Mak 1:14-45
Mak 1:14-45 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn ìgbà tí wọn ju Johanu sinu ẹ̀wọ̀n, Jesu wá sí Galili, ó ń waasu ìyìn rere tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá. Ó ń wí pé, “Àkókò tó; ìjọba Ọlọrun súnmọ́ ìtòsí. Ẹ ronupiwada, kí ẹ gba ìyìn rere gbọ́.” Bí Jesu ti ń rìn lọ lẹ́bàá òkun Galili, ó rí Simoni ati Anderu arakunrin rẹ̀ tí wọn ń da àwọ̀n sinu òkun, nítorí apẹja ni wọ́n. Jesu bá wí fún wọn pé, “Ẹ wá máa tẹ̀lé mi, èmi yóo sọ yín di ẹni tí ó ń fa eniyan bí a ti ń dẹ ẹja ninu omi.” Lẹ́sẹ̀ kan náà wọ́n bá fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n ń tẹ̀lé e. Bí ó ti rìn siwaju díẹ̀ sí i, ó rí Jakọbu ọmọ Sebede ati Johanu arakunrin rẹ̀ ninu ọkọ̀, wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe. Bí Jesu ti rí wọn, ó pè wọ́n. Wọ́n bá fi Sebede baba wọn sílẹ̀ ninu ọkọ̀ pẹlu àwọn alágbàṣe, wọ́n ń tẹ̀lé e. Wọ́n lọ sí Kapanaumu. Ní Ọjọ́ Ìsinmi àwọn Juu, Jesu lọ sí ilé ìpàdé, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn eniyan. Ẹnu ya àwọn tí ó gbọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀, nítorí ó ń kọ́ wọn bí ẹni tí ó ní àṣẹ, yàtọ̀ sí bí àwọn amòfin ṣe ń kọ́ wọn. Ọkunrin kan wà ninu ilé ìpàdé náà tí ó ní ẹ̀mí èṣù. Ó bá kígbe tòò, ó ní, “Kí ni ó pa tàwa-tìrẹ pọ̀, Jesu ará Nasarẹti? Ṣé o dé láti pa wá run ni? Mo mọ ẹni tí o jẹ́. Ẹni Mímọ́ Ọlọrun ni ọ́.” Jesu bá bá a wí, ó ní, “Pa ẹnu mọ́, kí o jáde kúrò ninu ọkunrin yìí.” Ẹ̀mí èṣù náà bá gbo ọkunrin náà jìgìjìgì, ó kígbe tòò, ó sì jáde kúrò ninu ọkunrin náà. Kẹ́kẹ́ bá pamọ́ gbogbo àwọn eniyan lẹ́nu tóbẹ́ẹ̀ tí wọn ń wí láàrin ara wọn pé, “Kí ni èyí? Ẹ̀kọ́ titun ni! Pẹlu àṣẹ ni ó fi bá àwọn ẹ̀mí èṣù wí, wọ́n sì gbọ́ràn sí i lẹ́nu.” Òkìkí Jesu wá kan ká gbogbo ìgbèríko Galili. Bí wọ́n ti jáde kúrò ninu ilé ìpàdé, Jesu pẹlu Jakọbu ati Johanu lọ sí ilé Simoni ati Anderu. Ìyá iyawo Simoni wà ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn ibà. Lẹsẹkẹsẹ wọ́n sọ fún Jesu nípa rẹ̀. Ó bá lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó fà á lọ́wọ́ dìde. Ibà náà sì fi í sílẹ̀, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí tọ́jú oúnjẹ fún wọn. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, tí oòrùn wọ̀, àwọn eniyan bẹ̀rẹ̀ sí gbé gbogbo àwọn tí ara wọn kò dá ati àwọn tí wọ́n ní ẹ̀mí èṣù wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Gbogbo ìlú péjọ sí ẹnu ọ̀nà. Ó ṣe ìwòsàn fún ọpọlọpọ àwọn tí ó ní oríṣìíríṣìí àìsàn, ó tún lé ẹ̀mí èṣù jáde. Kò jẹ́ kí àwọn ẹ̀mí èṣù náà sọ̀rọ̀, nítorí wọ́n mọ ẹni tí ó jẹ́. Ní òwúrọ̀ kutukutu kí ilẹ̀ tó mọ́, Jesu dìde, ó jáde kúrò ní ilé, ó lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú láti gbadura níbi tí kò sí ẹnìkankan. Simoni ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀ bá ń wá a kiri. Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n wí fún un pé, “Gbogbo eniyan ní ń wá ọ.” Ṣugbọn ó wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ sí àwọn abúlé mìíràn tí ó wà ní ìtòsí kí n lè waasu níbẹ̀, nítorí ohun tí mo wá sí ayé fún ni èyí.” Ó bá lọ, ó ń waasu ninu àwọn ilé ìpàdé wọn ní gbogbo ilẹ̀ Galili, ó ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Ẹnìkan tí ó ní àrùn ẹ̀tẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó ń bẹ̀ ẹ́ pé, “Bí o bá fẹ́, o lè sọ ara mi di mímọ́.” Àánú ṣe Jesu ó bá na ọwọ́ ó fi kàn án, ó ní, “Mo fẹ́. Di mímọ́.” Lẹsẹkẹsẹ àrùn ẹ̀tẹ̀ náà bá kúrò lára rẹ̀, ara rẹ̀ sì dá. Jesu fi ohùn líle kìlọ̀ fún un, lẹsẹkẹsẹ ó bá ní kí ó máa lọ. Ó wí fún un pé, “Má wí ohunkohun fún ẹnikẹ́ni. Ṣugbọn lọ fi ara rẹ han alufaa, kí o sì rúbọ ìwòsàn rẹ bí Mose ti pàṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí fún wọn pé ara rẹ ti dá.” Ṣugbọn ọkunrin náà jáde lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún ọpọlọpọ eniyan, ó ń rán ọ̀rọ̀ náà mọ́ ẹnu, tóbẹ́ẹ̀ tí Jesu kò fi lè wọ inú ìlú ní gbangba mọ́, ṣugbọn ó lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú níbi tí kò sí eniyan. Sibẹ àwọn eniyan ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti ibi gbogbo.
Mak 1:14-45 Bibeli Mimọ (YBCV)
Lẹhin igbati a fi Johanu sinu tubu tan, Jesu lọ si Galili, o nwasu ihinrere ijọba Ọlọrun, O si nwipe, Akokò na de, ijọba Ọlọrun si kù si dẹ̀dẹ: ẹ ronupiwada, ki ẹ si gbà ihinrere gbọ́. Bi o si ti nrìn leti okun Galili, o ri Simoni ati Anderu arakunrin rẹ̀, nwọn nsọ àwọn sinu okun: nitoriti nwọn ṣe apẹja. Jesu si wi fun wọn pe, Ẹ mã tọ̀ mi lẹhin, emi o si sọ nyin di apẹja enia. Lojukanna nwọn si fi àwọn wọn silẹ, nwọn si tọ̀ ọ lẹhin. Bi o si ti lọ siwaju diẹ, o ri Jakọbu ọmọ Sebede, ati Johanu arakunrin rẹ̀, nwọn wà ninu ọkọ̀, nwọn ndí àwọn wọn. Lojukanna o si pè wọn: nwọn si fi Sebede baba wọn silẹ ninu ọkọ̀ pẹlu awọn