Mat 8:16-17
Mat 8:16-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati o si di aṣalẹ, nwọn gbe ọ̀pọlọpọ awọn ẹniti o ni ẹmi èṣu wá sọdọ rẹ̀: o si fi ọ̀rọ rẹ̀ lé awọn ẹmi na jade, o si mu awọn olokunrun larada: Ki eyi ti a ti sọ lati ẹnu woli Isaiah wá le ṣẹ, pe, On tikararẹ̀ gbà ailera wa, o si nrù àrun wa.
Mat 8:16-17 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, wọ́n gbé ọpọlọpọ eniyan tí wọ́n ní ẹ̀mí èṣù wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Ọ̀rọ̀ ẹnu ni ó fi lé àwọn ẹ̀mí náà jáde, ó sì tún wo gbogbo àwọn tí ara wọn kò dá sàn. Báyìí ni ọ̀rọ̀ tí wolii Aisaya sọ ṣẹ, nígbà tí ó sọ pé, “Òun fúnra rẹ̀ ni ó mú àìlera wa lọ, ó sì gba àìsàn wa fún wa.”
Mat 8:16-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí ó di àṣálẹ́, ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó ní ẹ̀mí èṣù ni a mú wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ lé àwọn ẹ̀mí èṣù náà jáde. A sì mú gbogbo àwọn ọlọ́kùnrùn láradá. Kí èyí tí a ti sọ láti ẹnu wòlíì Isaiah lè ṣẹ pé: “Òun tìkára rẹ̀ gbà àìlera wa, ó sì ń ru ààrùn wa.”