Mak 11:20-33

Mak 11:20-33 Bibeli Mimọ (YBCV)

Bi nwọn si ti nkọja lọ li owurọ, nwọn ri igi ọpọtọ na gbẹ ti gbongbo ti gbongbo. Peteru si wa iranti o wi fun u pe, Rabbi, wò bi igi ọpọtọ ti iwọ fi bú ti gbẹ. Jesu si dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹ ni igbagbọ́ si Ọlọrun. Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ti o ba wi fun òke yi pe, Ṣidi, ki o si bọ sinu okun; ti kò ba si ṣiyemeji li ọkàn rẹ̀, ṣugbọn ti o ba gbagbọ́ pe ohun ti on wi yio ṣẹ, yio ri bẹ̃ fun u. Nitorina mo wi fun nyin, Ohunkohun ti ẹnyin ba tọrọ nigbati ẹ ba ngbadura, ẹ gbagbọ́ pe ẹ ti ri wọn gbà na, yio si ri bẹ̃ fun nyin. Nigbati ẹnyin ba si duro ngbadura, ẹ darijì, bi ẹnyin ba ni ohunkohun si ẹnikẹni: ki Baba nyin ti mbẹ li ọrun ba le dari ẹṣẹ nyin jì nyin pẹlu. Ṣugbọn bi ẹnyin ko ba dariji, Baba nyin ti mbẹ li ọrun kì yio si dari ẹ̀ṣẹ nyin jì nyin. Nwọn si tún wá si Jerusalemu: bi o si ti nrìn kiri ni tẹmpili, awọn olori alufa, ati awọn akọwe, ati awọn agbàgba, tọ̀ ọ wá, Nwọn si wi fun u pe, Aṣẹ wo li o fi nṣe nkan wọnyi? tali o si fun ọ li aṣẹ yi lati mã ṣe nkan wọnyi? Jesu si dahùn o si wi fun wọn pe, Emi ó bi nyin lẽre ọ̀rọ kan, ki ẹ si da mi lohùn, emi o si sọ fun nyin aṣẹ ti emi fi nṣe nkan wọnyi. Baptismu Johanu lati ọrun wá ni, tabi lati ọdọ enia? ẹ da mi lohùn. Nwọn si ba ara wọn gbèro, wipe, Bi awa ba wipe, Lati ọrun wá ni: on o wipe, Ẽha ti ṣe ti ẹnyin ko fi gbà a gbọ́? Ṣugbọn bi awa ba wipe, Lati ọdọ enia; nwọn bẹ̀ru awọn enia: nitori gbogbo enia kà Johanu si woli nitõtọ. Nwọn si dahùn wi fun Jesu pe, Awa kó mọ̀. Jesu si dahùn wi fun wọn pe, Emi kì yio si wi fun nyin aṣẹ ti emi fi nṣe nkan wọnyi.

Mak 11:20-33 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí ó di òwúrọ̀, bí wọ́n ti ń kọjá lọ, wọ́n rí i tí igi ọ̀pọ̀tọ́ àná ti gbẹ patapata láti orí dé gbòǹgbò. Peteru wá ranti ọ̀rọ̀ àná. Ó wí fún Jesu pé, “Olùkọ́ni, wo igi ọ̀pọ̀tọ́ tí o fi gégùn-ún, ó ti gbẹ!” Jesu dáhùn, ó wí fún wọn pé, “Ẹ ní igbagbọ ninu Ọlọrun; mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, bí ẹnikẹ́ni bá wí fún òkè yìí pé, ‘ṣídìí kúrò níbi tí o wà, kí o bọ́ sí inú òkun,’ tí kò bá ṣiyèméjì, ṣugbọn tí ó gbàgbọ́ pé, ohun tí òun wí yóo rí bẹ́ẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún un. Nítorí èyí, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé, ohun gbogbo tí ẹ bá bèèrè ninu adura, ẹ gbàgbọ́ pé ẹ ti rí i gbà, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fun yín. Nígbà tí ẹ bá dìde dúró láti gbadura, ẹ dáríjì ẹnikẹ́ni tí ẹ bá ní ohunkohun ninu sí, kí Baba yín ọ̀run lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín. [ Bí ẹ kò bá dárí ji eniyan, Baba yín ọ̀run kò ní dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.”] Wọ́n tún wá sí Jerusalẹmu. Bí Jesu ti ń rìn kiri ninu Tẹmpili, àwọn olórí alufaa, ati àwọn amòfin, ati àwọn àgbà wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Wọ́n ń bi í pé, “Irú àṣẹ wo ni o fi ń ṣe nǹkan wọnyi? Ta ni ó fún ọ ní àṣẹ tí o fi ń ṣe wọ́n?” Jesu dá wọn lóhùn, ó ní, “N óo bi yín léèrè ọ̀rọ̀ kan, ẹ dá mi lóhùn, èmi náà óo wá sọ irú àṣẹ tí mo fi ń ṣe nǹkan wọnyi. Ìrìbọmi tí Johanu ń ṣe, láti ọ̀run ni ó ti gba àṣẹ ni, tabi láti ọwọ́ eniyan? Ẹ dá mi lóhùn.” Nígbà náà ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn jiyàn pé, “Bí a bá wí pé, ‘Láti ọ̀run ni,’ yóo sọ pé, ‘Kí ló dé tí ẹ kò fi gbà á gbọ́?’ Àbí kí a wí pé, ‘Láti ọwọ́ eniyan ni?’ ” Wọ́n bẹ̀rù àwọn eniyan nítorí gbogbo eniyan ni ó gbà pé wolii tòótọ́ ni Johanu. Wọ́n bá dá Jesu lóhùn pé, “Àwa kò mọ̀.” Nígbà náà ni Jesu sọ fún wọn pé, “Èmi náà kò ní sọ irú àṣẹ tí mo fi ń ṣe àwọn nǹkan wọnyi fun yín.”

