Mak 1:32-37
Mak 1:32-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí ó di àṣálẹ́, tí oòrùn wọ̀, wọ́n gbé gbogbo àwọn aláìsàn àti àwọn tó ni ẹ̀mí àìmọ́ tọ̀ ọ́ wá. Gbogbo ìlú si péjọ ni ẹnu-ọ̀nà. Jesu sì wo ọ̀pọ̀ tí wọ́n ní onírúurú ààrùn sàn. Bákan náà ni ó lé ọ̀pọ̀ ẹ̀mí àìmọ́ jáde, Ṣùgbọ́n kò sì jẹ́ kí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà kí ó sọ̀rọ̀, nítorí tí wọ́n mọ ẹni tí òun í ṣe. Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, kí ilẹ̀ tó mọ́, Jesu nìkan jáde lọ sí aginjù kan, láti lọ gbàdúrà. Simoni àti àwọn ènìyàn rẹ̀ yòókù lọ láti wá a. Nígbà tí wọ́n sì rí I, wọ́n sọ fún wí pé, “Gbogbo ènìyàn ń wá ọ!”
Mak 1:32-37 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati o di aṣalẹ, ti õrun wọ̀, nwọn gbe gbogbo awọn alaìsan, ati awọn ti o li ẹmi i èṣu tọ̀ ọ wá. Gbogbo ilu si pejọ li ẹnu-ọ̀na. O si wò ọ̀pọ awọn ti o ni onirũru àrun sàn, o si lé ọ̀pọ ẹmi èṣu jade; ko si jẹ ki awọn ẹmi èṣu na ki o fọhun, nitoriti nwọn mọ̀ ọ. O si dide li owurọ̀ ki ilẹ to mọ́, o si jade lọ si ibi iju kan, nibẹ li o si ngbadura. Simoni ati awọn ti o wà pẹlu rẹ̀ si nwá a. Nigbati nwọn si ri i, nwọn wi fun u pe, Gbogbo enia nwá ọ.
Mak 1:32-37 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, tí oòrùn wọ̀, àwọn eniyan bẹ̀rẹ̀ sí gbé gbogbo àwọn tí ara wọn kò dá ati àwọn tí wọ́n ní ẹ̀mí èṣù wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Gbogbo ìlú péjọ sí ẹnu ọ̀nà. Ó ṣe ìwòsàn fún ọpọlọpọ àwọn tí ó ní oríṣìíríṣìí àìsàn, ó tún lé ẹ̀mí èṣù jáde. Kò jẹ́ kí àwọn ẹ̀mí èṣù náà sọ̀rọ̀, nítorí wọ́n mọ ẹni tí ó jẹ́. Ní òwúrọ̀ kutukutu kí ilẹ̀ tó mọ́, Jesu dìde, ó jáde kúrò ní ilé, ó lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú láti gbadura níbi tí kò sí ẹnìkankan. Simoni ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀ bá ń wá a kiri. Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n wí fún un pé, “Gbogbo eniyan ní ń wá ọ.”