alagbaṣe, nwọn si tọ̀ ọ lẹhin. Nwọn si lọ si Kapernaumu; lojukanna o si wọ̀ inu sinagogu li ọjọ, isimi, o si nkọ́ni. Ẹnu si yà wọn si ẹkọ́ rẹ̀: nitoriti o nkọ́ wọn bi ẹniti o li aṣẹ, kì isi ṣe bí awọn akọwe. Ọkunrin kan si wà ninu sinagogu wọn, ti o li ẹmi aimọ́; o si kigbe soke. O wipe, Jọwọ wa jẹ; kini ṣe tawa tirẹ, Jesu ara Nasareti? iwọ wá lati pa wa run? emi mọ̀ ẹniti iwọ ṣe, Ẹni-Mimọ́ Ọlọrun. Jesu si ba a wi, o wipe, Pa ẹnu rẹ mọ́, ki o si jade kuro lara rẹ̀. Nigbati ẹmi aimọ́ na si gbé e ṣanlẹ, o ke li ohùn rara, o si jade kuro lara rẹ̀. Hà si ṣe gbogbo wọn, tobẹ̃ ti nwọn fi mbi ara wọn lẽre, wipe, Kili eyi? ẹkọ́ titun li eyi? nitoriti o fi agbara paṣẹ fun awọn ẹmi aimọ́, nwọn si gbọ́ tirẹ̀. Lojukanna okikí rẹ̀ si kàn yi gbogbo ẹkùn Galili ká. Nigbati nwọn si jade kuro ninu sinagogu, lojukanna nwọn wọ̀ ile Simoni ati Anderu, pẹlu Jakọbu ati Johanu. Iya aya Simoni si dubulẹ aìsan ibà, nwọn si sọ ọ̀ran rẹ̀ fun u. O si wá, o fà a lọwọ, o si gbé e dide; lojukanna ibà na si fi i silẹ, o si nṣe iranṣẹ fun wọn. Nigbati o di aṣalẹ, ti õrun wọ̀, nwọn gbe gbogbo awọn alaìsan, ati awọn ti o li ẹmi i èṣu tọ̀ ọ wá. Gbogbo ilu si pejọ li ẹnu-ọ̀na. O si wò ọ̀pọ awọn ti o ni onirũru àrun sàn, o si lé ọ̀pọ ẹmi èṣu jade; ko si jẹ ki awọn ẹmi èṣu na ki o fọhun, nitoriti nwọn mọ̀ ọ. O si dide li owurọ̀ ki ilẹ to mọ́, o si jade lọ si ibi iju kan, nibẹ li o si ngbadura. Simoni ati awọn ti o wà pẹlu rẹ̀ si nwá a. Nigbati nwọn si ri i, nwọn wi fun u pe, Gbogbo enia nwá ọ. O si wi fun wọn pe, Ẹ jẹ ki a lọ si ilu miran, ki emi ki o le wasu nibẹ̀ pẹlu: nitori eyi li emi sá ṣe wá. O si nwãsu ninu sinagogu wọn lọ ni gbogbo Galili, o si nlé awọn ẹmi èṣu jade. Ọkunrin kan ti o dẹtẹ si tọ̀ ọ wá, o si kunlẹ niwaju rẹ̀, o si mbẹ̀ ẹ, o si wi fun u pe, Bi iwọ ba fẹ, iwọ le sọ mi di mimọ́. Jesu ṣãnu rẹ̀, o nà ọwọ́ rẹ̀, o fi bà a, o si wi fun u pe, Mo fẹ, iwọ di mimọ́. Bi o si ti sọ̀rọ, lojukanna ẹ̀tẹ na fi i silẹ; o si di mimọ́. O si kìlọ fun u gidigidi, lojukanna o si rán a lọ; O si wi fun u pe, Wo o, máṣe sọ ohunkohun fun ẹnikẹni: ṣugbọn lọ, fi ara rẹ hàn fun alufa, ki o si fi ẹ̀bun iwẹnumọ́ rẹ ti Mose ti palaṣẹ, ni ẹrí fun wọn. Ṣugbọn o jade, o si bẹrẹ si ikokiki, ati si itàn ọ̀ran na kalẹ, tobẹ̃ ti Jesu kò si le wọ̀ ilu ni gbangba mọ́, ṣugbọn o wà lẹhin odi nibi iju: nwọn si tọ̀ ọ wá lati ìha gbogbo wá.
