Mak 1:35-39
Mak 1:35-39 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si dide li owurọ̀ ki ilẹ to mọ́, o si jade lọ si ibi iju kan, nibẹ li o si ngbadura. Simoni ati awọn ti o wà pẹlu rẹ̀ si nwá a. Nigbati nwọn si ri i, nwọn wi fun u pe, Gbogbo enia nwá ọ. O si wi fun wọn pe, Ẹ jẹ ki a lọ si ilu miran, ki emi ki o le wasu nibẹ̀ pẹlu: nitori eyi li emi sá ṣe wá. O si nwãsu ninu sinagogu wọn lọ ni gbogbo Galili, o si nlé awọn ẹmi èṣu jade.
Mak 1:35-39 Yoruba Bible (YCE)
Ní òwúrọ̀ kutukutu kí ilẹ̀ tó mọ́, Jesu dìde, ó jáde kúrò ní ilé, ó lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú láti gbadura níbi tí kò sí ẹnìkankan. Simoni ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀ bá ń wá a kiri. Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n wí fún un pé, “Gbogbo eniyan ní ń wá ọ.” Ṣugbọn ó wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ sí àwọn abúlé mìíràn tí ó wà ní ìtòsí kí n lè waasu níbẹ̀, nítorí ohun tí mo wá sí ayé fún ni èyí.” Ó bá lọ, ó ń waasu ninu àwọn ilé ìpàdé wọn ní gbogbo ilẹ̀ Galili, ó ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.
Mak 1:35-39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, kí ilẹ̀ tó mọ́, Jesu nìkan jáde lọ sí aginjù kan, láti lọ gbàdúrà. Simoni àti àwọn ènìyàn rẹ̀ yòókù lọ láti wá a. Nígbà tí wọ́n sì rí I, wọ́n sọ fún wí pé, “Gbogbo ènìyàn ń wá ọ!” Jesu sì dáhùn wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a lọ sí àwọn ìlú mìíràn, kí ń lè wàásù níbẹ̀ pẹ̀lú. Nítorí èyí ni èmi sá à ṣe wá.” Nítorí náà, ó ń kiri gbogbo agbègbè Galili, ó ń wàásù nínú Sinagọgu. Ó sì ń lé àwọn ẹ̀mí àìmọ́ jáde.