Mak 11:20-21
Mak 11:20-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi nwọn si ti nkọja lọ li owurọ, nwọn ri igi ọpọtọ na gbẹ ti gbongbo ti gbongbo. Peteru si wa iranti o wi fun u pe, Rabbi, wò bi igi ọpọtọ ti iwọ fi bú ti gbẹ.
Pín
Kà Mak 11Mak 11:20-21 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó di òwúrọ̀, bí wọ́n ti ń kọjá lọ, wọ́n rí i tí igi ọ̀pọ̀tọ́ àná ti gbẹ patapata láti orí dé gbòǹgbò. Peteru wá ranti ọ̀rọ̀ àná. Ó wí fún Jesu pé, “Olùkọ́ni, wo igi ọ̀pọ̀tọ́ tí o fi gégùn-ún, ó ti gbẹ!”
Pín
Kà Mak 11Mak 11:20-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, bí wọ́n ti ń kọjá lọ, wọ́n rí igi ọ̀pọ̀tọ́ tí Jesu fi bú. Wọ́n rí i pé ó ti gbẹ tigbòǹgbò tigbòǹgbò. Peteru rántí pé Jesu ti bá igi náà wí. Nígbà náà ni ó sọ fún Jesu pé, “Rabbi, Wò ó! Igi ọ̀pọ̀tọ́ tí ìwọ fi bú ti gbẹ!”
Pín
Kà Mak 11