Mat 6:25-27
Mat 6:25-27 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina mo wi fun nyin, Ẹ máṣe ṣe aniyan nitori ẹmí nyin ohun ti ẹ ó jẹ, ati fun ara nyin ohun ti ẹ o fi bora. Ẹmí kò ha jù onjẹ lọ? tabi ara ni kò jù aṣọ lọ? Ẹ sá wò ẹiyẹ oju ọrun; nwọn kì ifunrugbin, bẹ̃ni nwọn kì ikore, nwọn kì isi ikójọ sinu abà, ṣugbọn Baba nyin ti mbẹ li ọrun mbọ́ wọn. Ẹnyin kò ha san jù wọn lọ? Tani ninu nyin nipa aniyàn ṣiṣe ti o le fi igbọnwọ kan kún ọjọ aiyé rẹ̀?
Mat 6:25-27 Yoruba Bible (YCE)
“Nítorí èyí ni mo ṣe sọ fun yín pé kí ẹ má máa ṣe àníyàn nípa ẹ̀mí yín, pé kí ni ẹ óo jẹ tabi kí ni ẹ óo mu, tabi pé kí ni ẹ óo fi bora. Mo ṣebí ẹ̀mí yín ju oúnjẹ lọ; ati pé ara yín ju aṣọ lọ. Ẹ wo àwọn ẹyẹ lójú ọ̀run. Wọn kì í fúnrúgbìn, wọn kì í kórè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kó nǹkan oko jọ sinu abà. Sibẹ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run ń bọ́ wọn. Mo ṣebí ẹ̀yin sàn ju àwọn ẹyẹ lọ! Ta ni ninu yín tí ó lè ṣe àníyàn títí tí ó lè fi kún ọjọ́ ayé rẹ̀?
Mat 6:25-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Nítorí náà, mo wí fún yín, ẹ má ṣe ṣe àníyàn nípa ẹ̀mí yín, ohun tí ẹ ó jẹ àti èyí tí ẹ ó mu; tàbí nípa ara yín, ohun tí ẹ ó wọ̀. Ṣé ẹ̀mí kò ha ṣe pàtàkì ju oúnjẹ lọ tàbí ara ni kò ha ṣe pàtàkì ju aṣọ lọ? Ẹ wo àwọn ẹyẹ ojú ọrun; wọn kì í gbìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kórè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kójọ sínú àká, síbẹ̀ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run ń bọ́ wọn. Ẹ̀yin kò ha níye lórí jù wọ́n lọ bí? Ta ni nínú gbogbo yín nípa àníyàn ṣíṣe ti ó lè fi ìṣẹ́jú kan kún ọjọ́ ayé rẹ̀?