Mat 9:27-31
Mat 9:27-31 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati Jesu si jade nibẹ̀, awọn ọkunrin afọju meji tọ̀ ọ lẹhin, nwọn kigbe soke wipe, Iwọ ọmọ Dafidi, ṣãnu fun wa. Nigbati o si wọ̀ ile, awọn afọju na tọ̀ ọ wá: Jesu bi wọn pe, Ẹnyin gbagbọ́ pe mo le ṣe eyi? Nwọn wi fun u pe, Iwọ le ṣe e, Oluwa. Nigbana li o fi ọwọ́ bà wọn li oju, o wipe, Ki o ri fun nyin, gẹgẹ bi igbagbọ́ nyin. Oju wọn si là; Jesu si kìlọ fun wọn gidigidi, wipe, Kiyesi i, ki ẹ máṣe jẹ ki ẹnikan ki o mọ̀. Ṣugbọn nigbati nwọn lọ, nwọn ròhin rẹ̀ yi gbogbo ilu na ká.
Mat 9:27-31 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Jesu kúrò níbẹ̀, àwọn afọ́jú meji kan tẹ̀lé e, wọ́n ń kígbe pé, “Ọmọ Dafidi, ṣàánú wa.” Nígbà tí ó wọ inú ilé, àwọn afọ́jú náà tọ̀ ọ́ lọ. Jesu bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ẹ gbàgbọ́ pé mo lè wò yín sàn?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Oluwa.” Ó bá fi ọwọ́ kàn wọ́n lójú, ó ní, “Kí ó rí fun yín gẹ́gẹ́ bí igbagbọ yín.” Ojú wọn bá là. Jesu wá kìlọ̀ fún wọn gidigidi, ó ní “Ẹ má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀.” Ṣugbọn nígbà tí wọ́n jáde, ńṣe ni wọ́n ń pòkìkí rẹ̀ káàkiri gbogbo agbègbè náà.
Mat 9:27-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí Jesu sì jáde níbẹ̀, àwọn ọkùnrin afọ́jú méjì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, wọ́n ń kígbe sókè wí pé, “Ṣàánú fún wa, ìwọ ọmọ Dafidi.” Nígbà tí ó sì wọ̀ ilé, àwọn afọ́jú náà tọ̀ ọ́ wá, Jesu bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin gbàgbọ́ pé mo le ṣe èyí?” Wọn sì wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa, ìwọ lè ṣe é.” Ó sì fi ọwọ́ bà wọ́n ní ojú, ó wí pé, “Kí ó rí fún yín gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ yín.” Ojú wọn sì là; Jesu sì kìlọ̀ fún wọn gidigidi, wí pé, “Kíyèsi i, kí ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan kí ó mọ̀ nípa èyí.” Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n lọ, wọ́n ròyìn rẹ̀ yí gbogbo ìlú náà ká.