Mak 5:25-32
Mak 5:25-32 Bibeli Mimọ (YBCV)
Obinrin kan ti o ti ni isun ẹ̀jẹ li ọdún mejila, Ẹniti oju rẹ̀ si ri ohun pipọ lọdọ ọ̀pọ awọn oniṣegun, ti o si ti ná ohun gbogbo ti o ni tan, ti kò si sàn rara, ṣugbọn kàka bẹ̃ o npọ̀ siwaju. Nigbati o gburo Jesu, o wá sẹhin rẹ̀ larin ọ̀pọ enia, o fọwọ́kàn aṣọ rẹ̀. Nitori o wipe, Bi mo ba sá le fi ọwọ́ mi kàn aṣọ rẹ̀, ara mi yio da. Lọgan ni isun ẹ̀jẹ rẹ̀ si ti gbẹ; on si mọ̀ lara rẹ̀ pe, a mu on larada ninu arun na. Lọgan Jesu si ti mọ̀ ninu ara rẹ̀ pe, aṣẹ ti ara on jade, o yipada larin ọpọ enia, o si wipe, Tali o fi ọwọ́ kàn mi li aṣọ? Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wi fun u pe, Iwọ ri bi ijọ enia ti nhá ọ li àye, iwọ si nwipe, Tali o fi ọwọ́ tọ́ mi? O si wò yiká lati ri ẹniti o ṣe nkan yi.
Mak 5:25-32 Yoruba Bible (YCE)
Obinrin kan wà láàrin wọn tí nǹkan oṣù rẹ̀ kọ̀ tí kò dá fún ọdún mejila. Ojú rẹ̀ ti rí oríṣìíríṣìí lọ́dọ̀ àwọn oníṣègùn. Gbogbo ohun ìní rẹ̀ ni ó ti run sórí àìsàn náà. Ṣugbọn kàkà kí ó sàn, ńṣe ni àìsàn náà túbọ̀ ń burú sí i. Nígbà tí obinrin náà gbọ́ nípa Jesu, ó gba ààrin àwọn eniyan dé ẹ̀yìn rẹ̀, ó bá fi ọwọ́ kan aṣọ rẹ̀, nítorí ó sọ ninu ara rẹ̀ pé, “Bí ó bá jẹ́ aṣọ rẹ̀ ni mo lè fi ọwọ́ kàn, ara mi yóo dá.” Lẹsẹkẹsẹ tí ó fọwọ́ kàn án ni ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ bá dá. Ó sì mọ̀ ninu ara rẹ̀ pé a ti mú òun lára dá ninu àìsàn náà. Lójú kan náà Jesu mọ̀ ninu ara rẹ̀ pé agbára ìwòsàn jáde lára òun. Ó bá yipada sí àwọn eniyan, ó bèèrè pé, “Ta ni fọwọ́ kàn mí láṣọ?” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “O rí i bí àwọn eniyan ti ń fún ọ lọ́tùn-ún lósì, o tún ń bèèrè pé ta ni fọwọ́ kàn ọ́?” Ṣugbọn Jesu ń wò yíká láti rí ẹni tí ó fọwọ́ kan aṣọ rẹ̀.
Mak 5:25-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Obìnrin kan sì wà láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn náà, tí ó ti ní ìsun ẹ̀jẹ̀ fún odidi ọdún méjìlá. Ẹni tí ojú rẹ̀ sì ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú lọ́dọ̀ ọ̀pọ̀ àwọn oníṣègùn, tí ó sì ti ná gbogbo ohun tí ó ní, síbẹ̀ kàkà kí ó san, ó ń burú sí i. Nígbà tí ó sì gbúròó iṣẹ́ ìyanu tí Jesu ṣe, ìdí nìyìí tí ó fi wá sẹ́yìn rẹ̀, láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó sì fọwọ́ kan aṣọ rẹ̀. Nítorí ti ó rò ní ọkàn rẹ̀ pé, “Bí mo bá sá à lè fi ọwọ́ kan aṣọ rẹ̀, ara mi yóò dá.” Ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì gbẹ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, òun sì mọ̀ lára rẹ̀ pé, a mú òun láradá kúrò nínú ààrùn náà. Lọ́gán, Jesu sì mọ̀ nínú ara rẹ̀ pé agbára jáde lára òun. Ó yípadà láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó sì béèrè, “Ta ni ó fi ọwọ́ kan aṣọ mi?” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Ìwọ rí ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó rọ̀gbà yí ọ ká, ìwọ sì tún ń béèrè ẹni tí ó fi ọwọ́ kàn ọ́?” Síbẹ̀, Jesu bẹ̀rẹ̀ sí wò yíká láti rí ẹni náà, tí ó fi ọwọ́ kan òun.