Mak 11:25-26
Mak 11:25-26 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati ẹnyin ba si duro ngbadura, ẹ darijì, bi ẹnyin ba ni ohunkohun si ẹnikẹni: ki Baba nyin ti mbẹ li ọrun ba le dari ẹṣẹ nyin jì nyin pẹlu. Ṣugbọn bi ẹnyin ko ba dariji, Baba nyin ti mbẹ li ọrun kì yio si dari ẹ̀ṣẹ nyin jì nyin.
Pín
Kà Mak 11Mak 11:25-26 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ẹ bá dìde dúró láti gbadura, ẹ dáríjì ẹnikẹ́ni tí ẹ bá ní ohunkohun ninu sí, kí Baba yín ọ̀run lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín. [ Bí ẹ kò bá dárí ji eniyan, Baba yín ọ̀run kò ní dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.”]
Pín
Kà Mak 11Mak 11:25-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí ẹ bá ń gbàdúrà, ẹ kọ́kọ́ dáríjì, bí ẹ̀yin bá ní ohunkóhun sí ẹnikẹ́ni, kí baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run bá à le dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tiyín náà jì yín. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá dáríjì, Baba yín ti ń bẹ ni ọ̀run kí yóò dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.”
Pín
Kà Mak 11