Mat 6:1-24
Mat 6:1-24 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ kiyesi ara ki ẹ máṣe itọrẹ anu nyin niwaju enia, ki a ba le ri nyin: bi o ba ri bẹ̃, ẹnyin ko li ère lọdọ Baba nyin ti mbẹ li ọrun. Nitorina nigbati iwọ ba nṣe itọrẹ ãnu rẹ, máṣe fun fère niwaju rẹ, bi awọn agabagebe ti nṣe ni sinagogu ati ni ita, ki nwọn ki o le gbà iyìn enia. Lõtọ ni mo wi fun nyin, nwọn ti gbà ère wọn na. Ṣugbọn nigbati iwọ ba nṣe itọrẹ ãnu rẹ, máṣe jẹ ki ọwọ́ òsi rẹ ki o mọ̀ ohun ti ọwọ́ ọtún rẹ nṣe; Ki itọrẹ ãnu rẹ ki o le wà ni ìkọkọ; Baba rẹ ti o si riran ni ìkọkọ, on tikararẹ̀ yio san a fun ọ ni gbangba. Nigbati iwọ ba ngbadura, máṣe dabi awọn agabagebe; nitori nwọn fẹ ati mã duro gbadura ni sinagogu ati ni igun ọ̀na ita, ki enia ki o ba le ri wọn. Lõtọ ni mo wi fun nyin, nwọn ti gbà ère wọn na. Ṣugbọn iwọ, nigbati iwọ ba ngbadura, wọ̀ iyẹwu rẹ lọ, nigbati iwọ ba si sé ilẹkùn rẹ tan, gbadura si Baba rẹ ti mbẹ ni ìkọkọ; Baba rẹ ti o si riran ni ìkọkọ yio san a fun ọ ni gbangba. Ṣugbọn nigbati ẹnyin ba ngbadura, ẹ máṣe atunwi asan bi awọn keferi; nwọn ṣebi a o ti itori ọ̀rọ pipọ gbọ́ ti wọn. Nitorina ki ẹnyin máṣe dabi wọn: Baba nyin sá mọ̀ ohun ti ẹnyin ṣe alaini, ki ẹ to bère lọwọ rẹ̀. Nitorina bayi ni ki ẹnyin mã gbadura: Baba wa ti mbẹ li ọrun; Ki a bọ̀wọ fun orukọ rẹ. Ki ijọba rẹ de; Ifẹ tirẹ ni ki a ṣe, bi ti ọrun, bẹ̃ni li aiye. Fun wa li onjẹ õjọ wa loni. Dari gbese wa jì wa, bi awa ti ndarijì awọn onigbese wa. Má si fà wa sinu idẹwò, ṣugbọn gbà wa lọwọ bilisi. Nitori ijọba ni tirẹ, ati agbara, ati ogo, lailai. Amin. Nitori bi ẹnyin ba fi ẹ̀ṣẹ awọn enia jì wọn, Baba nyin ti mbẹ li ọrun yio fi ẹ̀ṣẹ ti nyin jì nyin. Ṣugbọn bi ẹnyin ko ba fi ẹ̀ṣẹ awọn enia jì wọn, Baba nyin ki yio si fi ẹ̀ṣẹ ti nyin jì nyin. Ati pẹlu nigbati ẹnyin ba ngbàwẹ, ẹ máṣe dabi awọn agabagebe ti nfajuro; nwọn a ba oju jẹ, nitori ki nwọn ki o ba le farahàn fun enia pe nwọn ngbàwẹ. Lõtọ ni mo wi fun nyin, nwọn ti gbà ère wọn na. Ṣugbọn iwọ, nigbati iwọ ba ngbàwẹ, fi oróro kùn ori rẹ, ki o si bọju rẹ; Ki iwọ ki o máṣe farahàn fun enia pe iwọ ngbàwẹ, bikoṣe fun Baba rẹ ti o mbẹ ni ìkọkọ; Baba rẹ ti o si riran ni ìkọkọ yio san a fun ọ ni gbangba. Ẹ máṣe tò iṣura jọ fun ara nyin li aiye, nibiti kòkoro ati ipãra ibà a jẹ, ati nibiti awọn olè irunlẹ ti nwọn si ijale: Ṣugbọn ẹ tò iṣura jọ fun ara nyin li ọrun, nibiti kòkoro ati ipãra ko le bà a jẹ, ati nibiti awọn olè kò le runlẹ ki nwọn si jale. Nitori nibiti iṣura nyin bá gbé wà, nibẹ̀ li ọkàn nyin yio gbé wà pẹlu. Oju ni fitila ara: nitorina bi oju rẹ ba mọ́, gbogbo ara rẹ ni yio kún fun imọlẹ. Ṣugbọn bi oju rẹ ba ṣõkùn, gbogbo ara rẹ ni yio kun fun òkunkun. Njẹ bi imọlẹ ti mbẹ ninu rẹ ba jẹ́ òkunkun, òkunkun na yio ti pọ̀ to! Ko si ẹniti o le sìn oluwa meji: nitori yala yio korira ọkan, yio si fẹ ekeji; tabi yio faramọ ọkan, yio si yàn ekeji ni ipọsi. Ẹnyin ko le sìn Oluwa pẹlu mamoni.
