Mak 14:32-39
Mak 14:32-39 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nwọn si wá si ibi kan ti a npè ni Getsemane: o si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ joko nihinyi, nigbati mo ba lọ igbadura. O si mu Peteru ati Jakọbu ati Johanu pẹlu rẹ̀, ẹnu si bẹrẹ si yà a gidigidi, o si bẹré si rẹ̀wẹsi. O si wi fun wọn pẹ, Ọkàn mi nkãnu gidigidi titi de ikú: ẹ duro nihin, ki ẹ si mã ṣọna. O si lọ siwaju diẹ, o si dojubolẹ, o si gbadura pe, bi o ba le ṣe, ki wakati na le kọja kuro lori rẹ̀. O si wipe, Abba, Baba, ṣiṣe li ohun gbogbo fun ọ; mú ago yi kuro lori mi: ṣugbọn kì iṣe eyiti emi fẹ, bikoṣe eyiti iwọ fẹ, O si wá, o ba wọn, nwọn nsùn, o si wi fun Peteru pe, Simoni, iwọ nsùn? iwọ kò le ṣọna ni wakati kan? Ẹ mã ṣọna, kì ẹ si mã gbadura, ki ẹ má ba bọ́ sinu idẹwò. Lõtọ li ẹmí nfẹ, ṣugbọn o ṣe ailera fun ara. O si tún pada lọ, o si gbadura, o nsọ ọ̀rọ kanna.
Mak 14:32-39 Yoruba Bible (YCE)
Wọ́n dé ibìkan tí wọn ń pè ní Gẹtisemani. Ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jókòó níhìn-ín nígbà tí mo bá lọ gbadura.” Ó wá mú Peteru, Jakọbu ati Johanu pẹlu rẹ̀. Àyà bẹ̀rẹ̀ sí pá a, ó bẹ̀rẹ̀ sí dààmú. Ó wí fún wọn pé, “Ọkàn mi bàjẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí mo fẹ́rẹ̀ lè kú. Ẹ dúró níhìn-ín kí ẹ máa ṣọ́nà.” Ó bá lọ sí iwájú díẹ̀, ó dojúbolẹ̀, ó ń gbadura pé bí ó bá ṣeéṣe kí àkókò yìí kọjá lórí òun. Ó ní, “Baba, Baba, ohun gbogbo ṣeéṣe fún ọ. Mú kí ife kíkorò yìí kọjá kúrò lórí mi. Ṣugbọn ìfẹ́ tìrẹ ni kí o ṣe, kì í ṣe ìfẹ́ tèmi.” Ó pada lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mẹta, ó rí i pé wọ́n ti sùn lọ! Ó wí fún Peteru pé, “Simoni, ò ń sùn ni? O kò lè ṣọ́nà fún wakati kan péré? Gbogbo yín, ẹ máa ṣọ́nà, kí ẹ tún máa gbadura, kí ẹ má baà bọ́ sinu ìdánwò. Ẹ̀mí fẹ́ ṣe é, ṣugbọn ara kò lágbára.” Ó tún lọ gbadura, ó sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan náà bíi ti àkọ́kọ́.
Mak 14:32-39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí wọ́n dé ibi kan tí wọ́n ń pè ní ọgbà Getsemane. Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jókòó dè mí níhìn-ín títí n ó fi lọ gbàdúrà.” Ó sì mú Peteru àti Jakọbu àti Johanu lọ pẹ̀lú rẹ̀. Òun sì kún fún ìrẹ̀wẹ̀sì àti ìbànújẹ́ gidigidi. Ó sì wí fún wọn pé, “ọkàn mi ń káàánú gidigidi títí dé ojú ikú. Ẹ dúró níhìn-ín kí ẹ sì máa bá mi ṣọ́nà.” Ó sì lọ síwájú díẹ̀, ó dojúbo ilẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí i gbàdúrà pé, bí ó bá ṣe e ṣe kí wákàtí tí ó bọ̀ náà ré òun kọjá. Ó sì wí pé, “Ábbà, Baba, ìwọ lè ṣe ohun gbogbo, mú ago yìí kúrò lórí mi, ṣùgbọ́n kì í ṣe èyí tí èmi fẹ́, bí kò ṣe èyí tí ìwọ fẹ́.” Nígbà tí ó sì padà dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́ta, ó bá wọn lójú oorun. Ó sì wí fún Peteru pé, “Simoni, o ń sùn ni? Ìwọ kò lè bá mi ṣọ́nà fún wákàtí kan? Ẹ máa ṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà, ki ẹ má ba à bọ́ sínú ìdánwò. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ‘Ẹ̀mí ń fẹ́ ṣùgbọ́n ó ṣe àìlera fún ara.’ ” Ó sì tún lọ lẹ́ẹ̀kan sí i. Ó sì gbàdúrà gẹ́gẹ́ bí ó ti gbà á ti ìṣáájú.