Mak 14:12-25

Mak 14:12-25 Bibeli Mimọ (YBCV)

Li ọjọ kini ajọ aiwukara, nigbati nwọn npa ẹran irekọja, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si wi fun u pe, Nibo ni iwọ nfẹ ki a lọ ipèse silẹ, ki iwọ́ ki o le jẹ irekọja. O si rán awọn meji ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Ẹ lọ si ilu, ọkunrin kan ti nrù ìṣa omi yio pade nyin: ẹ mã tọ̀ ọ lẹhin. Ati ibikibi ti o ba gbé wọ̀, ki ẹnyin ki o wi fun bãle na pe, Olukọni wipe, Nibo ni gbọ̀ngan apejẹ na gbé wà, nibiti emi o gbé jẹ irekọja pẹlu awọn ọmọ-ẹhin mi? On o si fi gbọ̀ngan nla kan loke hàn nyin, ti a ṣe lọṣọ, ti a si pèse tẹlẹ; nibẹ̀ ni ki ẹnyin ki o pèse silẹ dè wa. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si jade lọ, nwọn wá si ilu, nwọn si ri i gẹgẹ bi o ti sọ fun wọn: nwọn si pèse irekọja silẹ. Nigbati alẹ lẹ, o wá pẹlu awọn mejila. Bi nwọn si ti joko ti nwọn njẹun, Jesu wipe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ọkan ninu nyin yio fi mi hàn, ani on na ti mba mi jẹun. Nwọn si bẹ̀rẹ si ikãnu gidigidi, ati si ibi i lẽre lọkọ̃kan wipe, Emi ni bi? Ekeji si wipe, Emi ni bi? O si dahùn o si wi fun wọn pe, Ọkan ninu awọn mejila ni, ti o ntọwọ bọ̀ inu awo pẹlu mi. Nitõtọ Ọmọ-enia nlọ bi a ti kọwe nipa tirẹ̀: ṣugbọn egbé ni fun ọkunrin na, lọdọ ẹniti a gbé ti fi Ọmọ-enia hàn! iba san fun ọkunrin na, bi o ṣepe a kò bí i. Bi nwọn si ti njẹun, Jesu mu akara, o si sure, o si bu u, o si fifun wọn, o wipe, Gbà, jẹ: eyiyi li ara mi. O si gbe ago, nigbati o si sure tan, o fifun wọn: gbogbo nwọn si mu ninu rẹ̀. O si wi fun wọn pe, Eyi li ẹ̀jẹ mi ti majẹmu titun, ti a ta silẹ fun ọ̀pọ enia. Lõtọ ni mo wi fun nyin, emi kì yio mu ninu eso ajara mọ́, titi yio fi di ọjọ na, nigbati emi o mu u ni titun ni ijọba Ọlọrun.

Mak 14:12-25 Yoruba Bible (YCE)

Ní ọjọ́ kinni Àjọ̀dún Àìwúkàrà, ní ọjọ́ tí wọn máa ń pa aguntan láti ṣe Àjọ̀dún Ìrékọjá, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu bi í pé, “Níbo ni o fẹ́ kí á tọ́jú fún ọ láti jẹ àsè Ìrékọjá?” Ó bá rán meji ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sí inú ìlú, ọkunrin kan tí ó ru ìkòkò omi yóo pàdé yín, ẹ tẹ̀lé e. Kí ẹ sọ fún baálé ilé tí ó bá wọ̀ pé, ‘Olùkọ́ni wí pé yàrá wo ni ààyè wà fún mi, níbi tí èmi ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi ti lè jẹ àsè Ìrékọjá?’ Yóo fi yàrá ńlá kan hàn yín, ní òkè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì, tí wọn ti tọ́jú sílẹ̀. Níbẹ̀ ni kí ẹ ṣe ètò sí.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà bá lọ, wọ́n wọ inú ìlú, wọ́n rí ohun gbogbo bí Jesu ti sọ fún wọn; wọ́n sì tọ́jú gbogbo nǹkan fún àsè Ìrékọjá. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, Jesu wá sibẹ pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila. Bí wọ́n ti jókòó tí wọn ń jẹun, Jesu ní, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ọ̀kan ninu yín tí ń bá mi jẹun nisinsinyii ni yóo fi mí lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́.” Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí dààmú, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ń bèèrè pé, “Àbí èmi ni?” Ṣugbọn ó wí fún wọn pé, “Ọ̀kan ninu ẹ̀yin mejeejila ni, tí ó ń fi òkèlè run ọbẹ̀ pẹlu mi ninu àwo kan náà. Nítorí Ọmọ-Eniyan ń lọ gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ nípa rẹ̀, ṣugbọn ẹni tí yóo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ gbé! Ìbá sàn fún un bí a kò bá bí i.” Bí wọ́n ti ń jẹun, Jesu mú burẹdi, ó gbadura sí i, ó bù ú, ó fún wọn. Ó ní, “Ẹ gbà, èyí ni ara mi.” Ó tún mú ife, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, ó bá gbé e fún wọn. Gbogbo wọn mu ninu rẹ̀. Ó wí fún wọn pé, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi tí a fi dá majẹmu, ẹ̀jẹ̀ tí a ta sílẹ̀ fún ọpọlọpọ eniyan. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé n kò ní mu ninu èso àjàrà mọ́ títí di ọjọ́ tí n óo mu ún ní ọ̀tun ninu ìjọba Ọlọrun.”

