Mat 8:1-17
Mat 8:1-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBATI o ti ori òke sọkalẹ, ọ̀pọ enia ntọ̀ ọ lẹhin. Si wò o, adẹtẹ̀ kan wá, o tẹriba fun u, o wipe, Oluwa, bi iwọ ba fẹ, iwọ le sọ mi di mimọ́. Jesu si nà ọwọ́ rẹ̀, o fi bà a, o wipe, Mo fẹ; iwọ di mimọ́. Lojukanna ẹ̀tẹ rẹ̀ si mọ́. Jesu si wi fun u pe, Wò ó, máṣe sọ fun ẹnikan; ṣugbọn mã ba ọ̀na rẹ lọ, fi ara rẹ hàn fun awọn alufa, ki o si fi ẹ̀bun ti Mose palaṣẹ li ẹrí fun wọn. Nigbati Jesu si wọ̀ Kapernaumu, balogun ọrún kan tọ̀ ọ wá, o mbẹ̀ ẹ, O si nwipe, Oluwa, ọmọ-ọdọ mi dubulẹ arùn ẹ̀gba ni ile, ni irora pupọ̀. Jesu si wi fun u pe, Emi mbọ̀ wá mu u larada. Balogun ọrún na dahùn, o si wipe, Oluwa, emi ko yẹ ti iwọ iba fi wọ̀ abẹ orule mi; ṣugbọn sọ kìki ọ̀rọ kan, a o si mu ọmọ-ọdọ mi larada. Ẹniti o wà labẹ aṣẹ sá li emi, emi si li ọmọ-ogun lẹhin mi; mo wi fun ẹnikan pe, Lọ, a si lọ; ati fun ẹnikeji pe, Wá, a si wá; ati fun ọmọ-ọdọ mi pe, Ṣe eyi, a si ṣe e. Nigbati Jesu gbọ́, ẹnu yà a, o si wi fun awọn ti o ntọ̀ ọ lẹhin pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, emi ko ri igbagbọ́ nla bi irú eyi ninu awọn enia Israeli. Mo si wi fun nyin, ọ̀pọlọpọ enia ni yio ti ìha ìla-õrùn ati ìha íwọ-õrùn wá, nwọn a si ba Abrahamu, ati Isaaki, ati Jakọbu joko ni ilẹ-ọba ọrun. Ṣugbọn awọn ọmọ ilẹ-ọba li a o sọ sinu òkunkun lode, nibẹ̀ li ẹkún on ipahinkeke yio gbe wà. Jesu si wi fun balogun ọrún na pe, Mã lọ, bi iwọ si ti gbagbọ́, bẹ̃ni ki o ri fun ọ. A si mu ọmọ-ọdọ rẹ̀ larada ni wakati kanna. Nigbati Jesu si wọ̀ ile Peteru lọ, o ri iya aya rẹ̀ dubulẹ àisan ibà. O si fi ọwọ́ bà a li ọwọ́, ibà si fi i silẹ; on si dide, o si nṣe iranṣẹ fun wọn. Nigbati o si di aṣalẹ, nwọn gbe ọ̀pọlọpọ awọn ẹniti o ni ẹmi èṣu wá sọdọ rẹ̀: o si fi ọ̀rọ rẹ̀ lé awọn ẹmi na jade, o si mu awọn olokunrun larada: Ki eyi ti a ti sọ lati ẹnu woli Isaiah wá le ṣẹ, pe, On tikararẹ̀ gbà ailera wa, o si nrù àrun wa.
Mat 8:1-17 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Jesu sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, ọ̀pọ̀ àwọn eniyan ń tẹ̀lé e. Ẹnìkan tí ó ní àrùn ẹ̀tẹ̀ sì wá, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó ní, “Alàgbà bí o bá fẹ́, o lè sọ ara mi di mímọ́.” Jesu bá na ọwọ́ rẹ̀, ó fi kàn án, ó ní, “Mo fẹ́, kí ara rẹ di mímọ́.” Lẹsẹkẹsẹ ni àrùn ẹ̀tẹ̀ náà bá kúrò lára rẹ̀. Jesu wá sọ fún un pé, “Má sọ fún ẹnikẹ́ni. Ṣugbọn, lọ, fi ara rẹ han alufaa, kí o ṣe ìrúbọ gẹ́gẹ́ bí Mose ti pa á láṣẹ, bí ẹ̀rí fún wọn pé ara rẹ ti dá.” Nígbà tí Jesu wọ ìlú Kapanaumu, ọ̀gágun kan tí ó ní ọgọrun-un ọmọ-ogun lábẹ́ rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, ó ń bẹ̀ ẹ́; ó ní, “Alàgbà, ọmọ-ọ̀dọ̀ mi kan wà ninu ilé tí àrùn ẹ̀gbà ń dà láàmú, ó sì ń joró gidigidi.” Jesu bá sọ fún un pé, “N óo wá, n óo sì wò ó sàn.” Ṣugbọn ọ̀gágun náà dáhùn pé, “Alàgbà, èmi kò yẹ ní ẹni tí ìwọ ìbá wọ inú ilé rẹ̀. Ṣá sọ gbolohun kan, ara ọmọ-ọ̀dọ̀ mi yóo sì dá. Nítorí ẹni tí ó wà lábẹ́ àṣẹ ni èmi náà, mo ní àwọn ọmọ-ogun lábẹ́ mi. Bí mo bá sọ fún ọ̀kan pé, ‘Lọ!’ yóo lọ ni. Bí mo bá sọ fún òmíràn pé, ‘Wá!’ yóo sì wá. Bí mo bá sọ fún ẹrú mi pé, ‘Ṣe èyí!’ yóo ṣe é ni.” Nígbà tí Jesu gbọ́, ẹnu yà á, ó sọ fún àwọn tí ó ń tẹ̀lé e pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, n kò rí irú igbagbọ báyìí ní