinu tubu nitori Herodia, aya Filippi arakunrin rẹ̀: on sá ti fi i ṣe aya. Johanu sá ti wi fun Herodu pe, kò tọ́ fun iwọ lati ni aya arakunrin rẹ. Nitorina ni Herodia ṣe ni i sinu, on si nfẹ ipa a; ṣugbọn kò le ṣe e: Nitori Herodu bẹ̀ru Johanu, o si mọ̀ ọ li olõtọ enia ati ẹni mimọ́, o si ntọju rẹ̀; nigbati o gbọrọ rẹ̀, o ṣe ohun pipọ, o si fi ayọ̀ gbọrọ rẹ̀. Nigbati ọjọ ti o wọ̀ si de, ti Herodu sàse ọjọ ibí rẹ̀ fun awọn ijoye rẹ̀, awọn balogun, ati awọn olori ni Galili; Nigbati ọmọbinrin Herodia si wọle, ti o si njó, o mu inu Herodu dùn ati awọn ti o ba a joko, ọba si wi fun ọmọbinrin na pe, Bère ohunkohun ti iwọ fẹ lọwọ mi, emi o si fifun ọ. O si bura fun u, wipe, Ohunkohun ti iwọ ba bere lọwọ mi, emi o si fifun ọ, titi fi de idameji ijọba mi. O si jade lọ, o wi fun iya rẹ̀ pe, Kini ki emi ki o bère? On si wipe, Ori Johanu Baptisti. Lojukanna, o si wọle tọ̀ ọba wá kánkan, o bère, wipe, emi nfẹ ki iwọ ki o fi ori Johanu Baptisti fun mi ninu awopọkọ nisisiyi. Inu ọba si bajẹ gidigidi; ṣugbọn nitori ibura rẹ̀, ati nitori awọn ti o bá a joko pọ̀, kò si fẹ ikọ̀ fun u. Lọgan ọba si rán ẹṣọ́ kan, o fi aṣẹ fun u pe, ki o gbé ori rẹ̀ wá: o si lọ, o bẹ́ Johanu lori ninu tubu. O si gbé ori rẹ̀ wá ninu awopọkọ, o si fi fun ọmọbinrin na: ọmọbinrin na si fi fun iya rẹ̀. Nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si gbọ́, nwọn wá, nwọn gbé okú rẹ̀, nwọn si lọ tẹ́ ẹ sinu ibojì.

Mak 6:17-29 Yoruba Bible (YCE)

Nítorí Hẹrọdu kan náà yìí ni ó ranṣẹ lọ mú Johanu tí ó fi í sẹ́wọ̀n nítorí ọ̀ràn Hẹrọdiasi iyawo Filipi arakunrin Hẹrọdu tí Hẹrọdu gbà. Nítorí Johanu a máa wí fún Hẹrọdu pé, “Kò yẹ fún ọ láti gba iyawo arakunrin rẹ.” Nítorí náà Hẹrọdiasi ní Johanu sinu, ó fẹ́ pa á, ṣugbọn kò lè pa á, nítorí Hẹrọdu bẹ̀rù Johanu, nítorí ó mọ̀ pé olóòótọ́ eniyan ni ati pé kò ní àléébù. Nítorí náà ó dáàbò bò ó. Ọkàn Hẹrọdu a máa dàrú gidigidi nígbàkúùgbà tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ Johanu, sibẹ a máa fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Nígbà tí ó di ọjọ́ kan, Hẹrọdiasi rí àkókò tí ó wọ̀ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Hẹrọdu se àsè ọjọ́ ìbí rẹ̀, ó pe àwọn ìjòyè, àwọn ọ̀gágun, ati àwọn eniyan pataki ilẹ̀ Galili. Ọmọ Hẹrọdiasi obinrin bá wọlé, ó bọ́ sí agbo, ó bẹ̀rẹ̀ sí jó, inú Hẹrọdu ati ti àwọn tí ó wà níbi àsè náà dùn. Ọba sọ fún ọmọbinrin náà pé, “Bèèrè ohun tí o bá fẹ́, n óo fi í fún ọ.” Ó bá búra fún un pé, “N óo fún ọ ní ohunkohun tí o bá bèèrè, kì báà ṣe ìdajì ìjọba mi.” Ọmọbinrin náà bá lọ sí ọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀, ó ní, “Kí ni kí n bèèrè?” Ìyá rẹ̀ dáhùn pé, “Bèèrè orí Johanu Onítẹ̀bọmi.” Ọmọbinrin náà yára lọ sí ọ̀dọ̀ ọba, ó wí pé, “Mo fẹ́ kí o fún mi ní orí Johanu Onítẹ̀bọmi kíákíá, kí wọ́n fi àwo pẹrẹsẹ gbé e wá.” Inú ọba bàjẹ́ pupọ, ṣugbọn nítorí ó ti ṣe ìlérí pẹlu ìbúra lójú àwọn tí ó wà níbi àsè, kò fẹ́ kọ̀ fún un. Lẹsẹkẹsẹ ọba rán ọmọ-ogun kan, ó pàṣẹ fún un kí ó gbé orí Johanu wá. Ó bá lọ, ó bẹ́ ẹ lórí ninu ilé ẹ̀wọ̀n. Ó bá fi àwo pẹrẹsẹ gbé orí rẹ̀ wá, ó fi í fún ọmọbinrin náà. Ọmọbinrin náà bá gbé e lọ fún ìyá rẹ̀. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu gbọ́, wọ́n wá gbé òkú rẹ̀, wọ́n sin ín sinu ibojì.

