Mat 27:11-60
Mat 27:11-60 Bibeli Mimọ (YBCV)
Jesu si duro niwaju Bãlẹ: Bãlẹ si bi i lẽre, wipe, Iwọ ha li Ọba awọn Ju? Jesu si wi fun u pe, Iwọ wi i. Nigbati a si nkà si i lọrùn lati ọwọ́ awọn olori alufa, ati awọn àgbãgba wá, on kò dahùn kan. Nigbana ni Pilatu wi fun u pe, Iwọ ko gbọ́ ọ̀pọ ohun ti nwọn njẹri si ọ? On kò si dá a ni gbolohun kan; tobẹ̃ ti ẹnu yà Bãlẹ gidigidi. Nigba ajọ na, Bãlẹ a mã dá ondè kan silẹ fun awọn enia, ẹnikẹni ti nwọn ba fẹ. Nwọn si ni ondè buburu kan lakoko na, ti a npè ni Barabba. Nitorina nigbati nwọn pejọ, Pilatu wi fun wọn pe, Tali ẹnyin nfẹ ki emi dá silẹ fun nyin? Barabba, tabi Jesu ti a npè ni Kristi? O sá ti mọ̀ pe nitori ilara ni nwọn ṣe fi i le on lọwọ. Nigbati o si joko lori itẹ́ idajọ, aya rẹ̀ ransẹ si i, wipe, Máṣe li ọwọ́ ninu ọ̀ran ọkunrin olododo nì: nitori ìyà ohun pipọ ni mo jẹ li oju àlá loni nitori rẹ̀. Ṣugbọn awọn olori alufa, ati awọn agbàgba yi ijọ enia li ọkàn pada lati bère Barabba, ki nwọn si pa Jesu. Bãlẹ dahùn o si wi fun wọn pe, Ninu awọn mejeji, ewo li ẹnyin fẹ ki emi dá silẹ fun nyin? Nwọn wipe, Barabba. Pilatu bi wọn pe, Kili emi o ha ṣe si Jesu ẹniti a npè ni Kristi? Gbogbo wọn wipe, Ki a kàn a mọ agbelebu. Bãlẹ si bère wipe, Ẽṣe, buburu kili o ṣe? Ṣugbọn nwọn kigbe soke si i pe, Ki a kàn a mọ agbelebu. Nigbati Pilatu ri pe, on ko le bori li ohunkohun, ṣugbọn pe a kuku sọ gbogbo rẹ̀ di ariwo, o bu omi, o si wẹ̀ ọwọ́ rẹ̀ li oju ijọ, o wipe, Ọrùn mi mọ́ kuro ninu ẹ̀jẹ enia olõtọ yi: ẹ mã bojuto o. Nigbana ni gbogbo enia dahùn, nwọn si wipe, Ki ẹjẹ rẹ̀ wà li ori wa, ati li ori awọn ọmọ wa. Nigbana li o da Barabba silẹ fun wọn. Ṣugbọn o nà Jesu, o si fi i le wọn lọwọ lati kàn a mọ agbelebu. Nigbana li awọn ọmọ-ogun Bãlẹ mu Jesu lọ sinu gbọ̀ngan idajọ, nwọn si kó gbogbo ẹgbẹ ọmọ-ogun tì i. Nwọn si bọ́ aṣọ rẹ̀, nwọn si wọ̀ ọ li aṣọ ododó. Nwọn si hun ade ẹgún, nwọn si fi dé e li ori, nwọn si fi ọpá iyè le e li ọwọ́ ọtún: nwọn si kunlẹ niwaju rẹ̀, nwọn si fi i ṣẹsin, wipe, Kabiyesi, ọba awọn Ju. Nwọn si tutọ́ si i lara, nwọn si gbà ọpá iyè na, nwọn si fi lù u li ori. Nigbati nwọn fi i ṣẹsin tan, nwọn bọ aṣọ na kuro lara rẹ̀, nwọn si fi aṣọ rẹ̀ wọ̀ ọ, nwọn si fa