Mak 14:12-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní ọjọ́ kìn-ín-ní àjọ̀dún ìrékọjá tí í ṣe ọjọ́ tí wọ́n máa ń pa ẹran àgùntàn fún ìrúbọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu bi í léèrè pé, “Níbo ni ìwọ fẹ́ kí a lọ pèsè sílẹ̀ tí ìwọ yóò ti jẹ àsè ìrékọjá?” Ó rán méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, lọ, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sínú ìlú, ọkùnrin kan tó ru ìkòkò omi yóò pàdé yín, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. Ilé tí ọkùnrin náà bá wọ̀, kí ẹ wí fún baálé náà pé, ‘Olùkọ́ rán wa pé: Níbo ni gbàngàn àpèjẹ náà gbé wa, níbi tí èmi yóò gbé jẹ àsè ìrékọjá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi?’ Òun yóò sì mú un yín lọ sí gbàngàn ńlá kan lókè ilé náà, tí a ti ṣe lọ́sọ́. Níbẹ̀ ni kí ẹ pèsè sílẹ̀ dè wá.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì náà sì jáde lọ àárín ìlú. Wọ́n bá gbogbo nǹkan gẹ́gẹ́ bí Jesu tí sọ fún wọn. Wọ́n sì pèsè àsè ìrékọjá. Nígbà tí ó di alẹ́, Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ dé síbẹ̀. Bí wọ́n sì ti jókòó yí tábìlì ká, tí wọ́n ń jẹun, Jesu wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, ọ̀kan nínú ẹ̀yin tí ẹ ń bá mi jẹun yìí ni yóò fi mí hàn.” Ọkàn wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí í dàrú. Olúkúlùkù sì ń bi í ní ọ̀kọ̀ọ̀kan wí pé, “Dájúdájú, kì í ṣe èmi?” Ó sì dáhùn wí pé, “Ọ̀kan nínú ẹ̀yin méjìlá tí ó ń bá mi tọwọ́ bọ àwo jẹun nísinsin yìí ni. Nítòótọ́ Ọmọ Ènìyàn ń lọ bí a ti kọ̀wé nípa rẹ̀: Ṣùgbọ́n ègbé ní fún ọkùnrin náà, láti ọwọ́ ẹni tí a ti fi Ọmọ Ènìyàn hàn. Ìbá sàn fún un bí a kò bá bí i rárá.” Bí wọ́n ti ń jẹun lọ́wọ́, Jesu mú ìṣù àkàrà kan, ó gbàdúrà sí i. Lẹ́yìn náà ó bù ú sí wẹ́wẹ́, ó sì fi fún wọn. Ó wí pé, “Ẹ gbà jẹ, èyí yìí ni ara mi.” Bákan náà, ó sì mú ago wáìnì, ó dúpẹ́ fún un, ó sì gbé e fún wọn. Gbogbo wọn sì mu nínú rẹ̀. Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi tí májẹ̀mú tuntun, tí a ta sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn. Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, èmi kò tún ní mu ọtí wáìnì mọ́ títí yóò fi di ọjọ́ náà tí Èmi yóò mu ún ní tuntun nínú ìjọba Ọlọ́run.”