Mak 4:3-11
Mak 4:3-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ẹ fi etí sílẹ̀! Ní ọjọ́ kan, afúnrúgbìn kan jáde lọ láti lọ fúnrúgbìn rẹ̀. Bí ó ti ń fúnrúgbìn, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ sì wá, wọ́n sì ṣà á jẹ. Díẹ̀ bọ́ sórí ilẹ̀ àpáta, níbi tí erùpẹ̀ ko sí púpọ̀. Láìpẹ́ ọjọ́, ó hu jáde. Ṣùgbọ́n nígbà tí oòrùn mú gangan, ó jóná, nítorí tí kò ní gbòǹgbò, ó gbẹ. Àwọn irúgbìn mìíràn sì bọ́ sáàrín ẹ̀gún, nígbà tí ẹ̀gún sì dàgbàsókè, ó fún wọn pa, tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn irúgbìn náà kò le so èso. Ṣùgbọ́n òmíràn bọ́ sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, o sì so èso lọ́pọ̀lọpọ̀-òmíràn ọgbọọgbọ̀n, òmíràn ọgọọgọ́ta, àti òmíràn ọgọọgọ́rùn-ún.” Jesu sì wí pé, “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́, kí ó gbọ́.” Nígbà tí ó ku òun nìkan pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjìlá àti àwọn mìíràn, wọ́n bi í léèrè wí pé, “Kí ni ìtumọ̀ òwe rẹ̀?” Ó sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin ni a gbà láààyè láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ nípa ìjọba Ọlọ́run. Èyí tí ó pamọ́ sí àwọn tí ó wà lẹ́yìn agbo ìjọba náà.
Mak 4:3-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ fi eti silẹ; Wo o, afunrugbin kan jade lọ ifunrugbin; O si ṣe, bi o ti nfunrugbin, diẹ bọ́ si ẹba ọ̀na, awọn ẹiyẹ si wá, nwọn si ṣà a jẹ. Diẹ si bọ́ sori ilẹ apata, nibiti kò li erupẹ̀ pipọ; lojukanna o si ti hù jade, nitoriti kò ni ijinlẹ: Ṣugbọn nigbati õrùn goke, o jóna; nitoriti kò ni gbongbo, o gbẹ. Diẹ si bọ́ sarin ẹgún, nigbati ẹgún si dàgba soke, o fun u pa, kò si so eso. Omiran si bọ́ si ilẹ rere, o si so eso, ti o ndagba ti o si npọ̀; o si mu eso jade wá, omiran ọgbọgbọn, omiran ọgọtọta, omiran ọgọrọ̀run. O si wi fun wọn pe, Ẹniti o ba li etí lati fi gbọ, ki o gbọ́. Nigbati o kù on nikan, awọn ti o wà lọdọ rẹ̀ pẹlu awọn mejila bi i lẽre idi owe na. O si wi fun wọn pe, Ẹnyin li a fifun lati mọ̀ ohun ijinlẹ ijọba Ọlọrun: ṣugbọn fun awọn ti o wà lode, gbogbo ohun wọnyi li a nfi owe sọ fun wọn
Mak 4:3-11 Yoruba Bible (YCE)
“Ẹ fi etí sílẹ̀! Ọkunrin kan jáde lọ láti fúnrúgbìn. Bí ó ti ń fúnrúgbìn lọ, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ bá wá, wọ́n ṣà á jẹ. Irúgbìn mìíràn bọ́ sí orí òkúta tí erùpẹ̀ díẹ̀ bò lórí. Láìpẹ́, wọ́n yọ sókè nítorí erùpẹ̀ ibẹ̀ kò jinlẹ̀. Nígbà tí oòrùn mú, ó jó wọn pa, nítorí wọn kò ní gbòǹgbò tí ó jinlẹ̀; wọ́n bá kú. Irúgbìn mìíràn bọ́ sí orí ilẹ̀ ẹlẹ́gùn-ún. Nígbà tí ẹ̀gún dàgbà, ó fún wọn pa, nítorí náà wọn kò so èso. Irúgbìn mìíràn bọ́ sí ilẹ̀ tí ó dára, wọ́n yọ sókè, wọ́n ń dàgbà, wọ́n sì ń so èso, òmíràn ọgbọ̀n, òmíràn ọgọta, òmíràn ọgọrun-un.” Lẹ́yìn náà Jesu ní, “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́!” Nígbà tí ó ku òun nìkan, àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀ ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila bèèrè ìtumọ̀ àwọn òwe tí ó fi ń sọ̀rọ̀. Ó bá sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni a fi fún láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ ìjọba Ọlọrun, ṣugbọn bí òwe bí òwe ni fún àwọn ẹlòmíràn tí ó wà lóde.