Mak 5:1-20

Mak 5:1-20 Bibeli Mimọ (YBCV)

NWỌN si wá si apa keji okun ni ilẹ awọn ara Gadara. Nigbati o si ti inu ọkọ̀ jade, lojukanna ọkunrin kan ti o li ẹmi aimọ pade rẹ̀, o nti ibi ibojì jade wá, Ẹniti o ni ibugbe rẹ̀ ninu ibojì; kò si si ẹniti o le dè e, kò si, kì iṣe ẹ̀wọn: Nitoripe nigbapupọ li a ti nfi ṣẹkẹṣẹkẹ ati ẹ̀wọn de e, on a si dá ẹ̀wọn na meji, a si dá ṣẹkẹṣẹkẹ wẹ́wẹ: bẹ̃ni kò si ẹnikan ti o li agbara lati se e rọ̀. Ati nigbagbogbo, li ọsán ati li oru, o wà lori òke, ati ninu ibojì, a ma kigbe, a si ma fi okuta pa ara rẹ̀ lara. Ṣugbọn nigbati o ri Jesu li òkere, o sare wá, o si foribalẹ fun u, O si nkigbe li ohùn rara, wipe, Kini ṣe temi tirẹ, Jesu, iwọ Ọmọ Ọlọrun Ọgá-ogo? mo fi Ọlọrun bẹ̀ ọ, ki iwọ ki o máṣe da mi loró. Nitoriti o wi fun u pe, Jade kuro lara ọkunrin na, iwọ ẹmi aimọ́. O si bi i lẽre pe, Orukọ rẹ? O si dahùn, wipe, Legioni li orukọ mi: nitori awa pọ̀. O si bẹ̀ ẹ gidigidi pe, ki o máṣe rán wọn jade kuro ni ilẹ na. Agbo ọ̀pọ ẹlẹdẹ kan si wà nibẹ ti njẹ lẹba oke. Gbogbo awọn ẹmi èṣu bẹ̀ ẹ wipe, Rán wa lọ sinu awọn ẹlẹdẹ, ki awa ki o le wọ̀ inu wọn lọ. Lọgan Jesu si jọwọ wọn. Awọn ẹmi aimọ́ si jade, nwọn si wọ̀ inu awọn ẹlẹdẹ lọ: agbo ẹlẹdẹ si tupũ nwọn si sure ni gẹrẹgẹrẹ lọ sinu okun (nwọn si to ìwọn ẹgbã;) nwọn si kú sinu okun. Awọn ti mbọ́ wọn si sá, nwọn si lọ ròhin ni ilu nla, atì ni ilẹ na. Nwọn si jade lọ lati wò ohun na ti o ṣe. Nwọn si wá sọdọ Jesu, nwọn si ri ẹniti o ti ni ẹmi èṣu, ti o si ni Legioni na, o joko, o si wọṣọ, iyè rẹ̀ si bọ si ipò: ẹ̀ru si ba wọn. Awọn ti o ri i si ròhin fun wọn bi o ti ri fun ẹniti o li ẹmi èṣu, ati ti awọn ẹlẹdẹ pẹlu. Nwọn si bẹ̀rẹ si ibẹ̀ ẹ, wipe, ki o lọ kuro li àgbegbe wọn. Bi o si ti nwọ̀ inu ọkọ̀, ẹniti o ti li ẹmi èṣu na o mbẹ ẹ, ki on ki o le mã bá a gbé. Ṣugbọn Jesu kò gbà fun u, ṣugbọn o wi fun u pe, Lọ si ile rẹ ki o si sọ fun awọn ará ile rẹ, bi Oluwa ti ṣe ohun nla fun ọ, ati bi o si ti ṣanu fun ọ. O si pada lọ, o bẹ̀rẹ si ima ròhin ni Dekapoli, ohun nla ti Jesu ṣe fun u: ẹnu si yà gbogbo enia.

