Mak 10:42-44
Mak 10:42-44 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn Jesu pè wọn sọdọ rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Ẹnyin mọ̀ pe, awọn ti a nkà si olori awọn Keferi, a ma lò ipá lori wọn: ati awọn ẹni-nla wọn a ma fi ọlá tẹri wọn ba. Ṣugbọn kì yio ri bẹ̃ lãrin nyin: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba fẹ tobi lãrin nyin, on ni yio ṣe iranṣẹ nyin: Ati ẹnikẹni ninu nyin ti o ba fẹ ṣe olori, on ni yio ṣe ọmọ-ọdọ gbogbo nyin.
Mak 10:42-44 Yoruba Bible (YCE)
Ni Jesu bá pè wọ́n, ó wí fún wọn pé, “Ẹ mọ̀ pé àwọn aláṣẹ láàrin àwọn alaigbagbọ a máa jẹ ọlá lórí wọn, àwọn eniyan ńláńlá ninu wọn a sì máa lo agbára lórí wọn, ṣugbọn tiyín kò gbọdọ̀ rí bẹ́ẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ jẹ́ pataki láàrin yín níláti jẹ́ iranṣẹ yín; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fẹ́ jẹ́ aṣaaju ninu yín níláti máa ṣe ẹrú gbogbo yín.
Mak 10:42-44 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Nítorí ìdí èyí, Jesu pè wọ́n sọ́dọ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé, àwọn ọba àti àwọn kèfèrí ń lo agbára lórí àwọn ènìyàn. Ṣùgbọ́n láàrín yín ko gbọdọ̀ ri bẹ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ di olórí nínú yín gbọdọ̀ ṣe ìránṣẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ di aṣáájú nínú yín gbọdọ̀ ṣe ìránṣẹ́ gbogbo yín.