Mak 4:31-32
Mak 4:31-32 Bibeli Mimọ (YBCV)
O dabi wóro irugbin mustardi, eyiti, nigbati a gbin i si ilẹ, bi o tilẹ ṣe pe o kére jù gbogbo irugbin ti o wa ni ilẹ lọ, Sibẹ nigbati a gbin i o dàgba soke, o si di titobi jù gbogbo ewebẹ lọ, o si pa ẹká nla; tobẹ ti awọn ẹiyẹ oju ọrun le ma gbe abẹ ojiji rẹ̀.
Mak 4:31-32 Yoruba Bible (YCE)
Ó ní, “Ó dàbí wóró musitadi kan tí a gbìn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni ó kéré jùlọ ninu gbogbo irúgbìn, ṣugbọn nígbà tí a gbìn ín, ó dàgbà, ó wá tóbi ju gbogbo ewébẹ̀ lọ, ó ní ẹ̀ka ńláńlá, àwọn ẹyẹ wá ń tẹ́ ìtẹ́ wọn sábẹ́ òjìji rẹ̀.”
Mak 4:31-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó dàbí èso hóró musitadi kan, lóòótọ́, ó jọ ọ̀kan nínú àwọn èso tí ó kéré jùlọ ti a gbìn sínú ilẹ̀. Síbẹ̀, nígbà tí a gbìn ín, ó dàgbàsókè, ó gbilẹ̀, ó sì di títóbi ju gbogbo ewéko inú ọgbà yòókù lọ. Ó sì yọ ẹ̀ka ńlá níbi tí àwọn ẹyẹ ọ̀run lè kọ́ ìtẹ́ wọn sí, kí wọn sì rí ìdáàbòbò.”