Mak 5:1-20 Yoruba Bible (YCE)

Jesu lọ sí òdìkejì òkun ní ilẹ̀ àwọn ará Geraseni. Bí ó ti jáde kúrò ninu ọkọ̀, ọkunrin wèrè kan wá pàdé rẹ̀ láti inú ibojì pàlàpálá àpáta. Ibojì náà ni ò fi ṣe ilé. Kò sí ẹni tí ó lè de wèrè náà mọ́lẹ̀; ẹ̀wọ̀n kò tilẹ̀ ṣe é fi dè é. Nítorí ní ọpọlọpọ ìgbà ni wọ́n kó ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ sí i lẹ́sẹ̀, tí wọ́n tún fi ẹ̀wọ̀n dè é lọ́wọ́. Ṣugbọn jíjá ni ó máa ń já ẹ̀wọ̀n, tí ó sì máa ń rún ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ tí wọ́n fi dè é. Kò sí ẹni tí ó lè fi agbára mú un kí ó fi ara balẹ̀. Tọ̀sán-tòru níí máa kígbe láàrin àwọn ibojì ati lórí òkè, a sì máa fi òkúta ya ara rẹ̀. Ṣugbọn nígbà tí ó rí Jesu lókèèrè, ó sáré, ó dọ̀bálẹ̀ níwájú rẹ̀. Ó ké rara pé, “Kí ni ó pa tàwa-tìrẹ pọ̀, Jesu ọmọ Ọlọrun tí ó lógo jùlọ? Mo fi Ọlọrun bẹ̀ ọ́, má ṣe dá mi lóró.” (Nítorí Jesu tí ń sọ pé kí ẹ̀mí èṣù náà jáde kúrò ninu ọkunrin náà.) Jesu wá bi í pé, “Kí ni orúkọ rẹ?” Ó ní, “Ẹgbaagbeje ni mò ń jẹ́, nítorí a kò níye.” Ó bá bẹ̀rẹ̀ sí bẹ Jesu títí pé kí ó má ṣe lé wọn jáde kúrò ní agbègbè ibẹ̀. Agbo ọ̀pọ̀ ẹlẹ́dẹ̀ kan wà níbẹ̀, wọ́n ń jẹ lẹ́bàá òkè. Àwọn ẹ̀mí èṣù náà bẹ̀ ẹ́ pé kí ó rán wọn sí ààrin ẹlẹ́dẹ̀ náà, kí wọ́n lè wọ inú wọn. Ó bá gbà bẹ́ẹ̀ fún wọn. Àwọn ẹ̀mí èṣù náà jáde lọ, wọ́n wọ inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà. Agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà bá tú pẹ̀ẹ́, wọ́n sáré láti gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè lọ sí òkun, wọ́n bá rì sinu òkun. Wọ́n tó bí ẹgbaa (2,000). Àwọn olùtọ́jú wọn bá sálọ sí àwọn ìlú ati àwọn abúlé tí ó wà yíká láti ròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Àwọn eniyan bá wá fi ojú ara wọn rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n rí ọkunrin náà tí ó ti jẹ́ wèrè rí, tí ó ti ní ẹgbaagbeje ẹ̀mí èṣù, ó jókòó, ó wọ aṣọ, iyè rẹ̀ sì ti bọ̀ sípò. Ẹ̀rù ba àwọn eniyan tí ó rí i. Àwọn tí ọ̀rọ̀ náà ṣe ojú wọn ròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọkunrin náà ati àwọn ẹlẹ́dẹ̀. Àwọn eniyan bá bẹ̀rẹ̀ sí bẹ Jesu pé kí ó kúrò ní agbègbè wọn. Bí ó ti ń wọ ọkọ̀ ojú omi pada, ọkunrin tí ó ti jẹ́ wèrè rí yìí bẹ̀ ẹ́ pé kí ó jẹ́ kí òun máa bá a lọ. Ṣugbọn Jesu kọ̀ fún un, ó sọ fún un pé, “Lọ sí ilé rẹ, sọ́dọ̀ àwọn ẹbí rẹ, kí o sọ ohun tí Oluwa ti ṣe fún ọ ati bí ó ti ṣàánú rẹ.” Ọkunrin náà lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí ròyìn ohun tí Jesu ṣe fún un ní agbègbè Ìlú Mẹ́wàá, ẹnu sì ya gbogbo eniyan tí ó gbọ́.

Mak 5:1-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Wọ́n lọ sí apá kejì adágún ní ẹ̀bá ilẹ̀ àwọn ará Gadara. Bí Jesu sì ti ń ti inú ọkọ̀ ojú omi jáde. Ọkùnrin kan tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́ jáde ti ibojì wá pàdé rẹ̀. Ọkùnrin yìí ń gbé nínú ibojì, kò sí ẹni tí ó lè dè é mọ́, kódà ẹ̀wọ̀n kò le dè é. Nítorí pé nígbà púpọ̀ ni wọ́n ti ń fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ dè é lọ́wọ́ àti ẹsẹ̀, tí ó sì ń já a dànù kúrò ni ẹsẹ̀ rẹ̀. Kò sí ẹnìkan tí ó ní agbára láti káwọ́ rẹ̀. Tọ̀sán tòru láàrín àwọn ibojì àti ní àwọn òkè ni ó máa ń kígbe rara tí ó sì ń fi òkúta ya ara rẹ̀. Nígbà tí ó sì rí Jesu látòkèrè, ó sì sáré lọ láti pàdé rẹ̀. Ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀. Ó sì kígbe ní ohùn rara wí pé, “Kí ní ṣe tèmi tìrẹ, Jesu Ọmọ Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo? Mo fi Ọlọ́run bẹ̀ ọ́ má ṣe dá mi lóró.” Nítorí tí Ó wí fún un pé, “Jáde kúrò lára ọkùnrin náà, ìwọ ẹ̀mí àìmọ́!” Jesu sì bi í léèrè pé, “Kí ni orúkọ rẹ?” Ẹ̀mí àìmọ́ náà sì dáhùn wí pé, “Ligioni, nítorí àwa pọ̀.” Nígbà náà ni ẹ̀mí àìmọ́ náà bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ Jesu gidigidi, kí ó má ṣe rán àwọn jáde kúrò ní agbègbè náà. Agbo ẹlẹ́dẹ̀ ńlá kan sì ń jẹ lẹ́bàá òkè. Àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà bẹ Jesu pé, “Rán wa lọ sínú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ wọ̀n-ọn-nì kí àwa le è wọ inú wọn lọ.” Jesu fún wọn láààyè, àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà sì jáde kúrò lára ọkùnrin náà, wọ́n sì wọ inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà lọ. Agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà tí ó tó ìwọ̀n ẹgbàá sì túká lọ́gán, wọ́n sì sáré lọ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè rọ́ sínú Òkun, wọ́n sì ṣègbé. Àwọn olùtọ́jú ẹran wọ̀nyí sì sálọ sí àwọn ìlú ńlá àti ìlú kéékèèkéé, wọ́n sì ń tan ìròyìn náà ká bí wọ́n ti ń sáré. Àwọn ènìyàn sì tú jáde láti fojú gán-án-ní ohun náà tí ó ṣẹlẹ̀. Nígbà tí wọ́n péjọ sọ́dọ̀ Jesu, wọ́n rí ọkùnrin náà, ẹni tí ó ní ẹ̀mí èṣù, tí ó jókòó níbẹ̀, ó wọ aṣọ ìyè rẹ sì bọ̀ sípò, ẹ̀rù sì bà wọ́n. Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣojú wọn sì ń ròyìn rẹ̀ fún àwọn ènìyàn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin ẹlẹ́mìí àìmọ́, wọ́n si sọ nípa agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà pẹ̀lú. Nígbà náà, àwọn èrò bẹ̀rẹ̀ sí ní bẹ Jesu pé kí ó fi agbègbè àwọn sílẹ̀. Bí Jesu ti ń wọ inú ọkọ̀ ojú omi lọ, ọkùnrin náà tí ó ti ní ẹ̀mí àìmọ́ tẹ́lẹ̀ bẹ̀ Ẹ́ pé kí òun lè bá a lọ. Jesu kò gbà fún un, ṣùgbọ́n ó wí fún un pé, “Lọ sí ilé sí ọ̀dọ̀ àwọn ẹbí rẹ, kí o sì sọ fún wọn bí Ọlọ́run ti ṣe ohun ńlá fún ọ, àti bí ó sì ti ṣàánú fún ọ.” Nítorí naà, ọkùnrin yìí padà lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí ròyìn ní Dekapoli nípa ohun ńlá tí Jesu ṣe fún un. Ẹnu sì ya gbogbo ènìyàn.