Mak 1:1-20

Mak 1:1-20 Bibeli Mimọ (YBCV)

IBẸRẸ ihinrere Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọrun. Bi a ti kọ ọ ninu iwe woli Isaiah: Kiyesi i, mo rán onṣẹ mi ṣiwaju rẹ, ẹniti yio tún ọ̀na rẹ ṣe niwaju rẹ. Ohùn ẹnikan ti nkigbe ni ijù, Ẹ tún ọ̀na Oluwa ṣe, ẹ ṣe oju ọ̀na rẹ̀ tọ́. Johanu de, ẹniti o mbaptisi ni iju, ti o si nwasu baptismu ironupiwada fun idariji ẹ̀ṣẹ. Gbogbo ilẹ Judea, ati gbogbo awọn ará Jerusalemu jade tọ̀ ọ lọ, a si ti ọwọ́ rẹ̀ baptisi gbogbo wọn li odò Jordani, nwọn njẹwọ ẹ̀ṣẹ wọn. Johanu si wọ̀ aṣọ irun ibakasiẹ, o si dì amure awọ mọ ẹgbẹ rẹ̀; o si njẹ ẽṣú ati oyin ìgan. O si nwasu, wipe, Ẹnikan ti o pọ̀ju mi lọ mbọ̀ lẹhin mi, okùn bata ẹsẹ ẹniti emi ko to bẹ̀rẹ tú: Emi fi omi baptisi nyin; ṣugbọn on yio fi Ẹmí Mimọ́ baptisi nyin. O si ṣe li ọjọ wọnni, Jesu jade wá lati Nasareti ti Galili, a si ti ọwọ́ Johanu baptisi rẹ̀ li odò Jordani. Lojukanna bi o si ti goke lati inu omi wá, o ri ọrun pinya, Ẹmi nsọkalẹ bi àdaba le e lori: Ohùn kan si ti ọrun wá, wipe, Iwọ ni ayanfẹ Ọmọ mi, ẹniti inu mi dùn si gidigidi. Loju kan náà Ẹmí si dari rẹ̀ si ijù. O si wà ni ogoji ọjọ ni ijù, a ti ọwọ́ Satani dán an wò, o si wà pẹlu awọn ẹranko igbẹ́; awọn angẹli si nṣe iranṣẹ fun u. Lẹhin igbati a fi Johanu sinu tubu tan, Jesu lọ si Galili, o nwasu ihinrere ijọba Ọlọrun, O si nwipe, Akokò na de, ijọba Ọlọrun si kù si dẹ̀dẹ: ẹ ronupiwada, ki ẹ si gbà ihinrere gbọ́. Bi o si ti nrìn leti okun Galili, o ri Simoni ati Anderu arakunrin rẹ̀, nwọn nsọ àwọn sinu okun: nitoriti nwọn ṣe apẹja. Jesu si wi fun wọn pe, Ẹ mã tọ̀ mi lẹhin, emi o si sọ nyin di apẹja enia. Lojukanna nwọn si fi àwọn wọn silẹ, nwọn si tọ̀ ọ lẹhin. Bi o si ti lọ siwaju diẹ, o ri Jakọbu ọmọ Sebede, ati Johanu arakunrin rẹ̀, nwọn wà ninu ọkọ̀, nwọn ndí àwọn wọn. Lojukanna o si pè wọn: nwọn si fi Sebede baba wọn silẹ ninu ọkọ̀ pẹlu awọn alagbaṣe, nwọn si tọ̀ ọ lẹhin.

Mak 1:1-20 Yoruba Bible (YCE)

Bí ìyìn rere Jesu Kristi Ọmọ Ọlọrun ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyí: Gẹ́gẹ́ bí wolii Aisaya ti kọ ọ́ tẹ́lẹ̀ ni ó rí: “Ọlọrun ní, ‘Wò ó! Mo rán oníṣẹ́ mi ṣiwaju rẹ òun ni yóo palẹ̀ mọ́ dè ọ́.’ Ohùn ẹni tí ń kígbe ninu aṣálẹ̀ pé, ‘Ẹ la ọ̀nà tí Oluwa yóo gbà, ẹ ṣe é kí ó tọ́ fún un láti rìn.’ ” Báyìí ni Johanu bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìrìbọmi ninu aṣálẹ̀, tí ó ń waasu pé kí àwọn eniyan ronupiwada, kí wọ́n ṣe ìrìbọmi, kí Ọlọrun lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wọ́n. Gbogbo eniyan ilẹ̀ Judia ati ti ìlú Jerusalẹmu jáde tọ̀ ọ́ lọ, wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ó sì ń ṣe ìrìbọmi fún wọn ninu odò Jọdani. Irun ràkúnmí ni wọ́n fi hun aṣọ tí Johanu wọ̀, ọ̀já ìgbànú aláwọ ni ó gbà mọ́ ìdí, eṣú ni ó ń jẹ, ó sì ń lá oyin ìgàn. Ó ń waasu pé, “Ẹnìkan tí ó jù mí lọ ń bọ̀ lẹ́yìn mi, n kò tó bẹ̀rẹ̀ láti tú okùn bàtà rẹ̀. Ìrìbọmi ni èmi ń ṣe fun yín ṣugbọn òun yóo fi Ẹ̀mí Mímọ́ wẹ̀ yín mọ́.” Ní ọjọ́ kan, Jesu wá láti Nasarẹti ìlú kan ní Galili, Johanu bá ṣe ìrìbọmi fún un ninu odò Jọdani. Bí Jesu ti ń jáde kúrò ninu omi, lẹ́sẹ̀ kan náà ó rí Ẹ̀mí Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí àdàbà tí ó bà lé e. Ó sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run tí ó wí pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ ọmọ mi, inú mi dùn sí ọ gidigidi.” Lẹ́yìn èyí, Ẹ̀mí Ọlọrun gbé Jesu lọ sinu aṣálẹ̀. Ó wà níbẹ̀ fún ogoji ọjọ́ tí Satani ń dán an wò. Ààrin àwọn ẹranko ni ó wà, ṣugbọn àwọn angẹli ń ṣe iranṣẹ fún un. Lẹ́yìn ìgbà tí wọn ju Johanu sinu ẹ̀wọ̀n, Jesu wá sí Galili, ó ń waasu ìyìn rere tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá. Ó ń wí pé, “Àkókò tó; ìjọba Ọlọrun súnmọ́ ìtòsí. Ẹ ronupiwada, kí ẹ gba ìyìn rere gbọ́.” Bí Jesu ti ń rìn lọ lẹ́bàá òkun Galili, ó rí Simoni ati Anderu arakunrin rẹ̀ tí wọn ń da àwọ̀n sinu òkun, nítorí apẹja ni wọ́n. Jesu bá wí fún wọn pé, “Ẹ wá máa tẹ̀lé mi, èmi yóo sọ yín di ẹni tí ó ń fa eniyan bí a ti ń dẹ ẹja ninu omi.” Lẹ́sẹ̀ kan náà wọ́n bá fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n ń tẹ̀lé e. Bí ó ti rìn siwaju díẹ̀ sí i, ó rí Jakọbu ọmọ Sebede ati Johanu arakunrin rẹ̀ ninu ọkọ̀, wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe. Bí Jesu ti rí wọn, ó pè wọ́n. Wọ́n bá fi Sebede baba wọn sílẹ̀ ninu ọkọ̀ pẹlu àwọn alágbàṣe, wọ́n ń tẹ̀lé e.

Mak 1:1-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ìbẹ̀rẹ̀ ìhìnrere nípa Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọ́run. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé wòlíì Isaiah pé: “Èmi yóò ran oníṣẹ́ mi síwájú rẹ, Ẹni tí yóò tún ọ̀nà rẹ ṣe.” “Ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù, ‘Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe, ẹ ṣe ojú ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.’ ” Johanu dé, ẹni tí ó ń tẹnibọmi ní aginjù, tí ó sì ń wàásù ìtẹ̀bọmi ìrònúpìwàdà fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀. Gbogbo àwọn tí ń gbé ní agbègbè Judea, àti gbogbo ènìyàn Jerusalẹmu jáde tọ̀ ọ́ lọ, a sì ti ọwọ́ rẹ̀ tẹ gbogbo wọn bọ omi ni odò Jordani, wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Johanu sì wọ aṣọ irun ìbákasẹ. Ó sì di àmùrè awọ mọ́ ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Eṣú àti oyin ìgàn sì ni oúnjẹ rẹ̀. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù wí pé, “Ẹnìkan tí ó tóbi jù mí lọ ń bọ̀ lẹ́yìn mi, okùn bàtà ẹsẹ̀ ẹni tí èmi kò tó ẹni tí ń tú. Èmi ń fi omi ṣe ìtẹ̀bọmi yín, ṣùgbọ́n Òun yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe ìtẹ̀bọmi yín.” Ó sì ṣe ní ọjọ́ kan Jesu ti Nasareti ti Galili jáde wá, a sì ti ọwọ́ Johanu ṣe ìtẹ̀bọmi fún ní odò Jordani. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí Jesu ń ti inú omi jáde wá, ó rí ọ̀run tí ó ṣí sílẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ bí àdàbà sọ̀kalẹ̀ lé e lórí. Ohùn kan sì ti ọ̀run wá wí pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ Ọmọ mi, ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.” Lẹ́sẹ̀kan náà, Ẹ̀mí Mímọ́ sì darí Jesu sí ijù, Ó sì wà ní ogójì ọjọ́ ní aginjù. A sì ti ọwọ́ Satani dán an wò, ó sì wà pẹ̀lú àwọn ẹranko ìgbẹ́. Àwọn angẹli sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún un. Lẹ́yìn ìgbà tí ọba Herodu ti fi Johanu sínú ẹ̀wọ̀n tan, Jesu lọ sí Galili, ó ń wàásù ìhìnrere ti ìjọba Ọlọ́run. Ó sì kéde wí pé, “Àkókò náà dé wàyí, ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀. Ẹ yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ sì gba ìhìnrere yìí gbọ́.” Ní ọjọ́ kan, bí Jesu ti ń rìn létí Òkun Galili, Ó rí Simoni àti Anderu arákùnrin rẹ̀, wọ́n ń fi àwọ̀n wọn pẹja torí pé apẹja ni wọ́n. Jesu sì ké sí wọn wí pé, “Ẹ máa tọ̀ mí lẹ́yìn. Èmi yóò sì sọ yín di apẹja ènìyàn.” Ní kánkán wọ́n fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ Ọ́ lẹ́yìn. Bí Ó sì ti rìn síwájú díẹ̀, ní etí Òkun, Ó rí Jakọbu ọmọ Sebede àti Johanu arákùnrin rẹ̀ nínú ọkọ̀, wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe. Ó sì ké sí àwọn náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n fi Sebede baba wọn sílẹ̀ nínú ọkọ̀ pẹ̀lú àwọn alágbàṣe, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.