Mat 9:18-38

Mat 9:18-38 Bibeli Mimọ (YBCV)

Bi o ti nsọ nkan wọnyi fun wọn, kiyesi i, ijoye kan tọ̀ ọ wá, o si tẹriba fun u, wipe, Ọmọbinrin mi kú nisisiyi, ṣugbọn wá fi ọwọ́ rẹ le e, on ó si yè. Jesu dide, o si ba a lọ, ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀. Si kiyesi i, obinrin kan ti o ni isun ẹ̀jẹ li ọdún mejila, o wá lẹhin rẹ̀, o fi ọwọ́ kàn iṣẹti aṣọ rẹ̀. Nitori o wi ninu ara rẹ̀ pe, Bi mo ba sá le fi ọwọ́ kàn aṣọ rẹ̀, ara mi ó da. Nigbati Jesu si yi ara rẹ̀ pada ti o ri i, o wipe, Ọmọbinrin, tújuka, igbagbọ́ rẹ mu ọ larada. A si mu obinrin na larada ni wakati kanna. Nigbati Jesu si de ile ijoye na, o ba awọn afunfere ati ọ̀pọ enia npariwo. O wi fun wọn pe, Bìla; nitori ọmọbinrin na ko kú, sisùn li o sùn. Nwọn si fi rín ẹrin ẹlẹyà. Ṣugbọn nigbati a si ṣe ti awọn enia jade, o bọ sile, o si fà ọmọbinrin na li ọwọ́ soke; bẹ̃li ọmọbinrin na si dide. Okikí si kàn ká gbogbo ilẹ nã. Nigbati Jesu si jade nibẹ̀, awọn ọkunrin afọju meji tọ̀ ọ lẹhin, nwọn kigbe soke wipe, Iwọ ọmọ Dafidi, ṣãnu fun wa. Nigbati o si wọ̀ ile, awọn afọju na tọ̀ ọ wá: Jesu bi wọn pe, Ẹnyin gbagbọ́ pe mo le ṣe eyi? Nwọn wi fun u pe, Iwọ le ṣe e, Oluwa. Nigbana li o fi ọwọ́ bà wọn li oju, o wipe, Ki o ri fun nyin, gẹgẹ bi igbagbọ́ nyin. Oju wọn si là; Jesu si kìlọ fun wọn gidigidi, wipe, Kiyesi i, ki ẹ máṣe jẹ ki ẹnikan ki o mọ̀. Ṣugbọn nigbati nwọn lọ, nwọn ròhin rẹ̀ yi gbogbo ilu na ká. Bi nwọn ti njade lọ, wò o, nwọn mu ọkunrin odi kan tọ̀ ọ wá, ti o li ẹmi èṣu. Nigbati a lé ẹmi èṣu na jade, odi si fọhùn; ẹnu si yà awọn enia, nwọn wipe, A ko ri irú eyi ri ni Israeli. Ṣugbọn awọn Farisi wipe, agbara olori awọn ẹmi èṣu li o fi lé awọn ẹmi èṣu jade. Jesu si rìn si gbogbo ilu-nla ati iletò, o nkọni ninu sinagogu wọn, o si nwãsu ihinrere ijọba, o si nṣe iwòsan arun ati gbogbo àisan li ara awọn enia. Ṣugbọn nigbati o ri ọ̀pọ enia, ãnu wọn ṣe e, nitoriti ãrẹ̀ mu wọn, nwọn, si tuká kiri bi awọn agutan ti ko li oluṣọ. Nigbana li o wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Lõtọ ni ikorè pọ̀, ṣugbọn awọn alagbaṣe ko to nkan; Nitorina ẹ gbadura si Oluwa ikorè ki o le rán awọn alagbaṣe sinu ikorè rẹ̀.

