Mak 11:11-21

Mak 11:11-21 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí ó wọ Jerusalẹmu, ó wọ àgbàlá Tẹmpili, ó wo ohun gbogbo yíká. Nítorí ọjọ́ ti lọ, ó jáde lọ sí Bẹtani pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila. Ní ọjọ́ keji, bí wọ́n ti ń jáde kúrò ní Bẹtani, ebi ń pa á. Ó rí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan tí ó ní ewé lókèèrè, ó bá lọ wò ó bí yóo rí èso lórí rẹ̀. Nígbà tí ó dé ìdí rẹ̀ kò rí ohunkohun àfi ewé, nítorí kò ì tíì tó àkókò èso. Jesu wí fún igi náà pé, “Kí ẹnikẹ́ni má rí èso jẹ lórí rẹ mọ́ lae!” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì gbọ́. Nígbà tí wọ́n dé Jerusalẹmu, Jesu wọ àgbàlá Tẹmpili lọ, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn tí wọn ń tà ati àwọn tí wọn ń rà jáde. Ó ti tabili àwọn onípàṣípààrọ̀ owó ṣubú, ó da ìsọ̀ àwọn tí ń ta ẹyẹlé rú. Kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni gbé ohunkohun la àgbàlá Tẹmpili kọjá. Ó ń kọ́ wọn pé, “Kò ha wà ninu àkọsílẹ̀ pé, ‘Ilé adura fún gbogbo orílẹ̀-èdè ni a óo máa pe ilé mi?’ Ṣugbọn ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ibi tí àwọn ọlọ́ṣà ń sápamọ́ sí!” Nígbà tí àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin gbọ́, wọ́n ń wá ọ̀nà tí wọn yóo fi pa á. Ṣugbọn wọ́n bẹ̀rù rẹ̀, nítorí ìyàlẹ́nu ni ẹ̀kọ́ rẹ̀ jẹ́ fún gbogbo eniyan. Nígbà tí ọjọ́ rọ̀ Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ jáde kúrò ní ìlú. Nígbà tí ó di òwúrọ̀, bí wọ́n ti ń kọjá lọ, wọ́n rí i tí igi ọ̀pọ̀tọ́ àná ti gbẹ patapata láti orí dé gbòǹgbò. Peteru wá ranti ọ̀rọ̀ àná. Ó wí fún Jesu pé, “Olùkọ́ni, wo igi ọ̀pọ̀tọ́ tí o fi gégùn-ún, ó ti gbẹ!”

Mak 11:11-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Jesu wọ Jerusalẹmu ó sì lọ sí inú tẹmpili. Ó wo ohun gbogbo yíká fínní fínní. Ó sì kúrò níbẹ̀, nítorí pé ilẹ̀ ti ṣú. Ó padà lọ sí Betani pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, bí wọ́n ti kúrò ní Betani, ebi ń pa Jesu. Ó rí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan lọ́ọ̀ọ́kán tí ewé kún orí rẹ̀. Nígbà náà, ó lọ sí ìdí rẹ̀ láti wò ó bóyá ó léso tàbí kò léso. Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ewé lásán ni ó rí, kò rí èso lórí rẹ̀. Nítorí pé àkókò náà kì í ṣe àkókò tí igi ọ̀pọ̀tọ́ máa ń so. Lẹ́yìn náà, Jesu pàṣẹ fún igi náà pé, “Kí ẹnikẹ́ni má ṣe jẹ èso lórí rẹ mọ́ títí láé.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́ nígbà tí ó wí bẹ́ẹ̀. Nígbà ti wọ́n padà sí Jerusalẹmu, ó wọ inú tẹmpili. Ó bẹ̀rẹ̀ sí nílé àwọn oníṣòwò àti àwọn oníbàárà wọn síta. Ó ti tábìlì àwọn tí ń pààrọ̀ owó nínú tẹmpili ṣubú. Bákan náà ni ó ti ìjókòó àwọn tí ń ta ẹyẹlé lulẹ̀. Kò sì gba ẹnikẹ́ni láààyè láti gbé ẹrù ọjà títà gba inú tẹmpili wọlé. Gẹ́gẹ́ bí ó ti kọ́ wọn, ó wí pé, “Ṣé a kò ti kọ ọ́ pé: ‘Ilé àdúrà ni a o máa pe ilé mi, ní gbogbo orílẹ̀-èdè?’ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ibùgbé àwọn ọlọ́ṣà.” Nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin gbọ́ ohun tí ó ti ṣe, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ń gbà èrò bí wọn yóò ti ṣe pa á. Wọ́n bẹ̀rù rògbòdìyàn tí yóò bẹ́ sílẹ̀, nítorí tí àwọn ènìyàn ní ìgbóná ọkàn sí ẹ̀kọ́ rẹ̀. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà, bí ìṣe wọn, Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ jáde kúrò ní ìlú Jerusalẹmu. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, bí wọ́n ti ń kọjá lọ, wọ́n rí igi ọ̀pọ̀tọ́ tí Jesu fi bú. Wọ́n rí i pé ó ti gbẹ tigbòǹgbò tigbòǹgbò. Peteru rántí pé Jesu ti bá igi náà wí. Nígbà náà ni ó sọ fún Jesu pé, “Rabbi, Wò ó! Igi ọ̀pọ̀tọ́ tí ìwọ fi bú ti gbẹ!”

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa