Mak 11:24-25
Mak 11:24-25 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina mo wi fun nyin, Ohunkohun ti ẹnyin ba tọrọ nigbati ẹ ba ngbadura, ẹ gbagbọ́ pe ẹ ti ri wọn gbà na, yio si ri bẹ̃ fun nyin. Nigbati ẹnyin ba si duro ngbadura, ẹ darijì, bi ẹnyin ba ni ohunkohun si ẹnikẹni: ki Baba nyin ti mbẹ li ọrun ba le dari ẹṣẹ nyin jì nyin pẹlu.
Mak 11:24-25 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí èyí, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé, ohun gbogbo tí ẹ bá bèèrè ninu adura, ẹ gbàgbọ́ pé ẹ ti rí i gbà, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fun yín. Nígbà tí ẹ bá dìde dúró láti gbadura, ẹ dáríjì ẹnikẹ́ni tí ẹ bá ní ohunkohun ninu sí, kí Baba yín ọ̀run lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín. [
Mak 11:24-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Torí náà, mo wí fún yín ohunkóhun tí ẹ bá béèrè fún nínú àdúrà, ẹ ní ìgbàgbọ́ pé, ó tí tẹ̀ yín lọ́wọ́, yóò sì jẹ́ tiyín. Nígbà tí ẹ bá ń gbàdúrà, ẹ kọ́kọ́ dáríjì, bí ẹ̀yin bá ní ohunkóhun sí ẹnikẹ́ni, kí baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run bá à le dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tiyín náà jì yín.