Mak 14:43-52

Mak 14:43-52 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Bí ó sì ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, lójú ẹsẹ̀ náà ni Judasi ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjìlá dé pẹ̀lú. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ti idà àti kùmọ̀ lọ́wọ́, àwọn olórí àlùfáà, àwọn olùkọ́ òfin àti àwọn àgbàgbà Júù ni ó rán wọn wá. Judasi tí fi ààmì fún wọn wí pe, “Ẹni tí mo bá fi ẹnu kò lẹ́nu nínú wọn, òun ní Jesu, Ẹ mú un.” Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jesu, Judasi lọ sì ọ̀dọ̀ rẹ̀ tààrà, ó wí pé, “Rabbi!” ó sì fi ẹnu kò Jesu lẹ́nu. Wọ́n sì mú Jesu. Ṣùgbọ́n ọ̀kan nínú àwọn tí ó dúró fa idà rẹ̀ yọ, ó fi ṣá ọmọ ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, ó sì gé etí rẹ̀ bọ́ sílẹ̀. Nígbà náà Jesu dáhùn, ó bi wọ́n léèrè pé, “Ṣé Èmi ni ẹ̀yin jáde tọ̀ wá bi olè, ti ẹ̀yin ti idà àti kùmọ̀ láti mú? Ojoojúmọ́ ni èmi wà pẹ̀lú yín ní tẹmpili, tí mo ń kọ́ni; ẹ kò mú mi. Ṣùgbọ́n eléyìí ṣẹlẹ̀, kí ohun tí ìwé Mímọ́ wí lè ṣẹ.” Ní àkókò yìí, gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti fi í sílẹ̀, wọ́n sálọ. Ọ̀dọ́mọkùnrin kan sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn tí ó fi aṣọ ọ̀gbọ̀ bo ìhòhò rẹ̀ àwọn ọmọ-ogun gbìyànjú láti mú òun náà. Ó sì fi aṣọ funfun náà sílẹ̀ fún wọn, ó sì sálọ ní ìhòhò.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa