Mak 4:37-40
Mak 4:37-40 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ìji nla si dide, ìgbi si mbù sinu ọkọ̀, tobẹ̃ ti ọkọ̀ fi bẹ̀rẹ si ikún. On pãpã si wà ni idi ọkọ̀, o nsùn lori irọri: nwọn si jí i, nwọn si wi fun u pe, Olukọni, iwọ ko bikita bi awa ṣegbé? O si ji, o ba afẹfẹ na wi, o si wi fun okun pe, Dakẹ jẹ. Afẹfẹ si da, iparọrọ nla si de. O si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nṣe ojo bẹ̃? ẹ kò ti iní igbagbọ sibẹ?
Mak 4:37-40 Yoruba Bible (YCE)
Ìjì líle kan bá dé, omi òkun bẹ̀rẹ̀ sí bì lu ọkọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí omi fi kún inú rẹ̀. Jesu wà ní ẹ̀yìn ọkọ̀, ó fi ìrọ̀rí kan rọrí, ó bá sùn lọ. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lọ jí i, wọ́n ní, “Olùkọ́ni, o kò tilẹ̀ bìkítà bí a bá ṣègbé sinu omi!” Ó bá dìde lójú oorun, ó bá afẹ́fẹ́ wí, ó wí fún òkun pé, “Pa rọ́rọ́.” Afẹ́fẹ́ bá rọlẹ̀. Ìdákẹ́rọ́rọ́ bá dé. Ó bá bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin ṣe lójo bẹ́ẹ̀? Ẹ kò ì tíì ní igbagbọ sibẹ?”
Mak 4:37-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìjì líle ńlá kan sì dìde, omi sì ń bù sínú ọkọ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ọkọ̀ fi bẹ̀rẹ̀ sí í kún fún omi, ó sì fẹ́rẹ rì. Jesu ti sùn lọ lẹ́yìn ọkọ̀, ó gbé orí lé ìrọ̀rí. Wọ́n sì jí i lóhùn rara wí pé, “Olùkọ́ni, tàbí ìwọ kò tilẹ̀ bìkítà pé gbogbo wa fẹ́ rì?” Ó dìde, ó bá ìjì líle náà wí, ó sì wí fún òkun pé, “Dákẹ́! Jẹ́ẹ́!” Ìjì náà sì dá, ìparọ́rọ́ ńlá sì wà. Lẹ́yìn náà, ó béèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń ṣojo bẹ́ẹ̀? Tàbí ẹ̀yin kò ì tí ì ní ìgbàgbọ́ síbẹ̀síbẹ̀?”