Mat 28:1-20

Mat 28:1-20 Bibeli Mimọ (YBCV)

LI opin ọjọ isimi, bi ilẹ ọjọ kini ọ̀sẹ ti bèrẹ si imọ́, Maria Magdalene ati Maria keji wá lati wò ibojì na. Si wò o, ìṣẹlẹ nla ṣẹ̀: nitori angẹli Oluwa ti ọrun sọkalẹ wá, o si yi okuta na kuro, o si joko lé e. Oju rẹ̀ dabi manamana, aṣọ rẹ̀ si fún bi ẹ̀gbọn owu: Nitori ẹ̀ru rẹ̀ awọn oluṣọ warìri, nwọn si dabi okú. Angẹli na si dahùn, o si wi fun awọn obinrin na pe, Ẹ má bẹ̀ru: nitori emi mọ̀ pe ẹnyin nwá Jesu, ti a ti kàn mọ agbelebu. Kò si nihinyi: nitori o ti jinde gẹgẹ bi o ti wi. Wá, ẹ wò ibiti Oluwa ti dubulẹ si. Ẹ si yara lọ isọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, o ti jinde kuro ninu okú; wo o, ó ṣãju nyin lọ si Galili; nibẹ̀ li ẹnyin o gbé ri i: wo o, mo ti sọ fun nyin. Nwọn si fi ibẹru pẹlu ayọ̀ nla yara lọ kuro ni ibojì; nwọn si saré lọ iròhin fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀. Bi nwọn si ti nlọ isọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, wo o, Jesu pade wọn, o wipe, Alafia. Nwọn si wá, nwọn si gbá a li ẹsẹ mu, nwọn si tẹriba fun u. Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Ẹ má bẹ̀ru: ẹ lọ isọ fun awọn arakunrin mi pe, ki nwọn ki o lọ si Galili, nibẹ̀ ni nwọn o gbé ri mi. Njẹ bi nwọn ti nlọ, wo o, ninu awọn olusọ wá si ilu, nwọn rohin gbogbo nkan wọnyi ti o ṣe fun awọn olori alufa. Nigbati awọn pẹlu awọn agbàgba pejọ, ti nwọn si gbìmọ, nwọn fi ọ̀pọ owo fun awọn ọmọ-ogun na, Nwọn wi fun wọn pe, Ẹ wipe, Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá li oru, nwọn si ji i gbé lọ nigbati awa sùn. Bi eyi ba de etí Bãlẹ, awa o yi i li ọkàn pada, a o si gbà nyin silẹ. Bẹ̃ni nwọn gbà owo na, nwọn si ṣe gẹgẹ bi a ti kọ́ wọn: ọ̀rọ yi si di rirò kiri lọdọ awọn Ju titi di oni. Nigbana li awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mọkanla jade lọ si Galili, si ori òke ti Jesu ti sọ fun wọn. Nigbati nwọn si ri i, nwọn foribalẹ fun u: ṣugbọn awọn miran ṣiyemeji. Jesu si wá, o si sọ fun wọn, wipe, Gbogbo agbara li ọrun ati li aiye li a fifun mi. Nitorina ẹ lọ, ẹ ma kọ́ orilẹ-ède gbogbo, ki ẹ si mã baptisi wọn ni orukọ Baba, ati ni ti Ọmọ, ati ni ti Ẹmí Mimọ́: Ki ẹ mã kọ́ wọn lati mã kiyesi ohun gbogbo, ohunkohun ti mo ti pa li aṣẹ fun nyin: ẹ si kiyesi i, emi wà pẹlu nyin nigbagbogbo, titi o fi de opin aiye. Amin.

Mat 28:1-20 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí Ọjọ́ Ìsinmi ti kọjá, tí ilẹ̀ fẹ́rẹ̀ mọ́ ní ọjọ́ kinni ọ̀sẹ̀, Maria Magidaleni ati Maria keji wá wo ibojì Jesu. Ilẹ̀ mì tìtì, nítorí angẹli Oluwa sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá. Ó yí òkúta tí ó wà lẹ́nu ibojì kúrò, ó sì jókòó lórí rẹ̀. Ìrísí rẹ̀ dàbí mànàmáná. Aṣọ rẹ̀ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú. Ẹ̀rù mú kí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ibojì náà gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, kí wọn sì kú sára. Angẹli náà sọ fún àwọn obinrin náà pé, “Ẹ má bẹ̀rù. Mo mọ̀ pé Jesu tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu ni ẹ̀ ń wá. Kò sí níhìn-ín, nítorí ó ti jí dìde, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ. Ẹ wá wo ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí. Ẹ lọ sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wéré, pé ó ti jí dìde kúrò ninu òkú. Ó ti ṣáájú yín lọ sí Galili; níbẹ̀ ni ẹ óo ti rí i. Ohun tí mo ní sọ fun yín nìyí.” Àwọn obinrin náà bá yára kúrò níbi ibojì náà pẹlu ìbẹ̀rùbojo ati ayọ̀ ńlá, wọ́n sáré lọ sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Lójijì Jesu pàdé wọn, ó kí wọn, ó ní, “Ẹ pẹ̀lẹ́ o!” Wọ́n bá dì mọ́ ọn lẹ́sẹ̀, wọ́n júbà rẹ̀. Jesu wá sọ fún wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù. Ẹ lọ sọ fún àwọn arakunrin mi pé kí wọ́n lọ sí Galili; níbẹ̀ ni wọn yóo ti rí mi.” Bí wọ́n ti ń lọ, àwọn kan ninu àwọn tí wọ́n fi ṣọ́ ibojì lọ sí inú ìlú láti sọ ohun gbogbo tí ó ṣẹlẹ̀ fún àwọn olórí alufaa. Nígbà tí àwọn olórí alufaa ti forí-korí pẹlu àwọn àgbà, wọ́n wá owó tí ó jọjú fún àwọn ọmọ-ogun náà. Wọ́n sì kọ́ wọn pé, “Ẹ sọ pé, ‘Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá lóru láti jí òkú rẹ̀ nígbà tí a sùn lọ.’ Bí ìròyìn yìí bá dé etí gomina, a óo bá a sọ̀rọ̀, kò ní sí ohunkohun tí yóo ṣẹ̀rù bà yín.” Àwọn ọmọ-ogun náà bá gba owó tí wọ́n fún wọn, wọ́n ṣe bí wọ́n ti kọ́ wọn. Èyí náà sì ni ìtàn tí àwọn Juu ń sọ káàkiri títí di òní olónìí. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mọkanla lọ sí Galili, sí orí òkè tí Jesu ti sọ fún wọn. Nígbà tí wọn rí i, wọ́n júbà rẹ̀, ṣugbọn àwọn kan ninu wọn ń ṣiyèméjì. Jesu wá sọ́dọ̀ wọn, ó sọ fún wọn pé, “A ti fún mi ní gbogbo àṣẹ ní ọ̀run ati ní ayé. Nítorí náà kí ẹ lọ sọ gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ-ẹ̀yìn mi; kí ẹ máa ṣe ìrìbọmi fún wọn ní orúkọ Baba ati ti Ọmọ ati ti Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ máa kọ́ wọn láti kíyèsí gbogbo nǹkan tí mo pa láṣẹ fun yín. Kí ẹ mọ̀ dájú pé mo wà pẹlu yín ní ìgbà gbogbo, títí dé òpin ayé.”

