Mak 1:29-38
Mak 1:29-38 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati nwọn si jade kuro ninu sinagogu, lojukanna nwọn wọ̀ ile Simoni ati Anderu, pẹlu Jakọbu ati Johanu. Iya aya Simoni si dubulẹ aìsan ibà, nwọn si sọ ọ̀ran rẹ̀ fun u. O si wá, o fà a lọwọ, o si gbé e dide; lojukanna ibà na si fi i silẹ, o si nṣe iranṣẹ fun wọn. Nigbati o di aṣalẹ, ti õrun wọ̀, nwọn gbe gbogbo awọn alaìsan, ati awọn ti o li ẹmi i èṣu tọ̀ ọ wá. Gbogbo ilu si pejọ li ẹnu-ọ̀na. O si wò ọ̀pọ awọn ti o ni onirũru àrun sàn, o si lé ọ̀pọ ẹmi èṣu jade; ko si jẹ ki awọn ẹmi èṣu na ki o fọhun, nitoriti nwọn mọ̀ ọ. O si dide li owurọ̀ ki ilẹ to mọ́, o si jade lọ si ibi iju kan, nibẹ li o si ngbadura. Simoni ati awọn ti o wà pẹlu rẹ̀ si nwá a. Nigbati nwọn si ri i, nwọn wi fun u pe, Gbogbo enia nwá ọ. O si wi fun wọn pe, Ẹ jẹ ki a lọ si ilu miran, ki emi ki o le wasu nibẹ̀ pẹlu: nitori eyi li emi sá ṣe wá.
Mak 1:29-38 Yoruba Bible (YCE)
Bí wọ́n ti jáde kúrò ninu ilé ìpàdé, Jesu pẹlu Jakọbu ati Johanu lọ sí ilé Simoni ati Anderu. Ìyá iyawo Simoni wà ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn ibà. Lẹsẹkẹsẹ wọ́n sọ fún Jesu nípa rẹ̀. Ó bá lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó fà á lọ́wọ́ dìde. Ibà náà sì fi í sílẹ̀, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí tọ́jú oúnjẹ fún wọn. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, tí oòrùn wọ̀, àwọn eniyan bẹ̀rẹ̀ sí gbé gbogbo àwọn tí ara wọn kò dá ati àwọn tí wọ́n ní ẹ̀mí èṣù wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Gbogbo ìlú péjọ sí ẹnu ọ̀nà. Ó ṣe ìwòsàn fún ọpọlọpọ àwọn tí ó ní oríṣìíríṣìí àìsàn, ó tún lé ẹ̀mí èṣù jáde. Kò jẹ́ kí àwọn ẹ̀mí èṣù náà sọ̀rọ̀, nítorí wọ́n mọ ẹni tí ó jẹ́. Ní òwúrọ̀ kutukutu kí ilẹ̀ tó mọ́, Jesu dìde, ó jáde kúrò ní ilé, ó lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú láti gbadura níbi tí kò sí ẹnìkankan. Simoni ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀ bá ń wá a kiri. Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n wí fún un pé, “Gbogbo eniyan ní ń wá ọ.” Ṣugbọn ó wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ sí àwọn abúlé mìíràn tí ó wà ní ìtòsí kí n lè waasu níbẹ̀, nítorí ohun tí mo wá sí ayé fún ni èyí.”
Mak 1:29-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí wọn sì jáde kúrò nínú Sinagọgu, wọ́n lọ pẹ̀lú Jakọbu àti Johanu sí ilé Simoni àti Anderu. Ìyá ìyàwó Simoni tí ó dùbúlẹ̀ àìsàn ibà, wọ́n sì sọ fún Jesu nípa rẹ̀. Ó sì tọ̀ ọ́ lọ, ó fà á lọ́wọ́, ó sì gbé e dìde; lójúkan náà ibà náà fi sílẹ̀, ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún wọn. Nígbà tí ó di àṣálẹ́, tí oòrùn wọ̀, wọ́n gbé gbogbo àwọn aláìsàn àti àwọn tó ni ẹ̀mí àìmọ́ tọ̀ ọ́ wá. Gbogbo ìlú si péjọ ni ẹnu-ọ̀nà. Jesu sì wo ọ̀pọ̀ tí wọ́n ní onírúurú ààrùn sàn. Bákan náà ni ó lé ọ̀pọ̀ ẹ̀mí àìmọ́ jáde, Ṣùgbọ́n kò sì jẹ́ kí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà kí ó sọ̀rọ̀, nítorí tí wọ́n mọ ẹni tí òun í ṣe. Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, kí ilẹ̀ tó mọ́, Jesu nìkan jáde lọ sí aginjù kan, láti lọ gbàdúrà. Simoni àti àwọn ènìyàn rẹ̀ yòókù lọ láti wá a. Nígbà tí wọ́n sì rí I, wọ́n sọ fún wí pé, “Gbogbo ènìyàn ń wá ọ!” Jesu sì dáhùn wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a lọ sí àwọn ìlú mìíràn, kí ń lè wàásù níbẹ̀ pẹ̀lú. Nítorí èyí ni èmi sá à ṣe wá.”