Mak 5:18-20
Mak 5:18-20 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi o si ti nwọ̀ inu ọkọ̀, ẹniti o ti li ẹmi èṣu na o mbẹ ẹ, ki on ki o le mã bá a gbé. Ṣugbọn Jesu kò gbà fun u, ṣugbọn o wi fun u pe, Lọ si ile rẹ ki o si sọ fun awọn ará ile rẹ, bi Oluwa ti ṣe ohun nla fun ọ, ati bi o si ti ṣanu fun ọ. O si pada lọ, o bẹ̀rẹ si ima ròhin ni Dekapoli, ohun nla ti Jesu ṣe fun u: ẹnu si yà gbogbo enia.
Mak 5:18-20 Yoruba Bible (YCE)
Bí ó ti ń wọ ọkọ̀ ojú omi pada, ọkunrin tí ó ti jẹ́ wèrè rí yìí bẹ̀ ẹ́ pé kí ó jẹ́ kí òun máa bá a lọ. Ṣugbọn Jesu kọ̀ fún un, ó sọ fún un pé, “Lọ sí ilé rẹ, sọ́dọ̀ àwọn ẹbí rẹ, kí o sọ ohun tí Oluwa ti ṣe fún ọ ati bí ó ti ṣàánú rẹ.” Ọkunrin náà lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí ròyìn ohun tí Jesu ṣe fún un ní agbègbè Ìlú Mẹ́wàá, ẹnu sì ya gbogbo eniyan tí ó gbọ́.
Mak 5:18-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí Jesu ti ń wọ inú ọkọ̀ ojú omi lọ, ọkùnrin náà tí ó ti ní ẹ̀mí àìmọ́ tẹ́lẹ̀ bẹ̀ Ẹ́ pé kí òun lè bá a lọ. Jesu kò gbà fún un, ṣùgbọ́n ó wí fún un pé, “Lọ sí ilé sí ọ̀dọ̀ àwọn ẹbí rẹ, kí o sì sọ fún wọn bí Ọlọ́run ti ṣe ohun ńlá fún ọ, àti bí ó sì ti ṣàánú fún ọ.” Nítorí naà, ọkùnrin yìí padà lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí ròyìn ní Dekapoli nípa ohun ńlá tí Jesu ṣe fún un. Ẹnu sì ya gbogbo ènìyàn.