a lọ lati kàn a mọ agbelebu. Bi nwọn si ti jade, nwọn ri ọkunrin kan ara Kirene, ti njẹ Simoni: on ni nwọn fi agbara mu lati rù agbelebu rẹ̀. Nigbati nwọn si de ibi ti a npè ni Golgota, eyini ni, Ibi agbari, Nwọn fi ọti kikan ti a dàpọ mọ orõrò fun u lati mu: nigbati o si tọ́ ọ wò, o kọ̀ lati mu u. Nigbati nwọn si kàn a mọ agbelebu, nwọn pín aṣọ rẹ̀, nwọn si ṣẹ gègé le e: ki eyi ti wolĩ wi ba le ṣẹ, pe, Nwọn pín aṣọ mi fun ara wọn aṣọ ileke mi ni nwọn ṣẹ gègé le. Nwọn si joko, nwọn nṣọ ọ nibẹ̀. Nwọn si fi ọ̀ran ifisùn rẹ̀ ti a kọ si igberi rẹ̀, EYI NI JESU ỌBA AWỌN JU. Nigbana li a kàn awọn olè meji mọ agbelebu pẹlu rẹ̀, ọkan li ọwọ́ ọtún, ati ekeji li ọwọ́ òsi. Awọn ti nkọja lọ si nfi ṣe ẹlẹyà, nwọn si nmì ori wọn, Wipe, Iwọ ti o wó tẹmpili, ti o si kọ́ ọ ni ijọ mẹta, gbà ara rẹ là. Bi iwọ ba ṣe Ọmọ Ọlọrun, sọkalẹ lati ori agbelebu wá. Gẹgẹ bẹ̃li awọn olori alufa pẹlu awọn akọwe, ati awọn àgbãgba nfi ṣe ẹlẹya, wipe, O gbà awọn ẹlomiran là; ara rẹ̀ ni kò le gbalà. Ọba Israeli sa ni iṣe, jẹ ki o sọkalẹ lati ori agbelebu wá nisisiyi, awa o si gbà a gbọ́. O gbẹkẹle Ọlọrun; jẹ ki o gbà a là nisisiyi, bi o ba fẹran rẹ̀: o sá wipe, Ọmọ Ọlọrun li emi. Awọn olè ti a kàn mọ agbelebu pẹlu rẹ̀ si nfi eyi na gún u loju bakanna. Lati wakati kẹfa, ni òkunkun ṣú bò gbogbo ilẹ titi o fi di wakati kẹsan. Niwọn wakati kẹsan ni Jesu si kigbe li ohùn rara wipe, Eli, Eli, lama sabaktani? eyini ni, Ọlọrun mi, Ọlọrun mi, ẽṣe ti iwọ fi kọ̀ mi silẹ? Nigbati awọn kan ninu awọn ti o duro nibẹ̀ gbọ́ eyi, nwọn wipe, ọkunrin yi npè Elijah. Lojukanna ọkan ninu wọn si sare, o mu kànìnkànìn, o tẹ̀ ẹ bọ̀ inu ọti kikan, o fi le ori ọpá iyè, o si fifun u mu. Awọn iyokù wipe, Ẹ fi silẹ̀, ẹ jẹ ki a mã wò bi Elijah yio wá gbà a là. Jesu si tún kigbe li ohùn rara, o jọwọ ẹmí rẹ̀ lọwọ. Si wo o, aṣọ ikele tẹmpili si ya si meji lati oke de isalẹ; ilẹ si mì titi, awọn apata si sán; Awọn isà okú si ṣí silẹ; ọ̀pọ okú awọn ẹni mimọ́ ti o ti sùn si jinde, Nwọn ti inu isà okú wọn jade lẹhin ajinde rẹ̀, nwọn si wá si ilu mimọ́, nwọn si farahàn ọ̀pọlọpọ enia. Nigbati balogun ọrún, ati awọn ti o wà pẹlu rẹ̀, ti nwọn nṣọ́ Jesu, ri isẹlẹ na, ati ohun wọnni ti ó ṣẹ̀, èru ba wọn gidigidi, nwọn wipe, Lõtọ Ọmọ Ọlọrun li eyi iṣe. Awọn obinrin pipọ, li o wà nibẹ̀, ti nwọn ńwòran lati òkẽrè, awọn ti o ba Jesu ti Galili wá, ti nwọn si nṣe iranṣẹ fun u: Ninu awọn ẹniti Maria Magdalene wà, ati Maria iya Jakọbu ati Jose, ati iya awọn ọmọ Sebede. Nigbati alẹ si lẹ, ọkunrin ọlọrọ̀ kan ti Arimatea wá, ti a npè ni Josefu, ẹniti on tikararẹ̀ iṣe ọmọ-ẹhin Jesu pẹlu: O tọ̀ Pilatu lọ, o si tọrọ okú Jesu. Nigbana ni Pilatu paṣẹ ki a fi okú na fun u. Josefu si gbé okú na, o si fi aṣọ ọ̀gbọ mimọ́ dì i, O si tẹ́ ẹ sinu iboji titun ti on tikararẹ̀, eyi ti a gbẹ ninu apata: o si yi okuta nla di ẹnu-ọ̀na ibojì na, o si lọ.
Mat 27:11-60 Yoruba Bible (YCE)
Jesu bá dúró siwaju gomina. Gomina bi í pé, “Ìwọ ni ọba àwọn Juu bí?” Jesu ní, “O ti fi ẹnu ara rẹ sọ ọ́.” Ṣugbọn bí àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbà ti ń fi ẹ̀sùn kàn án tó, kò fèsì rárá. Nígbà náà ni Pilatu sọ fún un pé, “O kò gbọ́ irú ẹ̀sùn tí wọn ń fi kàn ọ́ ni?” Ṣugbọn Jesu kò dá a lóhùn gbolohun kan ṣoṣo, tí ó fi jẹ́ pé ẹnu ya gomina pupọ. Gẹ́gẹ́ bí àṣà, ní àkókò àjọ̀dún, gomina a máa dá ẹlẹ́wọ̀n kan sílẹ̀ fún àwọn eniyan, ẹnikẹ́ni tí wọn bá fẹ́. Ní àkókó náà, ẹlẹ́wọ̀n olókìkí kan wà tí ó ń jẹ́ Jesu Baraba. Nígbà tí àwọn Juu pésẹ̀, Pilatu bi wọ́n pé, “Ta ni kí n dá sílẹ̀ fun yín, Jesu Baraba ni tabi Jesu tí ó ń jẹ́ Mesaya?” Pilatu ti mọ̀ pé nítorí ìlara ni wọ́n fi mú un wá sọ́dọ̀ òun. Nígbà tí Pilatu jókòó lórí pèpéle ìdájọ́, iyawo rẹ̀ ranṣẹ sí i, ó ní, “Má ṣe lọ́wọ́ ninu ọ̀ràn ọkunrin olódodo yìí. Nítorí pé mọ́jú òní, ojú mi rí nǹkan lójú àlá nípa rẹ̀.” Àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbà ti rọ àwọn eniyan láti bèèrè fún Baraba, kí wọ́n pa Jesu. Gomina bi wọ́n pé, “Ta ni ninu àwọn meji yìí ni ẹ fẹ́ kí n dá sílẹ̀ fun yín?” Wọ́n sọ pé, “Baraba ni.” Pilatu wá bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ fẹ́ kí n ṣe sí Jesu tí ó ń jẹ́ Mesaya?” Gbogbo wọn dáhùn pé, “Kàn án mọ́ agbelebu.” Pilatu bi wọ́n pé, “Ohun burúkú wo ni ó ṣe?” Ṣugbọn wọ́n túbọ̀ kígbe pé, “Kàn án mọ́ agbelebu.” Nígbà tí Pilatu rí i pé òun kò lè yí wọn lọ́kàn pada, ati pé rògbòdìyàn fẹ́ bẹ́ sílẹ̀, ó mú omi, ó fọ ọwọ́ rẹ̀ níwájú