Mak 1:14-45 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn ìgbà tí wọn ju Johanu sinu ẹ̀wọ̀n, Jesu wá sí Galili, ó ń waasu ìyìn rere tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá. Ó ń wí pé, “Àkókò tó; ìjọba Ọlọrun súnmọ́ ìtòsí. Ẹ ronupiwada, kí ẹ gba ìyìn rere gbọ́.” Bí Jesu ti ń rìn lọ lẹ́bàá òkun Galili, ó rí Simoni ati Anderu arakunrin rẹ̀ tí wọn ń da àwọ̀n sinu òkun, nítorí apẹja ni wọ́n. Jesu bá wí fún wọn pé, “Ẹ wá máa tẹ̀lé mi, èmi yóo sọ yín di ẹni tí ó ń fa eniyan bí a ti ń dẹ ẹja ninu omi.” Lẹ́sẹ̀ kan náà wọ́n bá fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n ń tẹ̀lé e. Bí ó ti rìn siwaju díẹ̀ sí i, ó rí Jakọbu ọmọ Sebede ati Johanu arakunrin rẹ̀ ninu ọkọ̀, wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe. Bí Jesu ti rí wọn, ó pè wọ́n. Wọ́n bá fi Sebede baba wọn sílẹ̀ ninu ọkọ̀ pẹlu àwọn alágbàṣe, wọ́n ń tẹ̀lé e. Wọ́n lọ sí Kapanaumu. Ní Ọjọ́ Ìsinmi àwọn Juu, Jesu lọ sí ilé ìpàdé, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn eniyan. Ẹnu ya àwọn tí ó gbọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀, nítorí ó ń kọ́ wọn bí ẹni tí ó ní àṣẹ, yàtọ̀ sí bí àwọn amòfin ṣe ń kọ́ wọn. Ọkunrin kan wà ninu ilé ìpàdé náà tí ó ní ẹ̀mí èṣù. Ó bá kígbe tòò, ó ní, “Kí ni ó pa tàwa-tìrẹ pọ̀, Jesu ará Nasarẹti? Ṣé o dé láti pa wá run ni? Mo mọ ẹni tí o jẹ́. Ẹni Mímọ́ Ọlọrun ni ọ́.” Jesu bá bá a wí, ó ní, “Pa ẹnu mọ́, kí o jáde kúrò ninu ọkunrin yìí.” Ẹ̀mí èṣù náà bá gbo ọkunrin náà jìgìjìgì, ó kígbe tòò, ó sì jáde kúrò ninu ọkunrin náà. Kẹ́kẹ́ bá pamọ́ gbogbo àwọn eniyan lẹ́nu tóbẹ́ẹ̀ tí wọn ń wí láàrin ara wọn pé, “Kí ni èyí? Ẹ̀kọ́ titun ni! Pẹlu àṣẹ ni ó fi bá àwọn ẹ̀mí èṣù wí, wọ́n sì gbọ́ràn sí i lẹ́nu.” Òkìkí Jesu wá kan ká gbogbo ìgbèríko Galili. Bí wọ́n ti jáde kúrò ninu ilé ìpàdé, Jesu pẹlu Jakọbu ati Johanu lọ sí ilé Simoni ati Anderu. Ìyá iyawo Simoni wà ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn ibà. Lẹsẹkẹsẹ wọ́n sọ fún Jesu nípa rẹ̀. Ó bá lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó fà á lọ́wọ́ dìde. Ibà náà sì fi í sílẹ̀, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí tọ́jú oúnjẹ fún wọn. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, tí oòrùn wọ̀, àwọn eniyan bẹ̀rẹ̀ sí gbé gbogbo àwọn tí ara wọn kò dá ati àwọn tí wọ́n ní ẹ̀mí èṣù wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Gbogbo ìlú péjọ sí ẹnu ọ̀nà. Ó ṣe ìwòsàn fún ọpọlọpọ àwọn tí ó ní oríṣìíríṣìí àìsàn, ó tún lé ẹ̀mí èṣù jáde. Kò jẹ́ kí àwọn ẹ̀mí èṣù náà sọ̀rọ̀, nítorí wọ́n mọ ẹni tí ó jẹ́. Ní òwúrọ̀ kutukutu kí ilẹ̀ tó mọ́, Jesu dìde, ó jáde kúrò ní ilé, ó lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú láti gbadura níbi tí kò sí ẹnìkankan. Simoni ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀ bá ń wá a kiri. Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n wí fún un pé, “Gbogbo eniyan ní ń wá ọ.” Ṣugbọn ó wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ sí àwọn abúlé mìíràn tí ó wà ní ìtòsí kí n lè waasu níbẹ̀, nítorí ohun tí mo wá sí ayé fún ni èyí.” Ó bá lọ, ó ń waasu ninu àwọn ilé ìpàdé wọn ní gbogbo ilẹ̀ Galili, ó ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Ẹnìkan tí ó ní àrùn ẹ̀tẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó ń bẹ̀ ẹ́ pé, “Bí o bá fẹ́, o lè sọ ara mi di mímọ́.” Àánú ṣe Jesu ó bá na ọwọ́ ó fi kàn án, ó ní, “Mo fẹ́. Di mímọ́.” Lẹsẹkẹsẹ àrùn ẹ̀tẹ̀ náà bá kúrò lára rẹ̀, ara rẹ̀ sì dá. Jesu fi ohùn líle kìlọ̀ fún un, lẹsẹkẹsẹ ó bá ní kí ó máa lọ. Ó wí fún un pé, “Má wí ohunkohun fún ẹnikẹ́ni. Ṣugbọn lọ fi ara rẹ han alufaa, kí o sì rúbọ ìwòsàn rẹ bí Mose ti pàṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí fún wọn pé ara rẹ ti dá.” Ṣugbọn ọkunrin náà jáde lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún ọpọlọpọ eniyan, ó ń rán ọ̀rọ̀ náà mọ́ ẹnu, tóbẹ́ẹ̀ tí Jesu kò fi lè wọ inú ìlú ní gbangba mọ́, ṣugbọn ó lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú níbi tí kò sí eniyan. Sibẹ àwọn eniyan ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti ibi gbogbo.
Mak 1:14-45 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn ìgbà tí ọba Herodu ti fi Johanu sínú ẹ̀wọ̀n tan, Jesu lọ sí Galili, ó ń wàásù ìhìnrere ti ìjọba Ọlọ́run. Ó sì kéde wí pé, “Àkókò náà dé wàyí, ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀. Ẹ yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ sì gba ìhìnrere yìí gbọ́.” Ní ọjọ́ kan, bí Jesu ti ń rìn létí Òkun Galili, Ó rí Simoni àti Anderu arákùnrin rẹ̀, wọ́n ń fi àwọ̀n wọn pẹja torí pé apẹja ni wọ́n. Jesu sì ké sí wọn wí pé, “Ẹ máa tọ̀ mí lẹ́yìn. Èmi yóò sì sọ yín di apẹja ènìyàn.” Ní kánkán wọ́n fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ Ọ́ lẹ́yìn. Bí Ó sì ti rìn síwájú díẹ̀, ní etí Òkun, Ó rí Jakọbu ọmọ Sebede àti Johanu arákùnrin rẹ̀ nínú ọkọ̀, wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe. Ó sì ké sí àwọn náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n fi Sebede baba wọn sílẹ̀ nínú ọkọ̀ pẹ̀lú àwọn alágbàṣe, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. Lẹ́yìn náà, Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ ìlú Kapernaumu, nígbà tí ó di òwúrọ̀ ọjọ́ ìsinmi, ó lọ sínú Sinagọgu, ó sì ń kọ́ni. Ẹnu sì ya ìjọ ènìyàn nítorí ìkọ́ni rẹ̀, nítorí pé ó ń kọ́ni bí ẹni tí ó ní àṣẹ, kì í ṣe bí àwọn olùkọ́ òfin ṣe ń kọ́ àwọn ènìyàn. Ní àsìkò náà gan an ni ọkùnrin kan tí ó wà nínú Sinagọgu wọn, tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́, bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe wí pé, “Kí ni ìwọ ń wá lọ́dọ̀ wa, Jesu ti Nasareti? Ṣé ìwọ wá láti pa wá run ni? Èmí mọ ẹni tí ìwọ í ṣe; Ìwọ ní ẹni Mímọ́ Ọlọ́run!” Jesu si bá a wí, ó wí pé, “Pa ẹnu rẹ mọ́, kí ó sì jáde kúrò lára rẹ̀.” Ẹ̀mí àìmọ́ náà sì gbé e ṣánlẹ̀ lógèdèǹgbé, ó ké ní ohùn rara, ó sì jáde kúrò lára ọkùnrin náà. Ẹnu sì ya àwọn ènìyàn, tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi ń sọ láàrín ara wọn ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀. Wọ́n béèrè pẹ̀lú ìgbóná ara, pé, “Kí ni èyí? Irú ẹ̀kọ́ tuntun wo ni èyí? Ó ń fi agbára pàṣẹ fún àwọn ẹ̀mí àìmọ́ pàápàá wọ́n sì gbọ́ tirẹ̀.” Ìròyìn nípa rẹ̀ tàn ká gbogbo agbègbè Galili. Nígbà tí wọn sì jáde kúrò nínú Sinagọgu, wọ́n lọ pẹ̀lú Jakọbu àti Johanu sí ilé Simoni àti Anderu. Ìyá ìyàwó Simoni tí ó dùbúlẹ̀ àìsàn ibà, wọ́n sì sọ fún Jesu nípa rẹ̀. Ó sì tọ̀ ọ́ lọ, ó fà á lọ́wọ́, ó sì gbé e dìde; lójúkan náà ibà náà fi sílẹ̀, ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún wọn. Nígbà tí ó di àṣálẹ́, tí oòrùn wọ̀, wọ́n gbé gbogbo àwọn aláìsàn àti àwọn tó ni ẹ̀mí àìmọ́ tọ̀ ọ́ wá. Gbogbo ìlú si péjọ ni ẹnu-ọ̀nà. Jesu sì wo ọ̀pọ̀ tí wọ́n ní onírúurú ààrùn sàn. Bákan náà ni ó lé ọ̀pọ̀ ẹ̀mí àìmọ́ jáde, Ṣùgbọ́n kò sì jẹ́ kí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà kí ó sọ̀rọ̀, nítorí tí wọ́n mọ ẹni tí òun í ṣe. Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, kí ilẹ̀ tó mọ́, Jesu nìkan jáde lọ sí aginjù kan, láti lọ gbàdúrà. Simoni àti àwọn ènìyàn rẹ̀ yòókù lọ láti wá a. Nígbà tí wọ́n sì rí I, wọ́n sọ fún wí pé, “Gbogbo ènìyàn ń wá ọ!” Jesu sì dáhùn wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a lọ sí àwọn ìlú mìíràn, kí ń lè wàásù níbẹ̀ pẹ̀lú. Nítorí èyí ni èmi sá à ṣe wá.” Nítorí náà, ó ń kiri gbogbo agbègbè Galili, ó ń wàásù nínú Sinagọgu. Ó sì ń lé àwọn ẹ̀mí àìmọ́ jáde. Ọkùnrin adẹ́tẹ̀ kan tọ̀ ọ́ wá, ó sì kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀. Ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ìmúláradá. Ó wí pé, “Bí ìwọ bá fẹ́, ìwọ lè mú mi láradá.” Jesu kún fún àánú, ó na ọwọ́ rẹ̀, ó fi ọwọ́ rẹ̀ bà a, ó wí pé, “Èmí fẹ́. Di mímọ́.” Lójúkan náà ẹ̀tẹ̀ náà fi sílẹ̀ lọ, ọkùnrin náà sì rí ìwòsàn. Jesu sì kìlọ̀ fún un gidigidi Ó wí pé, “Lọ fi ara rẹ̀ hàn àlùfáà Júù fún àyẹ̀wò. Ṣùgbọ́n má ṣe dúró sọ ohunkóhun fún ẹnikẹ́ni ní ọ̀nà. Mú ẹ̀bùn lọ́wọ́, èyí tí Mose pàṣẹ fún adẹ́tẹ̀ tí a mú láradá. Èyí tí í ṣe ẹ̀rí pé, ó ti rí ìwòsàn.” Ṣùgbọ́n ó jáde lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí í pòkìkí, ó ń tan ìròyìn kálẹ̀. Nítorí èyí, Jesu kò sì le wọ ìlú ní gbangba mọ́, ṣùgbọ́n ó wà lẹ́yìn odi ìlú ní aginjù. Síbẹ̀, àwọn ènìyàn tọ̀ ọ́ wá láti ibi gbogbo.