Mak 10:47-49
Mak 10:47-49 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati o gbọ́ pe, Jesu ti Nasareti ni, o bẹ̀rẹ si ikigbe lohùn rara, wipe, Jesu, iwọ Ọmọ Dafidi, ṣãnu fun mi. Ọpọlọpọ si ba a wipe, ki o pa ẹnu rẹ̀ mọ́: ṣugbọn on si kigbe si i jù bẹ̃ lọ pe, Iwọ Ọmọ Dafidi, ṣãnu fun mi. Jesu si dẹsẹ duro, o si paṣẹ pe ki a pè e wá. Nwọn si pè afọju na, nwọn wi fun u pe, Tùjuka, dide; o npè ọ.
Mak 10:47-49 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó gbọ́ pé Jesu ará Nasarẹti ni ó dé, ó bẹ̀rẹ̀ sí kígbe pé, “Jesu! Ọmọ Dafidi! Ṣàánú mi!” Ọpọlọpọ eniyan ń bá a wí pé kí ó panu mọ́. Ṣugbọn sibẹ ó túbọ̀ ń kígbe pé, “Ọmọ Dafidi! Ṣàánú mi.” Jesu bá dúró, ó ní, “Ẹ pè é wá.” Wọ́n wá wí fún afọ́jú náà pé, “Ṣe ara gírí, dìde, ó ń pè ọ́.”
Mak 10:47-49 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí Bartimeu gbọ́ pé Jesu ti Nasareti wà nítòsí, o bẹ̀rẹ̀ sí kígbe lóhùn rara pé, “Jesu ọmọ Dafidi, ṣàánú fún mi.” Àwọn tó wà níbẹ̀ kígbe mọ́ ọn pé, “Pa ẹnu rẹ mọ́.” Ṣùgbọ́n dípò kí ó pa ẹnu mọ́, ṣe ló ń kígbe lóhùn rara pé, “Jesu ọmọ Dafidi ṣàánú fún mi.” Nígbà tí Jesu gbọ́ igbe rẹ̀, ó dẹ́sẹ̀ dúró lójú ọ̀nà, ó sì wí pé, “Ẹ pè é kí ó wá sọ́dọ̀ mi.” Nítorí náà wọ́n pe ọkùnrin afọ́jú náà, wọ́n wí pé, “Tújúká! Dìde lórí ẹsẹ̀ rẹ! Ó ń pè ọ́.”