Mat 28:1-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀, bí ilẹ̀ ti ń mọ́, Maria Magdalene àti Maria kejì lọ sí ibojì. Wọ́n rí i pé, ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá ṣẹ̀ tí ó mú gbogbo ilẹ̀ mì tìtì. Nítorí angẹli Olúwa ti sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run. Ó ti yí òkúta ibojì kúrò. Ó sì jókòó lé e lórí. Ojú rẹ̀ tàn bí mọ̀nàmọ́ná. Aṣọ rẹ̀ sì jẹ́ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú. Ẹ̀rù ba àwọn olùṣọ́, wọ́n sì wárìrì wọn sì dàbí òkú. Nígbà náà ni angẹli náà wí fún àwọn obìnrin náà pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù. Mo mọ̀ pé ẹ̀yin ń wá Jesu tí a kàn mọ́ àgbélébùú. Ṣùgbọ́n kò sí níhìn-ín. Nítorí pé ó ti jíǹde, gẹ́gẹ́ bí òun ti wí. Ẹ wọlé wá wo ibi ti wọ́n tẹ́ ẹ sí. Nísinsin yìí, Ẹ lọ kíákíá láti sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, ‘Ó ti jíǹde kúrò nínú òkú. Àti pé òun ń lọ sí Galili síwájú yín, níbẹ̀ ni ẹ̀yin yóò gbé rí i,’ wò ó, o ti sọ fún yin.” Àwọn obìnrin náà sáré kúrò ní ibojì pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ayọ̀ ńlá. Wọ́n sáré láti sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn nípa ìròyìn tí angẹli náà fi fún wọn. Bí wọ́n ti ń sáré lọ lójijì Jesu pàdé wọn. Ó wí pé, “Àlàáfíà” Wọ́n wólẹ̀ níwájú rẹ̀. Wọ́n gbá a ní ẹsẹ̀ mú. Wọ́n sì foríbalẹ̀ fún un. Nígbà náà, Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù. Ẹ lọ sọ fún àwọn arákùnrin mi pé, ‘Kí wọ́n lọ tààrà sí Galili níbẹ̀ ni wọn yóò gbé rí mi.’ ” Bí àwọn obìnrin náà sì ti ń lọ sí ìlú, díẹ̀ nínú àwọn olùṣọ́ tí wọ́n ti ń ṣọ́ ibojì lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà. Wọ́n sì pe ìpàdé àwọn àgbàgbà Júù. Wọ́n sì fohùn ṣọ̀kan láti fi owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fún àwọn olùṣọ́. Wọ́n wí pé, “Ẹ sọ fún àwọn ènìyàn pé, ‘Gbogbo yín sùn nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu wá lóru láti jí òkú rẹ̀.’ Bí Pilatu bá sì mọ̀ nípa rẹ̀, àwa yóò ṣe àlàyé tí yóò tẹ́ ẹ lọ́rùn fún un, tí ọ̀rọ̀ náà kì yóò fi lè kó bá yín.” Àwọn olùṣọ́ sì gba owó náà. Wọ́n sì ṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti darí wọn. Ìtàn yìí sì tàn ká kíákíá láàrín àwọn Júù. Wọ́n sì gba ìtàn náà gbọ́ títí di òní yìí. Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mọ́kànlá náà lọ sí Galili ní orí òkè níbi tí Jesu sọ pé wọn yóò ti rí òun. Nígbà tí wọ́n sì rí i, wọ́n foríbalẹ̀ fún un. Ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú wọn ṣe iyèméjì bóyá Jesu ni tàbí òun kọ́. Nígbà náà ni Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Gbogbo agbára ni ọ̀run àti ní ayé ni a ti fi fún mi. Nítorí náà, Ẹ lọ, ẹ sọ wọ́n di ọmọ-ẹ̀yìn orílẹ̀-èdè gbogbo, ẹ máa bamitiisi wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ kọ́ wọn láti máa kíyèsi ohun gbogbo èyí tí mo ti pàṣẹ fún yín. Nítorí èmi wà pẹ̀lú yín ní ìgbà gbogbo títí tí ó fi dé òpin ayé.”