Mak 11:20-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, bí wọ́n ti ń kọjá lọ, wọ́n rí igi ọ̀pọ̀tọ́ tí Jesu fi bú. Wọ́n rí i pé ó ti gbẹ tigbòǹgbò tigbòǹgbò. Peteru rántí pé Jesu ti bá igi náà wí. Nígbà náà ni ó sọ fún Jesu pé, “Rabbi, Wò ó! Igi ọ̀pọ̀tọ́ tí ìwọ fi bú ti gbẹ!” Jesu sì dáhùn pé, “Ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, Lóòótọ́ ni mò wí fún un yín, bí ẹnikẹ́ni bá wí fún òkè ‘ṣídìí, gbé ara rẹ sọ sínú Òkun’ ti kò sì ṣe iyèméjì nínú ọkàn rẹ̀ ṣùgbọ́n tí ó gbàgbọ́ pé ohun tí òun wí yóò ṣẹ, yóò rí bẹ́ẹ̀ fún un. Torí náà, mo wí fún yín ohunkóhun tí ẹ bá béèrè fún nínú àdúrà, ẹ ní ìgbàgbọ́ pé, ó tí tẹ̀ yín lọ́wọ́, yóò sì jẹ́ tiyín. Nígbà tí ẹ bá ń gbàdúrà, ẹ kọ́kọ́ dáríjì, bí ẹ̀yin bá ní ohunkóhun sí ẹnikẹ́ni, kí baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run bá à le dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tiyín náà jì yín. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá dáríjì, Baba yín ti ń bẹ ni ọ̀run kí yóò dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.” Lẹ́yìn èyí, wọ́n tún padà sí Jerusalẹmu. Bí Jesu ti ń rìn kiri ni tẹmpili, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin pẹ̀lú àwọn àgbàgbà Júù wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Àṣẹ wo ni ó fi ń ṣe nǹkan yìí? Ta ni ó sì fún ọ ni àṣẹ yìí láti máa ṣe nǹkan wọ̀nyí?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi yóò bi yín léèrè ọ̀rọ̀ kan, kí ẹ sì dá mi lóhùn, èmi yóò sọ fún yín àṣẹ tí èmi fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí.” Ìtẹ̀bọmi Johanu láti ọ̀run wa ni, tàbí láti ọ̀dọ̀ ènìyàn? “Ẹ dá mi lóhùn!” Wọ́n bá ara wọn jíròrò pé: “Bí a bá wí pé láti ọ̀run wá ni, òun ó wí pé, ‘nígbà tí ẹ mọ̀ bẹ́ẹ̀, èéṣe tí ẹ kò fi gbà à gbọ́?’ Ṣùgbọ́n bí a bá wí pé, Láti ọ̀dọ̀ ènìyàn, wọ́n bẹ̀rù àwọn ènìyàn, nítorí pé gbogbo ènìyàn ló gbàgbọ́ pé wòlíì gidi ni Johanu.” Nítorí náà, Wọ́n kọjú sí Jesu wọn sì dáhùn pé, “Àwa kò mọ̀.” Nígbà náà ni Jesu wí pé, “Níwọ́n ìgbà tí ẹ kò lè dáhùn ìbéèrè mi, Èmi náà kì yóò sọ fún yín àṣẹ tí mo fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí.”