Mak 4:35-41
Mak 4:35-41 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ni ijọ kanna, nigbati alẹ lẹ tan, o wi fun wọn pe, Ẹ jẹ ki a rekọja lọ si apá keji. Nigbati nwọn si ti tu ijọ ká, nwọn si gbà a gẹgẹ bi o ti wà sinu ọkọ̀. Awọn ọkọ̀ kekere miran pẹlu si wà lọdọ rẹ̀. Ìji nla si dide, ìgbi si mbù sinu ọkọ̀, tobẹ̃ ti ọkọ̀ fi bẹ̀rẹ si ikún. On pãpã si wà ni idi ọkọ̀, o nsùn lori irọri: nwọn si jí i, nwọn si wi fun u pe, Olukọni, iwọ ko bikita bi awa ṣegbé? O si ji, o ba afẹfẹ na wi, o si wi fun okun pe, Dakẹ jẹ. Afẹfẹ si da, iparọrọ nla si de. O si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nṣe ojo bẹ̃? ẹ kò ti iní igbagbọ sibẹ? Ẹru si ba wọn gidigidi, nwọn si nwi fun ara wọn pe, Irú enia kili eyi, ti ati afẹfẹ ati okun gbọ́ tirẹ̀?
Mak 4:35-41 Yoruba Bible (YCE)
Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ sí èbúté ní òdìkejì òkun.” Wọ́n bá fi àwọn eniyan sílẹ̀, wọ́n mú un lọ pẹlu wọn ninu ọkọ̀ tí ó wà. Àwọn ọkọ̀ mìíràn wà níbẹ̀ pẹlu. Ìjì líle kan bá dé, omi òkun bẹ̀rẹ̀ sí bì lu ọkọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí omi fi kún inú rẹ̀. Jesu wà ní ẹ̀yìn ọkọ̀, ó fi ìrọ̀rí kan rọrí, ó bá sùn lọ. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lọ jí i, wọ́n ní, “Olùkọ́ni, o kò tilẹ̀ bìkítà bí a bá ṣègbé sinu omi!” Ó bá dìde lójú oorun, ó bá afẹ́fẹ́ wí, ó wí fún òkun pé, “Pa rọ́rọ́.” Afẹ́fẹ́ bá rọlẹ̀. Ìdákẹ́rọ́rọ́ bá dé. Ó bá bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin ṣe lójo bẹ́ẹ̀? Ẹ kò ì tíì ní igbagbọ sibẹ?” Ẹ̀rù ńlá bà wọ́n. Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí bi ara wọn pé, “Ta ni èyí, tí afẹ́fẹ́ ati òkun ń gbọ́ràn sí lẹ́nu!”
Mak 4:35-41 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí alẹ́ lẹ́, Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí a rékọjá sí apá kejì.” Nígbà tí wọn ti tú ìjọ ká, wọ́n sì gbà á sínú ọkọ̀ ojú omi gẹ́gẹ́ bí ó ti wà. Àwọn ọkọ̀ ojú omi kékeré mìíràn sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Ìjì líle ńlá kan sì dìde, omi sì ń bù sínú ọkọ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ọkọ̀ fi bẹ̀rẹ̀ sí í kún fún omi, ó sì fẹ́rẹ rì. Jesu ti sùn lọ lẹ́yìn ọkọ̀, ó gbé orí lé ìrọ̀rí. Wọ́n sì jí i lóhùn rara wí pé, “Olùkọ́ni, tàbí ìwọ kò tilẹ̀ bìkítà pé gbogbo wa fẹ́ rì?” Ó dìde, ó bá ìjì líle náà wí, ó sì wí fún òkun pé, “Dákẹ́! Jẹ́ẹ́!” Ìjì náà sì dá, ìparọ́rọ́ ńlá sì wà. Lẹ́yìn náà, ó béèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń ṣojo bẹ́ẹ̀? Tàbí ẹ̀yin kò ì tí ì ní ìgbàgbọ́ síbẹ̀síbẹ̀?” Ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi, wọ́n sì wí fún ara wọn pé, “Irú ọkùnrin wo ni èyí, tí ìjì àti Òkun ń gbọ́ tirẹ̀!”