Israẹli pàápàá! Mo tún ń sọ fun yín pé, ọpọlọpọ eniyan yóo wá láti ìlà oòrùn ati láti ìwọ̀ oòrùn, wọn yóo bá Abrahamu ati Isaaki ati Jakọbu jẹun ní ìjọba ọ̀run. Ṣugbọn àwọn ọmọ ìjọba ọ̀run ni a óo tì jáde sinu òkùnkùn biribiri, níbi tí ẹkún ati ìpayínkeke yóo wà.” Jesu bá sọ fún ọ̀gágun náà pé, “Máa lọ, gẹ́gẹ́ bí o ti gbàgbọ́, bẹ́ẹ̀ ni kí ó rí fún ọ.” Ara ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ sì dá ní àkókò náà gan-an. Nígbà tí Jesu wọ inú ilé Peteru, ó rí ìyá iyawo Peteru tí ibà dá dùbúlẹ̀. Jesu bá fi ọwọ́ kàn án lọ́wọ́, ibà náà sì fi í sílẹ̀. Ó bá dìde, ó bá tọ́jú oúnjẹ fún un. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, wọ́n gbé ọpọlọpọ eniyan tí wọ́n ní ẹ̀mí èṣù wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Ọ̀rọ̀ ẹnu ni ó fi lé àwọn ẹ̀mí náà jáde, ó sì tún wo gbogbo àwọn tí ara wọn kò dá sàn. Báyìí ni ọ̀rọ̀ tí wolii Aisaya sọ ṣẹ, nígbà tí ó sọ pé, “Òun fúnra rẹ̀ ni ó mú àìlera wa lọ, ó sì gba àìsàn wa fún wa.”
Mat 8:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí ó ti orí òkè sọ̀kalẹ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. Sì wò ó, adẹ́tẹ̀ kan wà, ó wá ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀ ó wí pé, “Olúwa, bí ìwọ bá fẹ́, ìwọ lè sọ mi di mímọ́.” Jesu sì nà ọwọ́ rẹ̀, ó fi bà á, ó wí pé, “Mo fẹ́, ìwọ di mímọ́.” Lójúkan náà, ẹ̀tẹ̀ rẹ̀ sì mọ́! Jesu sì wí fún pé, “Wò ó, má ṣe sọ fún ẹnìkan. Ṣùgbọ́n máa ba ọ̀nà rẹ̀ lọ, fi ara rẹ̀ hàn fún àlùfáà, kí o sì san ẹ̀bùn tí Mose pàṣẹ ní ẹ̀rí fún wọn.” Nígbà tí Jesu sì wọ̀ Kapernaumu, balógun ọ̀rún kan tọ̀ ọ́ wá, ó bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́. O sì wí pé, “Olúwa, ọmọ ọ̀dọ̀ mi dùbúlẹ̀ ààrùn ẹ̀gbà ni ilé, tòun ti ìrora ńlá.” Jesu sì wí fún un pé, “Èmi ń bọ̀ wá mú un láradá.” Balógun ọ̀rún náà dáhùn, ó wí pé, “Olúwa, èmi kò yẹ ní ẹni tí ìwọ ń wọ̀ abẹ́ òrùlé rẹ̀, ṣùgbọ́n sọ kìkì ọ̀rọ̀ kan, a ó sì mú ọmọ ọ̀dọ̀ mi láradá. Ẹni tí ó wà lábẹ́ àṣẹ sá ni èmi, èmi sí ní ọmọ-ogun lẹ́yìn mi. Bí mo wí fún ẹni kan pé, ‘Lọ,’ a sì lọ, àti fún ẹni kejì pé, ‘Wá,’ a sì wá, àti fún ọmọ ọ̀dọ̀ mi pé, ‘Ṣe èyí,’ a sì ṣe é.” Nígbà tí Jesu gbọ́ èyí ẹnu yà á, ó sì wí fún àwọn tí ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, èmi kò rí ẹnìkan ni Israẹli tó ní ìgbàgbọ́ ńlá bí irú èyí. Mo sì wí fún yín, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yóò ti ìhà ìlà-oòrùn àti ìhà ìwọ̀-oòrùn wá, wọ́n á sì bá Abrahamu àti Isaaki àti Jakọbu jẹun ní ìjọba ọ̀run. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ìjọba ni a ó sọ sínú òkùnkùn lóde, níbẹ̀ ni ẹkún àti ìpayínkeke yóò gbé wà.” Nítorí náà Jesu sì wí fún balógun ọ̀run náà pé, “Máa lọ ilé, ohun tí ìwọ gbàgbọ́ ti rí bẹ́ẹ̀.” A sì mú ọmọ ọ̀dọ̀ náà láradá ní wákàtí kan náà. Nígbà tí Jesu sì dé ilé Peteru, ìyá ìyàwó Peteru dùbúlẹ̀ àìsàn ibà. Ṣùgbọ́n nígbà tí Jesu fi ọwọ́ kan ọwọ́ rẹ̀, ibà náà fi í sílẹ̀, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ó sì dìde ó ń ṣe ìránṣẹ́ fún wọn. Nígbà tí ó di àṣálẹ́, ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó ní ẹ̀mí èṣù ni a mú wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ lé àwọn ẹ̀mí èṣù náà jáde. A sì mú gbogbo àwọn ọlọ́kùnrùn láradá. Kí èyí tí a ti sọ láti ẹnu wòlíì Isaiah lè ṣẹ pé: “Òun tìkára rẹ̀ gbà àìlera wa, ó sì ń ru ààrùn wa.”