Mak 6:17-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Herodu fúnrarẹ̀ sá ti ránṣẹ́ mú Johanu, tìkára rẹ̀ sínú túbú nítorí Herodia aya Filipi arákùnrin rẹ̀ nítorí tí ó fi ṣe aya. Johanu sì ti wí fún Herodu pé, “Kò tọ́ sí ọ láti fi ìyàwó arákùnrin rẹ ṣe aya.” Nítorí náà ni Herodia ṣe ní sínú, òun sì fẹ́ pa á, ṣùgbọ́n kò le ṣe é. Nítorí Herodu bẹ̀rù Johanu, ó sì mọ̀ ọ́n ni olóòtítọ́ ènìyàn àti ẹni mímọ́, ó sì ń tọ́jú rẹ̀. Nígbà tí Herodu ba gbọ́rọ̀ Johanu, ó máa ń dààmú síbẹ̀, ó sì fi ayọ̀ gbọ́rọ̀ rẹ̀. Níkẹyìn Herodia rí ààyè. Àkókò yìí ni ọjọ́ ìbí Herodu, òun sì pèsè àsè ní ààfin ọba fún àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀: àwọn balógun àti àwọn ènìyàn pàtàkì ní Galili. Nígbà náà, ni ọmọbìnrin Herodia wọlé láti jó. Inú Herodu àti àwọn àlejò rẹ̀ dùn tó bẹ́ẹ̀. Ọba sọ fún ọmọbìnrin náà pé, “Béèrè ohunkóhun tí ìwọ bá fẹ́ lọ́wọ́ mi, èmi ó sì fi fún ọ.” Ó sì búra fún un wí pé, “Ohunkóhun tí ìwọ bá fẹ́, ìbá à ṣe ìdajì ìjọba mi ni, èmi yóò fi fún ọ.” Ó jáde lọ sọ fún ìyá rẹ̀ pé “Kí ní kí ń béèrè?” Ó dáhùn pé, “Orí Johanu Onítẹ̀bọmi.” Ọmọbìnrin yìí sáré padà wá sọ́dọ̀ Herodu ọba. Ó sì wí fún un pé, “Mo ń fẹ́ orí Johanu Onítẹ̀bọmi nísinsin yìí nínú àwopọ̀kọ́.” Inú ọba sì bàjẹ́ gidigidi, ṣùgbọ́n nítorí àwọn ìbúra rẹ, àti nítorí àwọn tí ó bá a jókòó pọ̀, kò sì fẹ́ kọ̀ fún un. Nítorí èyí, ọba rán ẹ̀ṣọ́ kan, ó fi àṣẹ fún un pé, kí ó gbé orí Johanu wá. Ọkùnrin náà sì lọ, ó bẹ́ Johanu lórí nínú túbú. Ó sì gbé orí Johanu wa nínú àwopọ̀kọ́. Ó sì gbé e fún ọmọbìnrin náà. Òun sì gbé e tọ ìyá rẹ̀ lọ. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu gbọ́, wọ́n wá gbé òkú rẹ̀, wọ́n sì lọ tẹ́ ẹ sínú ibojì.