Mak 2:3-5
Mak 2:3-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nwọn si wá sọdọ rẹ̀, nwọn gbé ẹnikan ti o li ẹ̀gba tọ̀ ọ wá, ẹniti mẹrin gbé. Nigbati nwọn kò si le sunmọ ọ nitori ọ̀pọ enia, nwọn si ṣí orule ile nibiti o gbé wà: nigbati nwọn si da a lu tan, nwọn sọ akete na kalẹ lori eyiti ẹlẹgba na dubulẹ. Nigbati Jesu ri igbagbọ́ wọn, o wi fun ẹlẹgba na pe, Ọmọ, a dari ẹ̀ṣẹ rẹ jì ọ.
Mak 2:3-5 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn mẹrin kan ń gbé arọ kan bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Nígbà tí wọn kò lè gbé e dé ọ̀dọ̀ rẹ̀ nítorí ọ̀pọ̀ eniyan, wọ́n dá òrùlé lu ní ọ̀kánkán ibi tí Jesu wà. Nígbà tí wọ́n ti dá a lu tán, wọ́n sọ ọkunrin arọ náà kalẹ̀ ti òun ti ibùsùn rẹ̀. Nígbà tí Jesu rí igbagbọ wọn, ó wí fún arọ náà pé, “Ọmọ, a dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”
Mak 2:3-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn ọkùnrin kan wá, wọ́n gbé arọ tọ̀ ọ́ wá, ẹni tí ọkùnrin mẹ́rin gbé. Nígbà tí wọn kò sì le dé ọ̀dọ̀ Jesu, nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn, wọ́n dá òrùlé ilé lu ní ọ̀gangan ibi tí Jesu wà. Wọ́n sì sọ ọkùnrin arọ náà kalẹ̀ ti òun ti àkéte rẹ̀ níwájú Jesu. Nígbà tí Jesu sì rí ìgbàgbọ́ wọn, ó sọ fún arọ náà pé, “Ọmọ, a dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”