Mak 1:21-28
Mak 1:21-28 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nwọn si lọ si Kapernaumu; lojukanna o si wọ̀ inu sinagogu li ọjọ, isimi, o si nkọ́ni. Ẹnu si yà wọn si ẹkọ́ rẹ̀: nitoriti o nkọ́ wọn bi ẹniti o li aṣẹ, kì isi ṣe bí awọn akọwe. Ọkunrin kan si wà ninu sinagogu wọn, ti o li ẹmi aimọ́; o si kigbe soke. O wipe, Jọwọ wa jẹ; kini ṣe tawa tirẹ, Jesu ara Nasareti? iwọ wá lati pa wa run? emi mọ̀ ẹniti iwọ ṣe, Ẹni-Mimọ́ Ọlọrun. Jesu si ba a wi, o wipe, Pa ẹnu rẹ mọ́, ki o si jade kuro lara rẹ̀. Nigbati ẹmi aimọ́ na si gbé e ṣanlẹ, o ke li ohùn rara, o si jade kuro lara rẹ̀. Hà si ṣe gbogbo wọn, tobẹ̃ ti nwọn fi mbi ara wọn lẽre, wipe, Kili eyi? ẹkọ́ titun li eyi? nitoriti o fi agbara paṣẹ fun awọn ẹmi aimọ́, nwọn si gbọ́ tirẹ̀. Lojukanna okikí rẹ̀ si kàn yi gbogbo ẹkùn Galili ká.
Mak 1:21-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn náà, Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ ìlú Kapernaumu, nígbà tí ó di òwúrọ̀ ọjọ́ ìsinmi, ó lọ sínú Sinagọgu, ó sì ń kọ́ni. Ẹnu sì ya ìjọ ènìyàn nítorí ìkọ́ni rẹ̀, nítorí pé ó ń kọ́ni bí ẹni tí ó ní àṣẹ, kì í ṣe bí àwọn olùkọ́ òfin ṣe ń kọ́ àwọn ènìyàn. Ní àsìkò náà gan an ni ọkùnrin kan tí ó wà nínú Sinagọgu wọn, tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́, bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe wí pé, “Kí ni ìwọ ń wá lọ́dọ̀ wa, Jesu ti Nasareti? Ṣé ìwọ wá láti pa wá run ni? Èmí mọ ẹni tí ìwọ í ṣe; Ìwọ ní ẹni Mímọ́ Ọlọ́run!” Jesu si bá a wí, ó wí pé, “Pa ẹnu rẹ mọ́, kí ó sì jáde kúrò lára rẹ̀.” Ẹ̀mí àìmọ́ náà sì gbé e ṣánlẹ̀ lógèdèǹgbé, ó ké ní ohùn rara, ó sì jáde kúrò lára ọkùnrin náà. Ẹnu sì ya àwọn ènìyàn, tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi ń sọ láàrín ara wọn ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀. Wọ́n béèrè pẹ̀lú ìgbóná ara, pé, “Kí ni èyí? Irú ẹ̀kọ́ tuntun wo ni èyí? Ó ń fi agbára pàṣẹ fún àwọn ẹ̀mí àìmọ́ pàápàá wọ́n sì gbọ́ tirẹ̀.” Ìròyìn nípa rẹ̀ tàn ká gbogbo agbègbè Galili.
Mak 1:21-28 Yoruba Bible (YCE)
Wọ́n lọ sí Kapanaumu. Ní Ọjọ́ Ìsinmi àwọn Juu, Jesu lọ sí ilé ìpàdé, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn eniyan. Ẹnu ya àwọn tí ó gbọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀, nítorí ó ń kọ́ wọn bí ẹni tí ó ní àṣẹ, yàtọ̀ sí bí àwọn amòfin ṣe ń kọ́ wọn. Ọkunrin kan wà ninu ilé ìpàdé náà tí ó ní ẹ̀mí èṣù. Ó bá kígbe tòò, ó ní, “Kí ni ó pa tàwa-tìrẹ pọ̀, Jesu ará Nasarẹti? Ṣé o dé láti pa wá run ni? Mo mọ ẹni tí o jẹ́. Ẹni Mímọ́ Ọlọrun ni ọ́.” Jesu bá bá a wí, ó ní, “Pa ẹnu mọ́, kí o jáde kúrò ninu ọkunrin yìí.” Ẹ̀mí èṣù náà bá gbo ọkunrin náà jìgìjìgì, ó kígbe tòò, ó sì jáde kúrò ninu ọkunrin náà. Kẹ́kẹ́ bá pamọ́ gbogbo àwọn eniyan lẹ́nu tóbẹ́ẹ̀ tí wọn ń wí láàrin ara wọn pé, “Kí ni èyí? Ẹ̀kọ́ titun ni! Pẹlu àṣẹ ni ó fi bá àwọn ẹ̀mí èṣù wí, wọ́n sì gbọ́ràn sí i lẹ́nu.” Òkìkí Jesu wá kan ká gbogbo ìgbèríko Galili.