Mak 3:22-35

Mak 3:22-35 Bibeli Mimọ (YBCV)

Awọn akọwe ti o ti Jerusalemu sọkalẹ wá, wipe, O ni Beelsebubu, olori awọn ẹmi èṣu li o si fi nlé awọn ẹmi èṣu jade. O si pè wọn sọdọ rẹ̀, o si fi owe ba wọn sọrọ pe, Satani yio ti ṣe le lé Satani jade? Bi ijọba kan ba si yàpa si ara rẹ̀, ijọba na kì yio le duro. Bi ile kan ba si yàpa si ara rẹ̀, ile na kì yio le duro. Bi Satani ba si dide si ara rẹ̀, ti o si yàpa, on kì yio le duro, ṣugbọn yio ni opin. Kò si ẹniti o le wọ̀ ile ọkunrin alagbara kan lọ, ki o si kó o li ẹrù lọ, bikoṣepe o tètekọ dè ọkunrin alagbara na li okùn; nigbana ni yio le kó o li ẹrù ni ile. Lõtọ ni mo wi fun nyin, Gbogbo ẹ̀ṣẹ li a o dari wọn jì awọn ọmọ enia, ati gbogbo ọrọ-odi nipa eyiti nwọn o ma fi sọrọ-odi: Ṣugbọn ẹniti o ba sọrọ-odi si Ẹmi Mimọ́ kì yio ni idariji titi lai, ṣugbọn o wà ninu ewu ẹbi ainipẹkun: Nitoriti nwọn wipe, O li ẹmi aimọ́. Nigbana li awọn arakunrin rẹ̀ ati iya rẹ̀ wá, nwọn duro lode, nwọn si ranṣẹ si i, nwọn npè e. Awọn ọ̀pọ enia si joko lọdọ rẹ̀, nwọn si wi fun u pe, Wò o, iya rẹ ati awọn arakunrin rẹ nwá ọ lode. O si da wọn lohùn, wipe, Tani iṣe iya mi, tabi awọn arakunrin mi? O si wò gbogbo awọn ti o joko lọdọ rẹ̀ yiká, o si wipe, Wò iya mi ati awọn arakunrin mi: Nitori ẹnikẹni ti o ba ṣe ifẹ Ọlọrun, on na li arakunrin mi, ati arabinrin mi, ati iya mi.

Mak 3:22-35 Yoruba Bible (YCE)

Ṣugbọn àwọn amòfin tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá láti Jerusalẹmu sọ pé, “Ó ní ẹ̀mí Beelisebulu; ati pé nípa agbára olórí àwọn ẹ̀mí èṣù ni ó fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.” Jesu wá pè wọ́n sọ́dọ̀, ó fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ pé, “Báwo ni Satani ti ṣe lè lé Satani jáde? Bí ìjọba kan náà bá gbé ogun ti ara rẹ̀, ìjọba náà yóo parun. Bí àwọn ará ilé kan náà bá ń bá ara wọn jà, ilé náà kò lè fi ìdí múlẹ̀. Bí Satani bá gbógun ti ara rẹ̀, tí ó ń bá ara rẹ̀ jà, kò lè fi ẹsẹ̀ múlẹ̀, a jẹ́ pé ó parí fún un. “Ṣugbọn kò sí ẹnìkan tí ó lè wọ ilé alágbára kan lọ, kí ó kó dúkìá rẹ̀ láìjẹ́ pé ó kọ́ de alágbára náà mọ́lẹ̀, nígbà náà ni yóo tó lè kó ilé rẹ̀. “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ni a óo dárí ji àwọn ọmọ eniyan, ati gbogbo ìsọkúsọ tí wọ́n lè máa sọ. Ṣugbọn ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ẹ̀mí Mímọ́ kò lè ní ìdáríjì laelae, ṣugbọn ó jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ títí lae.” (Jesu sọ èyí nítorí wọ́n ń wí pé ó ní ẹ̀mí Èṣù.) Nígbà tí ó yá ìyá rẹ̀ ati àwọn arakunrin rẹ̀ wá, wọ́n dúró lóde, wọ́n bá ranṣẹ pè é. Àwọn eniyan jókòó yí i ká, wọ́n bá sọ fún un pé, “Gbọ́ ná, ìyá rẹ ati àwọn arakunrin rẹ ń bèèrè rẹ lóde.” Ó dá wọn lóhùn pé, “Ta ni ìyá mi ati arakunrin mi?” Nígbà tí ó wo gbogbo àwọn tí ó jókòó yí i ká lọ́tùn-ún lósì, ó ní, “Ẹ̀yin ni ìyá mi ati arakunrin mi. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe ohun tí ó wu Ọlọrun, òun ni arakunrin mi, ati arabinrin mi, ati ìyá mi.”

Mak 3:22-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Àwọn olùkọ́ni ní òfin sọ̀kalẹ̀ wá láti Jerusalẹmu, wọ́n sì wí pé, “Ó ni Beelsebulu, olórí àwọn ẹ̀mí èṣù, ni ó sì fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde!” Jesu pè wọ́n, ó sì fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀: “Báwo ni Èṣù ṣe lè lé èṣù jáde? Bí ìjọba kan bá yapa sí ara rẹ̀, ìjọba náà yóò wó lulẹ̀. Bákan náà, bí ilé kan bá sì yapa sí ara rẹ, ilé náà kí yóò le è dúró. Bí Èṣù bá sì dìde sí ara rẹ̀, tí ó sì yapa, òun kí yóò le è dúró ṣùgbọ́n òpin rẹ̀ yóò dé. Kò sí ẹni tí ó le wọ ilé ọkùnrin alágbára kan lọ, kí ó sì kó o ní ẹrù lọ, bí kò ṣe pé ó kọ́kọ́ de ọkùnrin alágbára náà ní okùn, nígbà náà ni yóò lè kó ẹrù ní ilé rẹ̀. Lóòótọ́ ní mo wí fún yín, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ni a ó dáríjì àwọn ọmọ ènìyàn, àti gbogbo ọ̀rọ̀-òdì. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀-òdì sí Ẹ̀mí Mímọ́, kì yóò rí ìdáríjì títí ayé, ṣùgbọ́n ó wà nínú ewu ẹ̀bi àìnípẹ̀kun.” Òun sọ eléyìí fún wọn, nítorí tí wọ́n sọ pé, “Nípa agbára ẹ̀mí àìmọ́ ló ń ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀.” Nígbà náà ni àwọn arákùnrin rẹ̀ àti ìyá wá, wọ́n dúró lóde, wọ́n sì ránṣẹ́ sí i, wọ́n ń pè é. Àwọn ènìyàn tí wọ́n jókòó lọ́dọ̀ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Ìyá àti àwọn arákùnrin rẹ wà lóde.” Ṣùgbọ́n ó dá wọn lóhùn wí pé, “Ta ni í ṣe ìyá mi tàbí àwọn arákùnrin mi?” Ó sì wò gbogbo àwọn tí ó jókòó lọ́dọ̀ rẹ̀ yíká, ó sì wí pé, “Àwọn wọ̀nyí ni ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi: Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, òun ni arákùnrin mi àti arábìnrin mi àti ìyá mi.”