Mat 5:1-10
Mat 5:1-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBATI o si ri ọ̀pọ enia, o gùn ori òke lọ: nigbati o si joko, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ tọ̀ ọ wá. O si yà ẹnu rẹ̀, o si kọ́ wọn, wipe: Alabukún-fun li awọn òtoṣi li ẹmí: nitori tiwọn ni ijọba ọrun. Alabukún-fun li awọn ẹniti nkãnu: nitoriti a ó tù wọn ninu. Alabukún-fun li awọn ọlọkàn-tutù: nitori nwọn o jogún aiye. Alabukún-fun li awọn ẹniti ebi npa ati ti ongbẹ ngbẹ sipa ododo: nitori nwọn ó yo. Alabukún-fun li awọn alãnu: nitori nwọn ó ri ãnu gbà. Alabukún-fun li awọn oninu-funfun: nitori nwọn ó ri Ọlọrun. Alabukún-fun li awọn onilaja: nitori ọmọ Ọlọrun ni a ó ma pè wọn. Alabukúnfun li awọn ẹniti a ṣe inunibini si nitori ododo: nitori tiwọn ni ijọba ọrun.
Mat 5:1-10 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Jesu rí ọ̀pọ̀ eniyan, ó gun orí òkè lọ. Ó jókòó; àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó bá tẹnu bọ̀rọ̀, ó ń kọ́ wọn pé: “Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ó jẹ́ òtòṣì ní ẹ̀mí, nítorí tiwọn ni ìjọba ọ̀run. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀, nítorí Ọlọrun yóo tù wọ́n ninu. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀, nítorí wọn yóo jogún ayé. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ebi òdodo ń pa, tí òùngbẹ òdodo sì ń gbẹ, nítorí Ọlọrun yóo bọ́ wọn ní àbọ́yó. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn aláàánú, nítorí Ọlọrun yóo ṣàánú wọn. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ọkàn wọn mọ́, nítorí wọn yóo rí Ọlọrun. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ó ń mú kí alaafia wà láàrin àwọn eniyan, nítorí Ọlọrun yóo pè wọ́n ní ọmọ rẹ̀. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí eniyan ń ṣe inúnibíni sí nítorí òdodo, nítorí tiwọn ni ìjọba ọ̀run.
Mat 5:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó gun orí òkè lọ ó sì jókòó. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ si tọ̀ ọ́ wá. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn. Ó wí pé: “Alábùkún fún ni àwọn òtòṣì ní ẹ̀mí, nítorí tiwọn ni ìjọba ọ̀run. Alábùkún fún ni àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀, nítorí a ó tù wọ́n nínú. Alábùkún fún ni àwọn ọlọ́kàn tútù, nítorí wọn yóò jogún ayé. Alábùkún fún ni àwọn tí ebi ń pa tí òǹgbẹ ń gbẹ́ nítorí òdodo, nítorí wọn yóò yó. Alábùkún fún ni àwọn aláàánú, nítorí wọn yóò rí àánú gbà. Alábùkún fún ni àwọn ọlọ́kàn mímọ́, nítorí wọn yóò rí Ọlọ́run. Alábùkún fún ni àwọn onílàjà, nítorí ọmọ Ọlọ́run ni a ó máa pè wọ́n. Alábùkún fún ni àwọn ẹni tí a ṣe inúnibíni sí, nítorí tí wọ́n jẹ́ olódodo nítorí tiwọn ní ìjọba ọ̀run.