Mak 14:22-24
Mak 14:22-24 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi nwọn si ti njẹun, Jesu mu akara, o si sure, o si bu u, o si fifun wọn, o wipe, Gbà, jẹ: eyiyi li ara mi. O si gbe ago, nigbati o si sure tan, o fifun wọn: gbogbo nwọn si mu ninu rẹ̀. O si wi fun wọn pe, Eyi li ẹ̀jẹ mi ti majẹmu titun, ti a ta silẹ fun ọ̀pọ enia.
Mak 14:22-24 Yoruba Bible (YCE)
Bí wọ́n ti ń jẹun, Jesu mú burẹdi, ó gbadura sí i, ó bù ú, ó fún wọn. Ó ní, “Ẹ gbà, èyí ni ara mi.” Ó tún mú ife, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, ó bá gbé e fún wọn. Gbogbo wọn mu ninu rẹ̀. Ó wí fún wọn pé, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi tí a fi dá majẹmu, ẹ̀jẹ̀ tí a ta sílẹ̀ fún ọpọlọpọ eniyan.
Mak 14:22-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí wọ́n ti ń jẹun lọ́wọ́, Jesu mú ìṣù àkàrà kan, ó gbàdúrà sí i. Lẹ́yìn náà ó bù ú sí wẹ́wẹ́, ó sì fi fún wọn. Ó wí pé, “Ẹ gbà jẹ, èyí yìí ni ara mi.” Bákan náà, ó sì mú ago wáìnì, ó dúpẹ́ fún un, ó sì gbé e fún wọn. Gbogbo wọn sì mu nínú rẹ̀. Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi tí májẹ̀mú tuntun, tí a ta sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.