Mak 1:1-8
Mak 1:1-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
IBẸRẸ ihinrere Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọrun. Bi a ti kọ ọ ninu iwe woli Isaiah: Kiyesi i, mo rán onṣẹ mi ṣiwaju rẹ, ẹniti yio tún ọ̀na rẹ ṣe niwaju rẹ. Ohùn ẹnikan ti nkigbe ni ijù, Ẹ tún ọ̀na Oluwa ṣe, ẹ ṣe oju ọ̀na rẹ̀ tọ́. Johanu de, ẹniti o mbaptisi ni iju, ti o si nwasu baptismu ironupiwada fun idariji ẹ̀ṣẹ. Gbogbo ilẹ Judea, ati gbogbo awọn ará Jerusalemu jade tọ̀ ọ lọ, a si ti ọwọ́ rẹ̀ baptisi gbogbo wọn li odò Jordani, nwọn njẹwọ ẹ̀ṣẹ wọn. Johanu si wọ̀ aṣọ irun ibakasiẹ, o si dì amure awọ mọ ẹgbẹ rẹ̀; o si njẹ ẽṣú ati oyin ìgan. O si nwasu, wipe, Ẹnikan ti o pọ̀ju mi lọ mbọ̀ lẹhin mi, okùn bata ẹsẹ ẹniti emi ko to bẹ̀rẹ tú: Emi fi omi baptisi nyin; ṣugbọn on yio fi Ẹmí Mimọ́ baptisi nyin.
Mak 1:1-8 Yoruba Bible (YCE)
Bí ìyìn rere Jesu Kristi Ọmọ Ọlọrun ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyí: Gẹ́gẹ́ bí wolii Aisaya ti kọ ọ́ tẹ́lẹ̀ ni ó rí: “Ọlọrun ní, ‘Wò ó! Mo rán oníṣẹ́ mi ṣiwaju rẹ òun ni yóo palẹ̀ mọ́ dè ọ́.’ Ohùn ẹni tí ń kígbe ninu aṣálẹ̀ pé, ‘Ẹ la ọ̀nà tí Oluwa yóo gbà, ẹ ṣe é kí ó tọ́ fún un láti rìn.’ ” Báyìí ni Johanu bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìrìbọmi ninu aṣálẹ̀, tí ó ń waasu pé kí àwọn eniyan ronupiwada, kí wọ́n ṣe ìrìbọmi, kí Ọlọrun lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wọ́n. Gbogbo eniyan ilẹ̀ Judia ati ti ìlú Jerusalẹmu jáde tọ̀ ọ́ lọ, wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ó sì ń ṣe ìrìbọmi fún wọn ninu odò Jọdani. Irun ràkúnmí ni wọ́n fi hun aṣọ tí Johanu wọ̀, ọ̀já ìgbànú aláwọ ni ó gbà mọ́ ìdí, eṣú ni ó ń jẹ, ó sì ń lá oyin ìgàn. Ó ń waasu pé, “Ẹnìkan tí ó jù mí lọ ń bọ̀ lẹ́yìn mi, n kò tó bẹ̀rẹ̀ láti tú okùn bàtà rẹ̀. Ìrìbọmi ni èmi ń ṣe fun yín ṣugbọn òun yóo fi Ẹ̀mí Mímọ́ wẹ̀ yín mọ́.”
Mak 1:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìbẹ̀rẹ̀ ìhìnrere nípa Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọ́run. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé wòlíì Isaiah pé: “Èmi yóò ran oníṣẹ́ mi síwájú rẹ, Ẹni tí yóò tún ọ̀nà rẹ ṣe.” “Ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù, ‘Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe, ẹ ṣe ojú ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.’ ” Johanu dé, ẹni tí ó ń tẹnibọmi ní aginjù, tí ó sì ń wàásù ìtẹ̀bọmi ìrònúpìwàdà fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀. Gbogbo àwọn tí ń gbé ní agbègbè Judea, àti gbogbo ènìyàn Jerusalẹmu jáde tọ̀ ọ́ lọ, a sì ti ọwọ́ rẹ̀ tẹ gbogbo wọn bọ omi ni odò Jordani, wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Johanu sì wọ aṣọ irun ìbákasẹ. Ó sì di àmùrè awọ mọ́ ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Eṣú àti oyin ìgàn sì ni oúnjẹ rẹ̀. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù wí pé, “Ẹnìkan tí ó tóbi jù mí lọ ń bọ̀ lẹ́yìn mi, okùn bàtà ẹsẹ̀ ẹni tí èmi kò tó ẹni tí ń tú. Èmi ń fi omi ṣe ìtẹ̀bọmi yín, ṣùgbọ́n Òun yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe ìtẹ̀bọmi yín.”