Mat 27:15-31
Mat 27:15-31 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigba ajọ na, Bãlẹ a mã dá ondè kan silẹ fun awọn enia, ẹnikẹni ti nwọn ba fẹ. Nwọn si ni ondè buburu kan lakoko na, ti a npè ni Barabba. Nitorina nigbati nwọn pejọ, Pilatu wi fun wọn pe, Tali ẹnyin nfẹ ki emi dá silẹ fun nyin? Barabba, tabi Jesu ti a npè ni Kristi? O sá ti mọ̀ pe nitori ilara ni nwọn ṣe fi i le on lọwọ. Nigbati o si joko lori itẹ́ idajọ, aya rẹ̀ ransẹ si i, wipe, Máṣe li ọwọ́ ninu ọ̀ran ọkunrin olododo nì: nitori ìyà ohun pipọ ni mo jẹ li oju àlá loni nitori rẹ̀. Ṣugbọn awọn olori alufa, ati awọn agbàgba yi ijọ enia li ọkàn pada lati bère Barabba, ki nwọn si pa Jesu. Bãlẹ dahùn o si wi fun wọn pe, Ninu awọn mejeji, ewo li ẹnyin fẹ ki emi dá silẹ fun nyin? Nwọn wipe, Barabba. Pilatu bi wọn pe, Kili emi o ha ṣe si Jesu ẹniti a npè ni Kristi? Gbogbo wọn wipe, Ki a kàn a mọ agbelebu. Bãlẹ si bère wipe, Ẽṣe, buburu kili o ṣe? Ṣugbọn nwọn kigbe soke si i pe, Ki a kàn a mọ agbelebu. Nigbati Pilatu ri pe, on ko le bori li ohunkohun, ṣugbọn pe a kuku sọ gbogbo rẹ̀ di ariwo, o bu omi, o si wẹ̀ ọwọ́ rẹ̀ li oju ijọ, o wipe, Ọrùn mi mọ́ kuro ninu ẹ̀jẹ enia olõtọ yi: ẹ mã bojuto o. Nigbana ni gbogbo enia dahùn, nwọn si wipe, Ki ẹjẹ rẹ̀ wà li ori wa, ati li ori awọn ọmọ wa. Nigbana li o da Barabba silẹ fun wọn. Ṣugbọn o nà Jesu, o si fi i le wọn lọwọ lati kàn a mọ agbelebu. Nigbana li awọn ọmọ-ogun Bãlẹ mu Jesu lọ sinu gbọ̀ngan idajọ, nwọn si kó gbogbo ẹgbẹ ọmọ-ogun tì i. Nwọn si bọ́ aṣọ rẹ̀, nwọn si wọ̀ ọ li aṣọ ododó. Nwọn si hun ade ẹgún, nwọn si fi dé e li ori, nwọn si fi ọpá iyè le e li ọwọ́ ọtún: nwọn si kunlẹ niwaju rẹ̀, nwọn si fi i ṣẹsin, wipe, Kabiyesi, ọba awọn Ju. Nwọn si tutọ́ si i lara, nwọn si gbà ọpá iyè na, nwọn si fi lù u li ori. Nigbati nwọn fi i ṣẹsin tan, nwọn bọ aṣọ na kuro lara rẹ̀, nwọn si fi aṣọ rẹ̀ wọ̀ ọ, nwọn si fa a lọ lati kàn a mọ agbelebu.
Mat 27:15-31 Yoruba Bible (YCE)
Gẹ́gẹ́ bí àṣà, ní àkókò àjọ̀dún, gomina a máa dá ẹlẹ́wọ̀n kan sílẹ̀ fún àwọn eniyan, ẹnikẹ́ni tí wọn bá fẹ́. Ní àkókó náà, ẹlẹ́wọ̀n olókìkí kan wà tí ó ń jẹ́ Jesu Baraba. Nígbà tí àwọn Juu pésẹ̀, Pilatu bi wọ́n pé, “Ta ni kí n dá sílẹ̀ fun yín, Jesu Baraba ni tabi Jesu tí ó ń jẹ́ Mesaya?” Pilatu ti mọ̀ pé nítorí ìlara ni wọ́n fi mú un wá sọ́dọ̀ òun. Nígbà tí Pilatu jókòó lórí pèpéle ìdájọ́, iyawo rẹ̀ ranṣẹ sí i, ó ní, “Má ṣe lọ́wọ́ ninu ọ̀ràn ọkunrin olódodo yìí. Nítorí pé mọ́jú òní, ojú mi rí nǹkan lójú àlá nípa rẹ̀.” Àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbà ti rọ àwọn eniyan láti bèèrè fún Baraba, kí wọ́n pa Jesu. Gomina bi wọ́n pé, “Ta ni ninu àwọn meji yìí ni ẹ fẹ́ kí n dá sílẹ̀ fun yín?” Wọ́n sọ pé, “Baraba ni.” Pilatu wá bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ fẹ́ kí n ṣe sí Jesu tí ó ń jẹ́ Mesaya?” Gbogbo wọn dáhùn pé, “Kàn án mọ́ agbelebu.” Pilatu bi wọ́n pé, “Ohun burúkú wo ni ó ṣe?” Ṣugbọn wọ́n túbọ̀ kígbe pé, “Kàn án mọ́ agbelebu.” Nígbà tí Pilatu rí i pé òun kò lè yí wọn lọ́kàn pada, ati pé rògbòdìyàn fẹ́ bẹ́ sílẹ̀, ó mú omi, ó fọ ọwọ́ rẹ̀ níwájú wọn. Ó ní, “N kò lọ́wọ́ ninu ikú ọkunrin yìí. Ẹ̀yin ni kí ẹ mójútó ọ̀ràn náà.” Gbogbo àwọn eniyan náà dáhùn pé, “Kí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wà lórí àwa ati àwọn ọmọ wa!” Pilatu bá dá Baraba sílẹ̀ fún wọn. Lẹ́yìn tí ó ti pàṣẹ pé kí wọ́n na Jesu ní pàṣán, ó fi í lé wọn lọ́wọ́ láti kàn mọ̀ agbelebu. Àwọn ọmọ-ogun gomina bá mú Jesu lọ sí ibùdó wọn, gbogbo wọn bá péjọ lé e lórí. Wọ́n bọ́ ẹ̀wù rẹ̀, wọ́n wá fi aṣọ àlàárì bò ó lára. Wọ́n fi ẹ̀gún hun adé, wọ́n fi dé e lórí. Wọ́n fi ọ̀pá sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀. Wọ́n wá ń kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́; wọ́n ń wí pé, “Kabiyesi, ọba àwọn Juu.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń tutọ́ sí i lára. Wọ́n mú ọ̀pá, wọ́n ń kán an mọ́ ọn lórí. Nígbà tí wọn ti fi ṣe ẹlẹ́yà tẹ́rùn, wọ́n bọ́ aṣọ àlàárì náà kúrò lára rẹ̀, wọ́n fi tirẹ̀ wọ̀ ọ́. Wọ́n bá mú un lọ láti kàn án mọ́ agbelebu.