Mat 9:18-38 Yoruba Bible (YCE)

Bí Jesu tí ń sọ ọ̀rọ̀ yìí fún wọn, ìjòyè kan wá, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó ní, “Ọmọdebinrin mi ṣẹ̀ṣẹ̀ kú nisinsinyii ni, ṣugbọn wá gbé ọwọ́ rẹ lé e, yóo sì yè.” Jesu bá dìde. Ó ń tẹ̀lé e lọ pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Obinrin kan wà, tí nǹkan oṣù rẹ̀ kò tètè dá rí fún ọdún mejila, ó gba ẹ̀yìn wá, ó fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ Jesu; nítorí ó ń sọ ninu ọkàn rẹ̀ pé, “Bí mo bá sá ti lè fi ọwọ́ kan etí aṣọ rẹ̀, ara mi yóo dá.” Jesu bá yipada, ó rí obinrin náà, ó ní, “Ṣe ara gírí, ọmọbinrin. Igbagbọ rẹ ti mú ọ lára dá.” Ara obinrin náà bá dá láti àkókò náà lọ. Nígbà tí Jesu dé ilé ìjòyè náà, ó rí àwọn tí wọn ń fun fèrè ati ọ̀pọ̀ eniyan tí wọn ń ké. Ó ní, “Ẹ sún sẹ́yìn, nítorí ọmọde náà kò kú, ó ń sùn ni.” Wọ́n bá ń fi í ṣe ẹlẹ́yà. Lẹ́yìn tí ó ti lé àwọn eniyan jáde, ó wọ inú ilé, ó mú ọmọbinrin náà lọ́wọ́, ọmọbinrin náà bá dìde. Òkìkí rẹ̀ kàn ká gbogbo agbègbè náà. Nígbà tí Jesu kúrò níbẹ̀, àwọn afọ́jú meji kan tẹ̀lé e, wọ́n ń kígbe pé, “Ọmọ Dafidi, ṣàánú wa.” Nígbà tí ó wọ inú ilé, àwọn afọ́jú náà tọ̀ ọ́ lọ. Jesu bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ẹ gbàgbọ́ pé mo lè wò yín sàn?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Oluwa.” Ó bá fi ọwọ́ kàn wọ́n lójú, ó ní, “Kí ó rí fun yín gẹ́gẹ́ bí igbagbọ yín.” Ojú wọn bá là. Jesu wá kìlọ̀ fún wọn gidigidi, ó ní “Ẹ má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀.” Ṣugbọn nígbà tí wọ́n jáde, ńṣe ni wọ́n ń pòkìkí rẹ̀ káàkiri gbogbo agbègbè náà. Bí àwọn afọ́jú náà ti jáde, bẹ́ẹ̀ ni àwọn kan mú ọkunrin kan, tí ẹ̀mí èṣù mú kí ó yadi, wá sọ́dọ̀ Jesu. Ṣugbọn bí ó ti lé ẹ̀mí èṣù náà jáde ni odi náà bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀. Ẹnu ya gbogbo àwọn eniyan, wọ́n ń sọ pé, “A kò rí irú èyí rí ní Israẹli.” Ṣugbọn àwọn Farisi ń sọ pé, “Agbára olórí àwọn ẹ̀mí èṣù ni ó fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.” Jesu ń rìn kiri ní gbogbo àwọn ìlú ati àwọn ìletò, ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu àwọn ilé ìpàdé, ó ń waasu ìyìn rere ìjọba Ọlọrun, ó sì ń wo oríṣìíríṣìí àrùn ati àìlera sàn. Nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ eniyan náà, àánú wọn ṣe é nítorí wọ́n dàbí aguntan tí kò ní olùṣọ́, tí ọkàn wọn dààmú, tí ó sì rẹ̀wẹ̀sì. Ó bá sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Àwọn ohun tí ó tó kórè pọ̀, ninu oko, ṣugbọn àwọn òṣìṣẹ́ kò pọ̀. Nítorí náà ẹ bẹ Oluwa ìkórè kí ó rán àwọn òṣìṣẹ́ sí ibi ìkórè rẹ̀.”

Mat 9:18-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí fún wọn, kíyèsi i, ìjòyè kan tọ̀ ọ́ wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀ wí pé, “Ọmọbìnrin mi kú nísinsin yìí, ṣùgbọ́n wá fi ọwọ́ rẹ̀ lé e, òun yóò sì yè.” Jesu dìde ó sì bá a lọ àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Sì kíyèsi i, obìnrin kan ti ó ní ìsun ẹ̀jẹ̀ ní ọdún méjìlá, ó wá lẹ́yìn rẹ̀, ó fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀. Nítorí ó wí nínú ara rẹ̀ pé, “Bí mo bá sá à le fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀, ara mi yóò dá.” Nígbà tí Jesu sì yí ara rẹ̀ padà tí ó rí i, ó wí pé, “Ọmọbìnrin, tújúká, ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradà.” A sì mú obìnrin náà láradá ni wákàtí kan náà. Nígbà tí Jesu sí i dé ilé ìjòyè náà, ó bá àwọn afunfèrè àti ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó ń pariwo. Ó wí fún wọn pé, “Ẹ máa lọ; nítorí ọmọbìnrin náà kò kú, sísùn ni ó sùn.” Wọ́n sì fi i rín ẹ̀rín ẹlẹ́yà. Ṣùgbọ́n nígbà tí a ti àwọn ènìyàn jáde, ó wọ ilé, ó sì fà ọmọbìnrin náà ní ọwọ́ sókè; bẹ́ẹ̀ ni ọmọbìnrin náà sì dìde. Òkìkí èyí sì kàn ká gbogbo ilẹ̀ náà. Nígbà tí Jesu sì jáde níbẹ̀, àwọn ọkùnrin afọ́jú méjì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, wọ́n ń kígbe sókè wí pé, “Ṣàánú fún wa, ìwọ ọmọ Dafidi.” Nígbà tí ó sì wọ̀ ilé, àwọn afọ́jú náà tọ̀ ọ́ wá, Jesu bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin gbàgbọ́ pé mo le ṣe èyí?” Wọn sì wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa, ìwọ lè ṣe é.” Ó sì fi ọwọ́ bà wọ́n ní ojú, ó wí pé, “Kí ó rí fún yín gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ yín.” Ojú wọn sì là; Jesu sì kìlọ̀ fún wọn gidigidi, wí pé, “Kíyèsi i, kí ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan kí ó mọ̀ nípa èyí.” Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n lọ, wọ́n ròyìn rẹ̀ yí gbogbo ìlú náà ká. Bí wọ́n tí ń jáde lọ, wò ó wọ́n mú ọkùnrin odi kan tí ó ní ẹ̀mí èṣù tọ Jesu wá. Nígbà tí a lé ẹ̀mí èṣù náà jáde, ọkùnrin tí ó ya odi sì fọhùn. Ẹnu sì ya àwọn ènìyàn, wọ́n wí pé, “A kò rí irú èyí rí ní Israẹli.” Ṣùgbọ́n àwọn Farisi wí pé, “Agbára olórí àwọn ẹ̀mí èṣù ni ó fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.” Jesu sì rìn yí gbogbo ìlú ńlá àti ìletò ká, ó ń kọ́ni nínú Sinagọgu wọn, ó sì ń wàásù ìhìnrere ìjọba ọrun, ó sì ń ṣe ìwòsàn ààrùn àti gbogbo àìsàn ní ara àwọn ènìyàn. Nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ ènìyàn, àánú wọn ṣe é, nítorí àárẹ̀ mú wọn, wọn kò sì rí ìrànlọ́wọ́, bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́. Nígbà náà ni ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Lóòótọ́ ni ìkórè pọ̀ ṣùgbọ́n àwọn alágbàṣe kò tó nǹkan Nítorí náà, ẹ gbàdúrà sí Olúwa ìkórè kí ó rán àwọn alágbàṣe sínú ìkórè rẹ̀.”

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa