Mak 14:1-10

Mak 14:1-10 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí Àjọ̀dún Ìrékọjá ati ti Àìwúkàrà ku ọ̀tunla, àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin ń wá ọ̀nà tí wọn yóo fi rí Jesu mú, kí wọ́n pa á. Nítorí wọ́n ń wí pé, “Kí ó má jẹ́ àkókò àjọ̀dún, kí rògbòdìyàn má baà bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn eniyan.” Nígbà tí Jesu wà ní Bẹtani, bí ó ti jókòó tí ó fẹ́ máa jẹun ní ilé Simoni tí ó dẹ́tẹ̀ nígbà kan rí, obinrin kan wọlé wá tí ó mú ìgò ojúlówó òróró ìpara olóòórùn dídùn kan tí ó ní iye lórí lọ́wọ́. Ó fọ́ ìgò náà, ó bá tú òróró inú rẹ̀ sí Jesu lórí. Ṣugbọn inú bí àwọn kan níbẹ̀, wọ́n ń sọ̀ láàrin ara wọn pé, “Kí ló dé tí a fi ń fi òróró yìí ṣòfò báyìí? Bí a bá tà á, ìbá tó nǹkan bí ọọdunrun (300) owó fadaka, à bá sì fún àwọn talaka.” Báyìí ni wọ́n ń fi ohùn líle bá obinrin náà wí. Ṣugbọn Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ fi í sílẹ̀, kí ni ẹ̀ ń yọ ọ́ lẹ́nu sí? Ohun rere ni ó ṣe sí mi. Nítorí ìgbà gbogbo ni ẹ ní àwọn talaka láàrin yín, nígbàkúùgbà tí ẹ bá fẹ́, ẹ lè ṣe nǹkan fún wọn; ṣugbọn kì í ṣe ìgbà gbogbo ni èmi yóo máa wà láàrin yín. Ó ti ṣe ohun tí ó lè ṣe: ó fi òróró kun ara mi ní ìpalẹ̀mọ́ ìsìnkú mi. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, a óo máa sọ ohun tí obinrin yìí ṣe ní ìrántí rẹ̀ níbikíbi tí a bá ń waasu ìyìn rere ní gbogbo ayé.” Judasi Iskariotu, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila, bá lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí alufaa, ó lọ fi Jesu lé wọn lọ́wọ́.

Mak 14:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Lẹ́yìn ọjọ́ méjì ni àjọ ìrékọjá àti tí àìwúkàrà, àti àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin sì ń wá ọ̀nà láti mú Jesu ní ìkọ̀kọ̀, kí wọn sì pa á. Ṣùgbọ́n wọ́n wí pé, “A kò ní mú un ní ọjọ́ àjọ, kí àwọn ènìyàn má bá á fa ìjàngbọ̀n.” Nígbà tí ó sì wà ní Betani ni ilé Simoni adẹ́tẹ̀ bí ó ti jókòó ti oúnjẹ, obìnrin kan wọlé, ti òun ti alabasita òróró ìkunra olówó iyebíye, ó ṣí ìgò náà, ó sì da òróró náà lé Jesu lórí. Àwọn kan nínú àwọn tí ó jókòó ti tábìlì kún fún ìbànújẹ́. Wọ́n sì ń bi ara wọn pé, “Nítorí kí ni a ṣe fi òróró yìí ṣòfò? Òun ìbá ta òróró ìkunra yìí ju owó iṣẹ́ ọdún kan lọ, kí ó sì fi owó rẹ̀ ta àwọn tálákà lọ́rẹ.” Báyìí ni wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ gún obìnrin náà lára. Ṣùgbọ́n Jesu wí fún pé, “Ẹ fi í sílẹ̀, kí ni ẹ ń yọ ọ́ lẹ́nu fún ṣé nítorí tí ó ṣe ohun rere sí mi? Nígbà gbogbo ni àwọn tálákà wà ní àárín yín, wọ́n sì ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ yín. Ẹ sì lè ṣe oore fún wọn nígbàkúgbà tí ẹ bá fẹ́. Ó ti ṣe èyí tí ó lè ṣe, o ti fi òróró kùn mí ni ara ní ìmúrasílẹ̀ de ìgbà tí wọn yóò sin òkú mi. Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, níbikíbi tí wọ́n bá ti wàásù mi, ní gbogbo ayé, wọn kò ní ṣe aláìsọ ohun tí obìnrin yìí ṣe pẹ̀lú ní ìrántí rẹ̀.” Nígbà náà ni Judasi Iskariotu, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà, láti ṣètò bí yóò ti fi Jesu lé wọn lọ́wọ́.