Mak 5:35-43
Mak 5:35-43 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi o si ti nsọ̀rọ li ẹnu, awọn kan ti ile olori sinagogu wá ti o wipe, Ọmọbinrin rẹ kú: ẽṣe ti iwọ si fi nyọ olukọni lẹnu? Lojukanna bi Jesu ti gbọ́ ọ̀rọ na ti a sọ, o si wi fun olori sinagogu na pe, Má bẹ̀ru, sá gbagbọ́ nikan. Kò si jẹ ki ẹnikẹni tọ̀ on lẹhin, bikoṣe Peteru, ati Jakọbu, ati Johanu arakunrin Jakọbu. O si wá si ile olori sinagogu, o si ri ariwo, ati awọn ti nsọkun ti nwọn si npohunrere ẹkún gidigidi. Nigbati o si wọle, o wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi npariwo, ti ẹ si nsọkun? ọmọ na ko kú, ṣugbọn sisùn li o sùn. Nwọn si fi rẹrin ẹlẹya. Ṣugbọn nigbati o si tì gbogbo wọn jade, o mu baba ati iya ọmọ na, ati awọn ti o wà pẹlu rẹ̀, o si wọ̀ ibiti ọmọ na gbé dubulẹ si. O si mu ọmọ na li ọwọ́, o wi fun u pe, Talita kumi; itumọ eyi ti ijẹ Ọmọbinrin, mo wi fun ọ, Dide. Lọgan ọmọbinrin na si dide, o si nrìn; nitori ọmọ ọdún mejila ni. Ẹ̀ru si ba wọn, ẹnu si yà wọn gidigidi. O si paṣe fun wọn gidigidi pe, ki ẹnikẹni ki o máṣe mọ̀ eyi; o si wipe, ki nwọn ki o fun u li onjẹ.
Mak 5:35-43 Yoruba Bible (YCE)
Kò tíì dákẹ́ ọ̀rọ̀ tí ń sọ, ni àwọn kan bá dé láti ilé olórí ilé ìpàdé tí Jesu ń bá lọ sílé, wọ́n ní, “Ọmọdebinrin rẹ ti kú, kí ni o tún ń yọ olùkọ́ni lẹ́nu sí?” Ṣugbọn Jesu kò pé òun gbọ́ ohun tí wọn ń sọ, ó wí fún ọkunrin náà pé, “Má bẹ̀rù, ṣá ti gbàgbọ́.” Kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tẹ̀lé òun àfi Peteru ati Jakọbu ati Johanu àbúrò Jakọbu. Nígbà tí wọ́n dé ilé olórí ilé ìpàdé náà, Jesu rí bí gbogbo ilé ti dàrú, tí ẹkún ati ariwo ń sọ gèè. Ó bá wọ inú ilé lọ, ó ní, “Kí ló dé tí ẹ fi ń kígbe, tí ẹ̀ ń sunkún bẹ́ẹ̀? Ọmọde náà kò kú; ó sùn ni.” Wọ́n bá ń fi ṣe yẹ̀yẹ́, ó bá lé gbogbo wọn jáde. Ó wá mú baba ati ìyá ọmọ náà pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tí ó wà pẹlu rẹ̀, ó wọ yàrá tí ọmọde náà wà lọ. Ó bá fa ọmọde náà lọ́wọ́, ó wí fún un pé, “Talita kumi” ìtumọ̀ èyí tíí ṣe, “Ìwọ ọmọde yìí, mo wí fún ọ, dìde.” Lẹsẹkẹsẹ ọmọdebinrin náà dìde, ó bá ń rìn, nítorí ọmọ ọdún mejila ni. Ìyàlẹ́nu ńlá ni ó jẹ́ fún gbogbo wọn. Jesu wá kìlọ̀ fún wọn gan-an pé kí wọn má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀. Ó ní kí wọn wá oúnjẹ fún ọmọde náà kí ó jẹ.
Mak 5:35-43 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí Jesu sì ti ń ba obìnrin náà sọ̀rọ̀, àwọn ìránṣẹ́ dé láti ilé Jairu olórí Sinagọgu wá, wọ́n wí fún un pé, ọmọbìnrin rẹ ti kú, àti pé kí wọn má ṣe yọ Jesu lẹ́nu láti wá, nítorí ó ti pẹ́ jù. Ṣùgbọ́n bi Jesu ti gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ó wí fún Jairu pé, “Má bẹ̀rù, sá à gbàgbọ́ nìkan.” Nígbà náà, Jesu dá ọ̀pọ̀ ènìyàn náà dúró. Kò sì jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tẹ̀lé òun lẹ́yìn lọ ilé Jairu, bí kò ṣe Peteru, Jakọbu àti Johanu arákùnrin Jakọbu. Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, Jesu rí i pé gbogbo nǹkan ti dàrú. Ilé kún fún àwọn tí ń sọkún, àti àwọn tí ń pohùnréré ẹkún. Ó wọ inú ilé lọ, o sì bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀, ó béèrè pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń sọkún tí ẹ sì ń pohùnréré ẹkún? Ọmọbìnrin náà kò kú, ó sùn lásán ni.” Wọ́n sì fi í rẹ́rìn-ín. Ṣùgbọ́n ó sọ fún gbogbo wọn láti bọ́ síta, ó mú baba àti ìyá ọmọ náà, àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mẹ́ta. Ó sì wọ inú yàrá tí ọmọbìnrin náà gbé dùbúlẹ̀ sí. Ó gbá a ní ọwọ́ mú, ó sì wí pé, “Talita kuumi” (tí ó túmọ̀ sí, ọmọdébìnrin, dìde dúró). Lẹ́sẹ̀kan náà, ọmọbìnrin náà sì dìde. Ó sì ń rìn, ẹ̀rù sì bà wọ́n, ẹnu sì ya àwọn òbí rẹ̀ gidigidi. Jesu sì kìlọ̀ fún wọn gidigidi pé kí wọn má ṣe sọ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀. Ó sì wí fún wọn kí wọn fún ọmọbìnrin náà ní oúnjẹ.