Mat 5:38-40
Mat 5:38-40 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹnyin ti gbọ́ bi a ti wipe, Oju fun oju, ati ehín fun ehín: Ṣugbọn emi wi fun nyin, Ẹ máṣe kọ̀ ibi; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba gbá ọ li ẹrẹkẹ ọtún, yi ti òsi si i pẹlu. Bi ẹnikan ba fẹ sùn ọ ni ile ẹjọ, ti o si gbà ọ li ẹ̀wu lọ, jọwọ agbáda rẹ fun u pẹlu.
Mat 5:38-40 Yoruba Bible (YCE)
“Ẹ ti gbọ́ tí a sọ pé, ‘Nígbà tí o bá fẹ́ gbẹ̀san, ojú dípò ojú ati eyín dípò eyín ni.’ Ṣugbọn èmi wá ń sọ fún yín pé, ẹ má ṣe gbẹ̀san bí ẹnikẹ́ni bá ṣe yín níbi. Kàkà bẹ́ẹ̀, bí ẹnìkan bá gbá yín létí ọ̀tún, ẹ kọ ti òsì sí i. Ẹni tí ó bá fẹ́ pè ọ́ lẹ́jọ́ láti gba àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ, jẹ́ kí ó gba ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ náà.
Mat 5:38-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ẹ̀yin tí gbọ́ bí òfin tí wí pé, ‘Ojú fún ojú àti eyín fún eyín.’ Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín pé, ẹ má ṣe tako ẹni ibi. Bí ẹnìkan bá gbá ọ lẹ́rẹ̀kẹ́ ọ̀tún, yí ẹ̀rẹ̀kẹ́ òsì sí olúwa rẹ̀ pẹ̀lú. Bí ẹnìkan bá fẹ́ gbé ọ lọ sílé ẹjọ́, tí ó sì fẹ́ gba ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀, jọ̀wọ́ agbádá rẹ fún un pẹ̀lú.