Mat 6:28-33
Mat 6:28-33 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẽṣe ti ẹnyin sì fi nṣe aniyan nitori aṣọ? Kiyesi lili ti mbẹ ni igbẹ́, bi nwọn ti ndàgba; nwọn kì iṣiṣẹ, bẹ̃ni nwọn kì irànwu: Mo si wi fun nyin pe, a ko ṣe Solomoni pãpã li ọṣọ ninu gbogbo ogo rẹ̀ to bi ọkan ninu wọnyi. Njẹ bi Ọlọrun ba wọ̀ koriko igbẹ́ li aṣọ bẹ̃, eyiti o wà loni, ti a si gbá a sinu iná lọla, melomelo ni ki yio fi le wọ̀ nyin li aṣọ, ẹnyin oni-kekere igbagbọ? Nitorina ẹ maṣe ṣe aniyan, wipe, Kili a o jẹ? tabi, Kili a o mu? tabi, aṣọ wo li a o fi wọ̀ wa? Nitori gbogbo nkan wọnyi li awọn keferi nwá kiri. Nitori Baba nyin ti mbẹ li ọrun mọ̀ pe, ẹnyin kò le ṣe alaini gbogbo nkan wọnyi. Ṣugbọn ẹ tète mã wá ijọba Ọlọrun na, ati ododo rẹ̀; gbogbo nkan wọnyi li a o si fi kún u fun nyin.
Mat 6:28-33 Yoruba Bible (YCE)
“Kí ní ṣe tí ẹ̀ ń ṣe àníyàn nípa ohun tí ẹ óo wọ̀? Ẹ ṣe akiyesi àwọn òdòdó inú igbó bí wọ́n ti ń dàgbà. Wọn kì í ṣiṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í rànwú. Sibẹ mo sọ fun yín pé Solomoni pàápàá ninu gbogbo ìgúnwà rẹ̀ kò lè wọ aṣọ tí ó lẹ́wà bíi ti ọ̀kan ninu àwọn òdòdó yìí. Ǹjẹ́ bí Ọlọrun bá wọ koríko ìgbẹ́ láṣọ báyìí, koríko tí yóo wà lónìí, tí a óo fi dáná lọ́la, mélòó-mélòó ni yóo wọ̀ yín láṣọ, ẹ̀yin onigbagbọ kékeré? “Nítorí náà, ẹ má ṣe àníyàn pé kí ni ẹ óo jẹ? Tabi, kí ni ẹ óo mu? Tabi kí ni ẹ óo fi bora? Nítorí gbogbo nǹkan wọnyi ni àwọn abọ̀rìṣà ń lépa. Nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo wọn. Ṣugbọn ẹ kọ́kọ́ máa wá ìjọba Ọlọrun ná ati òdodo rẹ̀, gbogbo nǹkan wọnyi ni a óo fi kún un fún yín.
Mat 6:28-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Kí ni ìdí ti ẹ fi ń ṣe àníyàn ní ti aṣọ? Ẹ wo bí àwọn lílì tí ń bẹ ní igbó ti ń dàgbà. Wọn kì í ṣiṣẹ́ bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í rànwú. Bẹ́ẹ̀ ni mo wí fún yín pé, a kò ṣe Solomoni lọ́ṣọ̀ọ́ nínú gbogbo ògo rẹ̀ tó ọ̀kan nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí. Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run bá wọ koríko igbó ní aṣọ bẹ́ẹ̀, èyí tí ó wà níhìn-ín lónìí ti a sì gbà sínú iná lọ́la, kò ha ṣe ni ṣe yín lọ́ṣọ̀ọ́ tó bẹ́ẹ̀ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ̀yin tí ìgbàgbọ́ yín kéré? Nítorí náà, ẹ má ṣe ṣe àníyàn kí ẹ sì máa wí pé, ‘Kí ni àwa yóò jẹ?’ Tàbí ‘Kí ni àwa yóò mu?’ Tàbí ‘Irú aṣọ wo ni àwa yóò wọ̀?’ Nítorí àwọn kèfèrí ń fi ìwọra wá àwọn nǹkan wọ̀nyí bẹ́ẹ̀ ni Baba yín ní ọ̀run mọ̀ dájúdájú pé ẹ ní ìlò àwọn nǹkan wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n, ẹ kọ́kọ́ wá ìjọba Ọlọ́run ná àti òdodo rẹ̀, yóò sì fi gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí kún un fún yín pẹ̀lú.