Mat 5:13-16
Mat 5:13-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹnyin ni iyọ̀ aiye: ṣugbọn bi iyọ̀ ba di obu, kini a o fi mu u dùn? kò nilari mọ́, bikoṣepe a dà a nù, ki o si di itẹmọlẹ li atẹlẹsẹ enia. Ẹnyin ni imọlẹ aiye. Ilu ti a tẹ̀do lori òke ko le farasin. Bẹ̃ni a kì itàn fitila tan, ki a si fi i sabẹ òṣuwọn; bikoṣe lori ọpá fitila, a si fi imọlẹ fun gbogbo ẹniti mbẹ ninu ile. Ẹ jẹ ki imọlẹ nyin ki o mọlẹ tobẹ̃ niwaju enia, ki nwọn ki o le mã ri iṣẹ rere nyin, ki nwọn ki o le ma yìn Baba nyin ti mbẹ li ọrun logo.
Mat 5:13-16 Yoruba Bible (YCE)
“Ẹ̀yin ni iyọ̀ ayé; ṣugbọn bí iyọ̀ bá di òbu, kí ni yóo tún sọ ọ́ di iyọ̀ gidi mọ́? Kò wúlò fún ohunkohun mọ́ àfi kí á dà á nù, kí eniyan máa tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀. “Ẹ̀yin ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ìlú tí a tẹ̀dó sórí òkè, kò ṣe é gbé pamọ́. Wọn kì í tan fìtílà tán kí wọ́n fi igbá bò ó; lórí ọ̀pá fìtílà ni wọ́n ń gbé e kà. Yóo wá fi ìmọ́lẹ̀ fún gbogbo ẹni tí ó wà ninu ilé. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ìmọ́lẹ̀ yín níláti máa tàn níwájú àwọn eniyan, kí wọn lè rí iṣẹ́ rere yín, kí wọn lè máa yin Baba yín tí ó ń bẹ lọ́run lógo.
Mat 5:13-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ẹ̀yin ni iyọ̀ ayé. Ṣùgbọ́n bí iyọ̀ bá di òbu kí ni a ó fi mú un dùn? Kò tún wúlò fún ohunkóhun mọ́, bí kò ṣe pé kí a dàánù, kí ó sì di ohun tí ènìyàn ń fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀. “Ẹyin ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ìlú tí a tẹ̀dó sórí òkè kò lè fi ara sin. Bẹ́ẹ̀ ni a kì í tan fìtílà tán, kí a sì gbé e sí abẹ́ òṣùwọ̀n; bí kò ṣe sí orí ọ̀pá fìtílà, a sì tan ìmọ́lẹ̀ fún gbogbo ẹni tí ń bẹ nínú ilé. Bákan náà, ẹ jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ yín kí ó mọ́lẹ̀ níwájú ènìyàn, kí wọ́n lè máa rí iṣẹ́ rere yín, kí wọn lè máa yin baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run lógo.