Mak 1:12-20
Mak 1:12-20 Bibeli Mimọ (YBCV)
Loju kan náà Ẹmí si dari rẹ̀ si ijù. O si wà ni ogoji ọjọ ni ijù, a ti ọwọ́ Satani dán an wò, o si wà pẹlu awọn ẹranko igbẹ́; awọn angẹli si nṣe iranṣẹ fun u. Lẹhin igbati a fi Johanu sinu tubu tan, Jesu lọ si Galili, o nwasu ihinrere ijọba Ọlọrun, O si nwipe, Akokò na de, ijọba Ọlọrun si kù si dẹ̀dẹ: ẹ ronupiwada, ki ẹ si gbà ihinrere gbọ́. Bi o si ti nrìn leti okun Galili, o ri Simoni ati Anderu arakunrin rẹ̀, nwọn nsọ àwọn sinu okun: nitoriti nwọn ṣe apẹja. Jesu si wi fun wọn pe, Ẹ mã tọ̀ mi lẹhin, emi o si sọ nyin di apẹja enia. Lojukanna nwọn si fi àwọn wọn silẹ, nwọn si tọ̀ ọ lẹhin. Bi o si ti lọ siwaju diẹ, o ri Jakọbu ọmọ Sebede, ati Johanu arakunrin rẹ̀, nwọn wà ninu ọkọ̀, nwọn ndí àwọn wọn. Lojukanna o si pè wọn: nwọn si fi Sebede baba wọn silẹ ninu ọkọ̀ pẹlu awọn alagbaṣe, nwọn si tọ̀ ọ lẹhin.

Mak 1:12-20 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn èyí, Ẹ̀mí Ọlọrun gbé Jesu lọ sinu aṣálẹ̀. Ó wà níbẹ̀ fún ogoji ọjọ́ tí Satani ń dán an wò. Ààrin àwọn ẹranko ni ó wà, ṣugbọn àwọn angẹli ń ṣe iranṣẹ fún un. Lẹ́yìn ìgbà tí wọn ju Johanu sinu ẹ̀wọ̀n, Jesu wá sí Galili, ó ń waasu ìyìn rere tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá. Ó ń wí pé, “Àkókò tó; ìjọba Ọlọrun súnmọ́ ìtòsí. Ẹ ronupiwada, kí ẹ gba ìyìn rere gbọ́.” Bí Jesu ti ń rìn lọ lẹ́bàá òkun Galili, ó rí Simoni ati Anderu arakunrin rẹ̀ tí wọn ń da àwọ̀n sinu òkun, nítorí apẹja ni wọ́n. Jesu bá wí fún wọn pé, “Ẹ wá máa tẹ̀lé mi, èmi yóo sọ yín di ẹni tí ó ń fa eniyan bí a ti ń dẹ ẹja ninu omi.” Lẹ́sẹ̀ kan náà wọ́n bá fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n ń tẹ̀lé e. Bí ó ti rìn siwaju díẹ̀ sí i, ó rí Jakọbu ọmọ Sebede ati Johanu arakunrin rẹ̀ ninu ọkọ̀, wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe. Bí Jesu ti rí wọn, ó pè wọ́n. Wọ́n bá fi Sebede baba wọn sílẹ̀ ninu ọkọ̀ pẹlu àwọn alágbàṣe, wọ́n ń tẹ̀lé e.
Mak 1:12-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́sẹ̀kan náà, Ẹ̀mí Mímọ́ sì darí Jesu sí ijù, Ó sì wà ní ogójì ọjọ́ ní aginjù. A sì ti ọwọ́ Satani dán an wò, ó sì wà pẹ̀lú àwọn ẹranko ìgbẹ́. Àwọn angẹli sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún un. Lẹ́yìn ìgbà tí ọba Herodu ti fi Johanu sínú ẹ̀wọ̀n tan, Jesu lọ sí Galili, ó ń wàásù ìhìnrere ti ìjọba Ọlọ́run. Ó sì kéde wí pé, “Àkókò náà dé wàyí, ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀. Ẹ yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ sì gba ìhìnrere yìí gbọ́.” Ní ọjọ́ kan, bí Jesu ti ń rìn létí Òkun Galili, Ó rí Simoni àti Anderu arákùnrin rẹ̀, wọ́n ń fi àwọ̀n wọn pẹja torí pé apẹja ni wọ́n. Jesu sì ké sí wọn wí pé, “Ẹ máa tọ̀ mí lẹ́yìn. Èmi yóò sì sọ yín di apẹja ènìyàn.” Ní kánkán wọ́n fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ Ọ́ lẹ́yìn. Bí Ó sì ti rìn síwájú díẹ̀, ní etí Òkun, Ó rí Jakọbu ọmọ Sebede àti Johanu arákùnrin rẹ̀ nínú ọkọ̀, wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe. Ó sì ké sí àwọn náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n fi Sebede baba wọn sílẹ̀ nínú ọkọ̀ pẹ̀lú àwọn alágbàṣe, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.