Mak 14:33-36
Mak 14:33-36 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si mu Peteru ati Jakọbu ati Johanu pẹlu rẹ̀, ẹnu si bẹrẹ si yà a gidigidi, o si bẹré si rẹ̀wẹsi. O si wi fun wọn pẹ, Ọkàn mi nkãnu gidigidi titi de ikú: ẹ duro nihin, ki ẹ si mã ṣọna. O si lọ siwaju diẹ, o si dojubolẹ, o si gbadura pe, bi o ba le ṣe, ki wakati na le kọja kuro lori rẹ̀. O si wipe, Abba, Baba, ṣiṣe li ohun gbogbo fun ọ; mú ago yi kuro lori mi: ṣugbọn kì iṣe eyiti emi fẹ, bikoṣe eyiti iwọ fẹ
Mak 14:33-36 Yoruba Bible (YCE)
Ó wá mú Peteru, Jakọbu ati Johanu pẹlu rẹ̀. Àyà bẹ̀rẹ̀ sí pá a, ó bẹ̀rẹ̀ sí dààmú. Ó wí fún wọn pé, “Ọkàn mi bàjẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí mo fẹ́rẹ̀ lè kú. Ẹ dúró níhìn-ín kí ẹ máa ṣọ́nà.” Ó bá lọ sí iwájú díẹ̀, ó dojúbolẹ̀, ó ń gbadura pé bí ó bá ṣeéṣe kí àkókò yìí kọjá lórí òun. Ó ní, “Baba, Baba, ohun gbogbo ṣeéṣe fún ọ. Mú kí ife kíkorò yìí kọjá kúrò lórí mi. Ṣugbọn ìfẹ́ tìrẹ ni kí o ṣe, kì í ṣe ìfẹ́ tèmi.”
Mak 14:33-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì mú Peteru àti Jakọbu àti Johanu lọ pẹ̀lú rẹ̀. Òun sì kún fún ìrẹ̀wẹ̀sì àti ìbànújẹ́ gidigidi. Ó sì wí fún wọn pé, “ọkàn mi ń káàánú gidigidi títí dé ojú ikú. Ẹ dúró níhìn-ín kí ẹ sì máa bá mi ṣọ́nà.” Ó sì lọ síwájú díẹ̀, ó dojúbo ilẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí i gbàdúrà pé, bí ó bá ṣe e ṣe kí wákàtí tí ó bọ̀ náà ré òun kọjá. Ó sì wí pé, “Ábbà, Baba, ìwọ lè ṣe ohun gbogbo, mú ago yìí kúrò lórí mi, ṣùgbọ́n kì í ṣe èyí tí èmi fẹ́, bí kò ṣe èyí tí ìwọ fẹ́.”