Mat 8:1-3
Mat 8:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBATI o ti ori òke sọkalẹ, ọ̀pọ enia ntọ̀ ọ lẹhin. Si wò o, adẹtẹ̀ kan wá, o tẹriba fun u, o wipe, Oluwa, bi iwọ ba fẹ, iwọ le sọ mi di mimọ́. Jesu si nà ọwọ́ rẹ̀, o fi bà a, o wipe, Mo fẹ; iwọ di mimọ́. Lojukanna ẹ̀tẹ rẹ̀ si mọ́.
Mat 8:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Jesu sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, ọ̀pọ̀ àwọn eniyan ń tẹ̀lé e. Ẹnìkan tí ó ní àrùn ẹ̀tẹ̀ sì wá, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó ní, “Alàgbà bí o bá fẹ́, o lè sọ ara mi di mímọ́.” Jesu bá na ọwọ́ rẹ̀, ó fi kàn án, ó ní, “Mo fẹ́, kí ara rẹ di mímọ́.” Lẹsẹkẹsẹ ni àrùn ẹ̀tẹ̀ náà bá kúrò lára rẹ̀.
Mat 8:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí ó ti orí òkè sọ̀kalẹ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. Sì wò ó, adẹ́tẹ̀ kan wà, ó wá ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀ ó wí pé, “Olúwa, bí ìwọ bá fẹ́, ìwọ lè sọ mi di mímọ́.” Jesu sì nà ọwọ́ rẹ̀, ó fi bà á, ó wí pé, “Mo fẹ́, ìwọ di mímọ́.” Lójúkan náà, ẹ̀tẹ̀ rẹ̀ sì mọ́!