Mak 5:24-34
Mak 5:24-34 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ba a lọ; ọ̀pọ enia si ntọ̀ ọ lẹhin, nwọn si nhá a li àye. Obinrin kan ti o ti ni isun ẹ̀jẹ li ọdún mejila, Ẹniti oju rẹ̀ si ri ohun pipọ lọdọ ọ̀pọ awọn oniṣegun, ti o si ti ná ohun gbogbo ti o ni tan, ti kò si sàn rara, ṣugbọn kàka bẹ̃ o npọ̀ siwaju. Nigbati o gburo Jesu, o wá sẹhin rẹ̀ larin ọ̀pọ enia, o fọwọ́kàn aṣọ rẹ̀. Nitori o wipe, Bi mo ba sá le fi ọwọ́ mi kàn aṣọ rẹ̀, ara mi yio da. Lọgan ni isun ẹ̀jẹ rẹ̀ si ti gbẹ; on si mọ̀ lara rẹ̀ pe, a mu on larada ninu arun na. Lọgan Jesu si ti mọ̀ ninu ara rẹ̀ pe, aṣẹ ti ara on jade, o yipada larin ọpọ enia, o si wipe, Tali o fi ọwọ́ kàn mi li aṣọ? Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wi fun u pe, Iwọ ri bi ijọ enia ti nhá ọ li àye, iwọ si nwipe, Tali o fi ọwọ́ tọ́ mi? O si wò yiká lati ri ẹniti o ṣe nkan yi. Ṣugbọn obinrin na ni ibẹ̀ru ati iwarìri, bi o ti mọ̀ ohun ti a ṣe lara on, o wá, o si wolẹ niwaju rẹ̀, o si sọ gbogbo otitọ fun u. O si wi fun u pe, Ọmọbinrin, igbagbọ́ rẹ mu ọ larada; mã lọ li alafia, ki iwọ ki o si sàn ninu arun rẹ.
Mak 5:24-34 Yoruba Bible (YCE)
Jesu bá bá a lọ. Bí ó ti ń lọ, ọpọlọpọ eniyan ń tẹ̀lé e, wọ́n ń fún un lọ́tùn-ún lósì. Obinrin kan wà láàrin wọn tí nǹkan oṣù rẹ̀ kọ̀ tí kò dá fún ọdún mejila. Ojú rẹ̀ ti rí oríṣìíríṣìí lọ́dọ̀ àwọn oníṣègùn. Gbogbo ohun ìní rẹ̀ ni ó ti run sórí àìsàn náà. Ṣugbọn kàkà kí ó sàn, ńṣe ni àìsàn náà túbọ̀ ń burú sí i. Nígbà tí obinrin náà gbọ́ nípa Jesu, ó gba ààrin àwọn eniyan dé ẹ̀yìn rẹ̀, ó bá fi ọwọ́ kan aṣọ rẹ̀, nítorí ó sọ ninu ara rẹ̀ pé, “Bí ó bá jẹ́ aṣọ rẹ̀ ni mo lè fi ọwọ́ kàn, ara mi yóo dá.” Lẹsẹkẹsẹ tí ó fọwọ́ kàn án ni ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ bá dá. Ó sì mọ̀ ninu ara rẹ̀ pé a ti mú òun lára dá ninu àìsàn náà. Lójú kan náà Jesu mọ̀ ninu ara rẹ̀ pé agbára ìwòsàn jáde lára òun. Ó bá yipada sí àwọn eniyan, ó bèèrè pé, “Ta ni fọwọ́ kàn mí láṣọ?” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “O rí i bí àwọn eniyan ti ń fún ọ lọ́tùn-ún lósì, o tún ń bèèrè pé ta ni fọwọ́ kàn ọ́?” Ṣugbọn Jesu ń wò yíká láti rí ẹni tí ó fọwọ́ kan aṣọ rẹ̀. Obinrin náà mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lára òun, ó bá yọ jáde. Ẹ̀rù bà á, ó ń gbọ̀n, ó bá wá kúnlẹ̀ níwájú Jesu, ó sọ gbogbo òtítọ́ ọ̀rọ̀ náà fún un. Jesu wí fún un pé, “Arabinrin, igbagbọ rẹ ti mú ọ lára dá. Máa lọ ní alaafia, o kò ní gbúròó àìsàn náà mọ́.”
Mak 5:24-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Jesu sì ń bá a lọ. Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì ń tọ̀ Ọ́ lẹ́yìn. Obìnrin kan sì wà láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn náà, tí ó ti ní ìsun ẹ̀jẹ̀ fún odidi ọdún méjìlá. Ẹni tí ojú rẹ̀ sì ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú lọ́dọ̀ ọ̀pọ̀ àwọn oníṣègùn, tí ó sì ti ná gbogbo ohun tí ó ní, síbẹ̀ kàkà kí ó san, ó ń burú sí i. Nígbà tí ó sì gbúròó iṣẹ́ ìyanu tí Jesu ṣe, ìdí nìyìí tí ó fi wá sẹ́yìn rẹ̀, láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó sì fọwọ́ kan aṣọ rẹ̀. Nítorí ti ó rò ní ọkàn rẹ̀ pé, “Bí mo bá sá à lè fi ọwọ́ kan aṣọ rẹ̀, ara mi yóò dá.” Ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì gbẹ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, òun sì mọ̀ lára rẹ̀ pé, a mú òun láradá kúrò nínú ààrùn náà. Lọ́gán, Jesu sì mọ̀ nínú ara rẹ̀ pé agbára jáde lára òun. Ó yípadà láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó sì béèrè, “Ta ni ó fi ọwọ́ kan aṣọ mi?” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Ìwọ rí ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó rọ̀gbà yí ọ ká, ìwọ sì tún ń béèrè ẹni tí ó fi ọwọ́ kàn ọ́?” Síbẹ̀, Jesu bẹ̀rẹ̀ sí wò yíká láti rí ẹni náà, tí ó fi ọwọ́ kan òun. Nígbà náà, obìnrin náà kún fún ìbẹ̀rù àti ìwárìrì nítorí ó ti mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lára òun. Ó sì kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì sọ gbogbo òtítọ́ fún un. Jesu sì wí fún un pé, “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá. Máa lọ ní àlàáfíà, ìwọ sì ti sàn nínú ààrùn rẹ.”