Mat 27:15-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó jẹ́ àṣà gómìnà láti dá ọ̀kan nínú àwọn ẹlẹ́wọ̀n Júù sílẹ̀ lọ́dọọdún, ní àsìkò àjọ̀dún ìrékọjá. Ẹnikẹ́ni tí àwọn ènìyàn bá ti fẹ́ ni. Ní àsìkò náà ọ̀daràn paraku kan wà nínú ẹ̀wọ̀n tí à ń pè Jesu Baraba. Bí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti péjọ síwájú ilé Pilatu lówúrọ̀ ọjọ́ náà, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ta ni ẹ̀yin ń fẹ́ kí n dá sílẹ̀ fún yín, Baraba tàbí Jesu, ẹni tí ń jẹ́ Kristi?” Òun ti mọ̀ pé nítorí ìlara ni wọn fi fà á lé òun lọ́wọ́. Bí Pilatu sì ti ṣe jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́ rẹ̀, ìyàwó rẹ̀ ránṣẹ́ sí i pé, “Má ṣe ní ohun kankan ṣe pẹ̀lú ọkùnrin aláìṣẹ̀ náà. Nítorí mo jìyà ohun púpọ̀ lójú àlá mi lónìí nítorí rẹ̀.” Ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù rọ àwọn ènìyàn, láti béèrè kí a dá Baraba sílẹ̀, kí a sì béèrè ikú fún Jesu. Nígbà tí Pilatu sì tún béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èwo nínú àwọn méjèèjì yìí ni ẹ̀ ń fẹ́ kí n dá sílẹ̀ fún yín?” Àwọn ènìyàn sì kígbe padà pé, “Baraba!” Pilatu béèrè pé, “Kí ni kí èmi ṣe sí Jesu ẹni ti a ń pè ní Kristi?” Gbogbo wọn sì tún kígbe pé, “Kàn án mọ́ àgbélébùú!” Pilatu sì béèrè pé, “Nítorí kí ni? Kí ló ṣe tí ó burú?” Wọ́n kígbe sókè pé, “Kàn án mọ́ àgbélébùú! Kàn án mọ́ àgbélébùú!” Nígbà tí Pilatu sì rí i pé òun kò tún rí nǹkan kan ṣe mọ́, àti wí pé rògbòdìyàn ti ń bẹ̀rẹ̀, ó béèrè omi, ó sì wẹ ọwọ́ rẹ̀ níwájú ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó wí pé, “Ọrùn mí mọ́ nípa ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yìí. Ẹ̀yin fúnrayín, ẹ bojútó o!” Gbogbo àgbájọ náà sì ké pé, “Kí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wà lórí wa, àti ní orí àwọn ọmọ wa!” Nígbà náà ni Pilatu dá Baraba sílẹ̀ fún wọn. Lẹ́yìn tí òun ti na Jesu tán, ó fi í lé wọn lọ́wọ́ láti mú un lọ kàn mọ́ àgbélébùú. Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ogun gómìnà mú Jesu lọ sí gbọ̀ngàn ìdájọ́ wọ́n sì kó gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ-ogun tì í Wọ́n tú Jesu sì ìhòhò, wọ́n sì wọ̀ ọ́ ní aṣọ òdòdó, Wọ́n sì hun adé ẹ̀gún. Wọ́n sì fi dé e lórí. Wọ́n sì fi ọ̀pá sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá ọba. Wọ́n sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n fi í ṣe ẹlẹ́yà pé, “Kábíyèsí, ọba àwọn Júù!” Wọ́n sì tu itọ́ sí i lójú àti ara, wọ́n gba ọ̀pá wọ́n sì nà án lórí. Nígbà tí wọ́n fi ṣẹ̀sín tán, wọ́n bọ́ aṣọ ara rẹ̀. Wọ́n tún fi aṣọ tirẹ̀ wọ̀ ọ́. Wọ́n sì mú un jáde láti kàn án mọ́ àgbélébùú.