Mat 6:1-24 Yoruba Bible (YCE)
“Ẹ ṣọ́ra nígbà tí ẹ bá ń ṣe iṣẹ́ ẹ̀sìn yín, ẹ má máa hùwà ṣe-á-rí-mi, kí àwọn eniyan baà lè rí ohun tí ẹ̀ ń ṣe. Bí ẹ bá ń hùwà ṣe-á-rí-mi, ẹ kò ní èrè lọ́dọ̀ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run. “Nítorí náà, nígbà tí o bá ń ṣe ìtọrẹ àánú, má ṣe gbé agogo síta gẹ́gẹ́ bí àwọn aláṣehàn tí ń ṣe ninu àwọn ilé ìpàdé ati ní ojú títì ní ìgboro, kí wọn lè gba ìyìn eniyan. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, wọ́n ti gba èrè wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Ṣugbọn nígbà tí o bá ń ṣe ìtọrẹ àánú, má tilẹ̀ jẹ́ kí ọwọ́ òsì rẹ mọ ohun tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ń ṣe; kí ìtọrẹ àánú rẹ jẹ́ ohun ìkọ̀kọ̀. Baba rẹ, tí ó rí ohun tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀ yóo sì san ẹ̀san rẹ fún ọ. “Nígbà tí ẹ bá ń gbadura, ẹ má ṣe bí àwọn aláṣehàn. Nítorí wọ́n fẹ́ràn kí wọ́n máa dúró gbadura ninu ilé ìpàdé ati ní ẹ̀bá títì, kí àwọn eniyan lè rí wọn. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, wọ́n ti gba èrè wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Ṣugbọn nígbà tí ìwọ bá ń gbadura, wọ inú yàrá rẹ lọ, ti ìlẹ̀kùn rẹ, kí o gbadura sí Baba rẹ tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀. Baba rẹ, tí ó rí ohun tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀, yóo san ẹ̀san rẹ fún ọ. “Nígbà tí ẹ bá ń gbadura, ẹ má máa wí nǹkankan náà títí, bí àwọn abọ̀rìṣà ti ń ṣe. Nítorí wọ́n rò pé nípa ọ̀rọ̀ pupọ ni adura wọn yóo ṣe gbà. Ẹ má ṣe fara wé wọn, nítorí Baba yín ti mọ ohun tí ẹ nílò kí ẹ tó bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Nítorí náà, báyìí ni kí ẹ̀yin máa gbadura: ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run: Kí á bọ̀wọ̀ fún orúkọ mímọ́ rẹ, kí ìjọba rẹ dé, ìfẹ́ tìrẹ ni kí á ṣe ní ayé bí wọ́n ti ń ṣe ní ọ̀run. Fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lónìí. Dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá gẹ́gẹ́ bí àwa náà ti dárí ji àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ wá. Má fà wá sinu ìdánwò, ṣugbọn gbà wá lọ́wọ́ èṣù.’ “Nítorí bí ẹ bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan jì wọ́n, Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run yóo dáríjì yín. Ṣugbọn bí ẹ kò bá dáríjì àwọn eniyan, Baba yín kò ní dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín. “Nígbà tí ẹ bá ń gbààwẹ̀, ẹ má máa ṣe bí àwọn aláṣehàn tí wọ́n máa ń fajúro, kí àwọn eniyan lè rí i lójú wọn pé wọ́n ń gbààwẹ̀. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, wọ́n ti gba èrè wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Ṣugbọn nígbà tí ìwọ bá ń gbààwẹ̀, bọ́jú kí o sì fi nǹkan pa ara, kí ó má baà hàn sí àwọn eniyan pé ò ń gbààwẹ̀, àfi sí Baba rẹ tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀. Baba rẹ, tí ó rí ohun tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀, yóo san ẹ̀san fún ọ. “Ẹ má ṣe kó ìṣúra jọ fún ara yín ní ayé, níbi tí kòkòrò lè bà á jẹ́, tí ó sì lè dógùn-ún. Àwọn olè tún lè wá a kàn kí wọ́n jí i lọ. Ṣugbọn ẹ kó ìṣúra jọ fún ara yín ní ọ̀run, níbi tí kòkòrò kò lè bà á jẹ́, bẹ́ẹ̀ ni kò lè dógùn-ún, àwọn olè kò sì lè wá a kàn kí wọ́n jí i lọ níbẹ̀. Nítorí níbi tí ìṣúra rẹ bá wà, níbẹ̀ náà ni ọkàn rẹ yóo wà. “Ojú ni ìmọ́lẹ̀ ara. Bí ojú rẹ bá ríran kedere, gbogbo ara rẹ yóo ní ìmọ́lẹ̀. Ṣugbọn bí ojú rẹ kò bá ríran tààrà, gbogbo ara rẹ ni yóo ṣókùnkùn. Bí ìmọ́lẹ̀ tí ó wà ninu rẹ bá wá di òkùnkùn, báwo ni òkùnkùn náà yóo ti pọ̀ tó! “Kò sí ẹni tí ó lè sin oluwa meji. Nítorí ọ̀kan ni yóo ṣe: ninu kí ó kórìíra ọ̀kan, kí ó fẹ́ràn ekeji, tabi kí ó fara mọ́ ọ̀kan, kí ó má ka ekeji sí. Ẹ kò lè sin Ọlọrun, kí ẹ tún máa bọ owó.
Mat 6:1-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ẹ kíyèsára kí ẹ má ṣe iṣẹ́ rere yín níwájú àwọn ènìyàn nítorí kí a le rí yín, Bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin kò ni èrè kankan lọ́dọ̀ Baba yín ní ọ̀run. “Nítorí náà, nígbà ti ẹ́ bá ti ń fún aláìní, ẹ má ṣe fi fèrè kéde rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn àgàbàgebè ti í ṣe ní Sinagọgu àti ní ìta gbangba; kí àwọn ènìyàn le yìn wọ́n. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, wọ́n ti gba èrè tí wọn ní kíkún. Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá ń fi fún aláìní, má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ òsì rẹ mọ ohun tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ń ṣe, kí ìfúnni rẹ má ṣe jẹ́ mí mọ̀. Nígbà náà ni Baba rẹ̀, tí ó sì mọ ohun ìkọ̀kọ̀ gbogbo, yóò san án fún ọ. “Nígbà tí ìwọ bá ń gbàdúrà, má ṣe ṣe bí àwọn àgàbàgebè, nítorí wọn fẹ́ràn láti máa dúró gbàdúrà ní Sinagọgu àti ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà tí ènìyàn ti lè rí wọ́n. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, wọ́n ti gba èrè wọn ní kíkún. Ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá ń gbàdúrà, wọ inú iyàrá rẹ lọ, sé ìlẹ̀kùn mọ́ ara rẹ, gbàdúrà sí Baba rẹ ẹni tí ìwọ kò rí. Nígbà náà ni Baba rẹ tí ó mọ gbogbo ohun ìkọ̀kọ̀ rẹ, yóò san án fún ọ. Ṣùgbọ́n nígbà ti ẹ̀yin bá ń gbàdúrà, ẹ má ṣe àtúnwí asán bí àwọn aláìkọlà, nítorí wọn rò pé a ó tìtorí ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ gbọ́ tiwọn. Ẹ má ṣe dàbí i wọn, nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ ohun tí ẹ ṣe aláìní, kí ẹ tilẹ̀ tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀. “Nítorí náà, báyìí ni kí ẹ ṣe máa gbàdúrà: “ ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, ọ̀wọ̀ fún orúkọ yín, Kí ìjọba yín dé, Ìfẹ́ tiyín ni kí a ṣe ní ayé bí ti ọ̀run. Ẹ fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lónìí Ẹ dárí gbèsè wa jì wá, Bí àwa ti ń dáríji àwọn ajigbèsè wa, Ẹ má ṣe fà wá sínú ìdánwò, Ṣùgbọ́n ẹ gbà wá lọ́wọ́ ibi. Nítorí ìjọba ni tiyín, àti agbára àti ògo, láéláé, Àmín.’ Nítorí náà, bí ẹ̀yin bá dárí jí àwọn tó ṣẹ̀ yín, baba yín ọ̀run náà yóò dáríjì yín. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá kọ̀ láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn jì wọ́n, baba yín kò ní í dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín. “Nígbà tí ẹ̀yin bá gbààwẹ̀, ẹ má ṣe fa ojú ro bí àwọn àgàbàgebè ṣe máa ń ṣe nítorí wọn máa ń fa ojú ro láti fihàn àwọn ènìyàn pé àwọn ń gbààwẹ̀. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín wọn ti gba èrè wọn ní kíkún. Ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá gbààwẹ̀, bu òróró sí orí rẹ, kí ó sì tún ojú rẹ ṣe dáradára. Kí ó má ṣe hàn sí ènìyàn pé ìwọ ń gbààwẹ̀, bí kò ṣe sì í Baba rẹ, ẹni tí ìwọ kò rí, àti pé, Baba rẹ tí ó rí ohun tí o ṣe ni ìkọ̀kọ̀, yóò san án fún ọ. “Má ṣe to àwọn ìṣúra jọ fún ara rẹ ní ayé yìí, níbi tí kòkòrò ti le jẹ ẹ́, tí ó sì ti le bàjẹ́ àti ibi tí àwọn olè lè fọ́ tí wọ́n yóò sì jí i lọ. Dípò bẹ́ẹ̀ to ìṣúra rẹ jọ sí ọ̀run, níbi ti kòkòrò àti ìpáàrà kò ti lè bà á jẹ́, àti ní ibi tí àwọn olè kò le fọ́ wọlé láti jí í lọ. Nítorí ibi tí ìṣúra yín bá wà níbẹ̀ náà ni ọkàn yín yóò wà pẹ̀lú. “Ojú ni fìtílà ara. Bí ojú rẹ bá mọ́lẹ̀ kedere, gbogbo ara rẹ yóò jẹ́ kìkì ìmọ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n bí ojú rẹ kò bá dára, gbogbo ara rẹ ni yóò kún fún òkùnkùn. Bí ìmọ́lẹ̀ ti ó wà nínú rẹ bá wá jẹ́ òkùnkùn, òkùnkùn náà yóò ti pọ̀ tó! “Kò sì í ẹnìkan tí ó lè sin ọ̀gá méjì. Òun yóò yà kórìíra ọ̀kan tí yóò fẹ́ràn èkejì, tàbí kí ó fi ara mọ́ ọ̀kan kí ó sì yan èkejì ní ìpọ̀sí. Ẹ̀yin kò lè sin Ọlọ́run àti owó papọ̀.