Mak 2:15-17
Mak 2:15-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe, bi o si ti joko tì onjẹ ni ile rẹ̀, ọ̀pọ awọn agbowode ati ẹlẹṣẹ wá bá Jesu joko pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀: nitoriti nwọn pọ̀ nwọn si tọ̀ ọ lẹhin. Nigbati awọn akọwe ati awọn Farisi si ri i ti o mbá awọn agbowode ati awọn ẹlẹṣẹ jẹun, nwọn wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẽtiri ti o fi mba awọn agbowode ati awọn ẹlẹṣẹ jẹ, ti o si mba wọn mu? Nigbati Jesu gbọ́, o wi fun wọn pe, Awọn ti ara wọn le kì iwá oniṣegun, bikoṣe awọn ti ara wọn ko da: Emi ko wá lati pè awọn olododo, bikoṣe awọn ẹlẹṣẹ si ironupiwada.
Mak 2:15-17 Yoruba Bible (YCE)
Bí Jesu ti jókòó ní ilé Lefi, ọpọlọpọ àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ń bá Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ jẹun, nítorí wọ́n pọ̀ tí wọn ń tẹ̀lé e. Nígbà tí àwọn amòfin ninu àwọn Farisi rí i tí ó ń bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ati àwọn agbowó-odè jẹun, wọ́n bi àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ léèrè pé, “Kí ló dé tí ó fi ń bá àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun?” Nígbà tí Jesu gbọ́, ó wí fún wọn pé, “Àwọn tí ara wọn le kò nílò oníṣègùn bíkòṣe àwọn tí ara wọn kò dá: èmi kò wá láti pe àwọn olódodo bíkòṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.”
Mak 2:15-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì ṣe, bí ó sì ti jókòó ti oúnjẹ ni ilé Lefi, ọ̀pọ̀ àwọn agbowó òde àti ẹlẹ́ṣẹ̀ wá bá Jesu jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, nítorí tiwọn pọ̀ tiwọn tẹ̀lé e. Nígbà tí àwọn olùkọ́ òfin àti àwọn Farisi rí ì tí ó ń bá àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun, wọn wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Èétirí tí ó fi ń bá àwọn agbowó òde àti ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun?” Nígbà tí Jesu gbọ́, ó sọ fún wọn wí pé, “Àwọn tí ara wọ́n dá kò wa oníṣègùn, bí ko ṣe àwọn tí ara wọn kò dá. Èmi kò wá láti sọ fún àwọn ènìyàn rere láti ronúpìwàdà, bí kò ṣe àwọn ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀.”