wọn. Ó ní, “N kò lọ́wọ́ ninu ikú ọkunrin yìí. Ẹ̀yin ni kí ẹ mójútó ọ̀ràn náà.” Gbogbo àwọn eniyan náà dáhùn pé, “Kí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wà lórí àwa ati àwọn ọmọ wa!” Pilatu bá dá Baraba sílẹ̀ fún wọn. Lẹ́yìn tí ó ti pàṣẹ pé kí wọ́n na Jesu ní pàṣán, ó fi í lé wọn lọ́wọ́ láti kàn mọ̀ agbelebu. Àwọn ọmọ-ogun gomina bá mú Jesu lọ sí ibùdó wọn, gbogbo wọn bá péjọ lé e lórí. Wọ́n bọ́ ẹ̀wù rẹ̀, wọ́n wá fi aṣọ àlàárì bò ó lára. Wọ́n fi ẹ̀gún hun adé, wọ́n fi dé e lórí. Wọ́n fi ọ̀pá sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀. Wọ́n wá ń kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́; wọ́n ń wí pé, “Kabiyesi, ọba àwọn Juu.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń tutọ́ sí i lára. Wọ́n mú ọ̀pá, wọ́n ń kán an mọ́ ọn lórí. Nígbà tí wọn ti fi ṣe ẹlẹ́yà tẹ́rùn, wọ́n bọ́ aṣọ àlàárì náà kúrò lára rẹ̀, wọ́n fi tirẹ̀ wọ̀ ọ́. Wọ́n bá mú un lọ láti kàn án mọ́ agbelebu. Nígbà tí wọn ń jáde lọ, wọ́n rí ọkunrin kan ará Kirene tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Simoni. Wọ́n bá fi ipá mú un láti ru agbelebu Jesu. Nígbà tí wọ́n dé ibi tí wọn ń pè ní Gọlgọta (ìtumọ̀ èyí tíí ṣe “Ibi Agbárí”), wọ́n fún un ní ọtí kíkorò mu. Nígbà tí ó tọ́ ọ wò, ó kọ̀, kò mu ún. Nígbà tí wọ́n kàn án mọ́ agbelebu tán, wọ́n pín aṣọ rẹ̀ mọ́ ara wọn lọ́wọ́, wọ́n ṣẹ́ gègé láti mọ èyí tí yóo kan ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn. Wọ́n bá jókòó níbẹ̀, wọ́n ń ṣọ́ ọ. Wọ́n fi àkọlé kan kọ́ sí òkè orí rẹ̀, wọ́n kọ ẹ̀sùn tí a fi kàn án sibẹ pé, “Eléyìí ni Jesu ọba àwọn Juu.” Wọ́n tún kan àwọn ọlọ́ṣà meji mọ́ agbelebu pẹlu rẹ̀, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, ekeji ní ọwọ́ òsì rẹ̀. Àwọn tí ó ń kọjá lọ ń sọ ìsọkúsọ sí i. Wọ́n ń já apá mọ́nú, wọ́n ń sọ pé, “Ìwọ tí yóo wó Tẹmpili, tí yóo tún un kọ́ ní ọjọ́ mẹta, gba ara rẹ là. Bí Ọmọ Ọlọrun bá ni ọ́, sọ̀kalẹ̀ kúrò lórí agbelebu.” Bákan náà ni àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin ati àwọn àgbà, àwọn náà ń fi í ṣe ẹlẹ́yà. Wọ́n ń sọ pé, “Àwọn ẹlòmíràn ni ó rí gbà là, kò lè gba ara rẹ̀ là. Ṣé ọba Israẹli ni! Kí ó sọ̀kalẹ̀ nisinsinyii láti orí agbelebu, a óo gbà á gbọ́. Ṣé ó gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun ni! Kí Ọlọrun gbà á sílẹ̀ nisinsinyii bí ó bá fẹ́ ẹ! Ṣebí ó sọ pé ọmọ Ọlọrun ni òun.” Bákan náà ni àwọn ọlọ́ṣà tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu pẹlu rẹ̀ fi ń ṣe ẹlẹ́yà. Láti agogo mejila ọ̀sán ni òkùnkùn ti bo gbogbo ilẹ̀ títí di agogo mẹta ọ̀sán. Nígbà tí ó tó nǹkan bí agogo mẹta ọ̀sán, Jesu kígbe ní ohùn rara pé, “Eli, Eli, lema sabakitani?” Ìtumọ̀ èyí ni, “Ọlọrun mi! Ọlọrun mi! Kí ló dé tí o fi kọ̀ mí sílẹ̀?” Nígbà tí àwọn kan tí ó dúró níbẹ̀ gbọ́, wọ́n ní, “Ọkunrin yìí ń pe Elija.” Lẹsẹkẹsẹ ọ̀kan ninu wọn sáré, ó ti nǹkankan bíi kànìnkànìn bọ inú ọtí kíkan, ó fi sórí ọ̀pá láti fi fún un mu. Ṣugbọn àwọn yòókù ń sọ pé, “Fi í sílẹ̀! Jẹ́ kí a wò bí Elija yóo wá gbà á là.” Jesu bá tún kígbe tòò, ó mí kanlẹ̀, ó bá dákẹ́. Aṣọ ìkélé tí ó wà ninu Tẹmpili ya sí meji láti òkè dé ilẹ̀. Ilẹ̀ mì tìtì. Àwọn òkè sán. Òkúta ẹnu ibojì ṣí, a sì jí ọ̀pọ̀ òkú àwọn olódodo dìde. Wọ́n jáde kúrò ninu ibojì lẹ́yìn tí Jesu ti jí dìde, wọ́n wọ Jerusalẹmu lọ, ọpọlọpọ eniyan ni ó rí wọn. Nígbà tí ọ̀gágun ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀ tí wọn ń ṣọ́ Jesu rí ilẹ̀ tí ó mì ati gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ẹ̀rù bà wọ́n pupọ. Wọ́n ní, “Nítòótọ́ Ọmọ Ọlọrun ni ọkunrin yìí.” Ọ̀pọ̀ àwọn obinrin wà níbẹ̀ tí wọ́n dúró ní òkèèrè réré, tí wọn ń wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Àwọn ni wọ́n tí ń tẹ̀lé Jesu láti Galili, tí wọn ń ṣe iranṣẹ fún un. Maria Magidaleni wà lára wọn, ati Maria ìyá Jakọbu ati ti Josẹfu ati ìyá àwọn ọmọ Sebede. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, ọkunrin ọlọ́rọ̀ kan, ará Arimatia tí ó ń jẹ́ Josẹfu wá. Òun náà jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Jesu. Ó tọ Pilatu lọ láti bèèrè òkú Jesu. Pilatu bá pàṣẹ pé kí wọ́n fún un. Nígbà tí Josẹfu ti gba òkú náà, ó fi aṣọ funfun tí ó mọ́ wé e. Ó tẹ́ ẹ sí inú ibojì rẹ̀ titun tí òun tìkalárarẹ̀ ti gbẹ́ sí inú àpáta. Ó yí òkúta ńlá kan dí ẹnu ọ̀nà ibojì náà. Ó bá kúrò níbẹ̀.
Mat 27:11-60 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni Jesu dúró níwájú baálẹ̀ láti gba ìdájọ́. Baálẹ̀ sì béèrè pé, “Ṣe ìwọ ni ọba àwọn Júù?” Jesu dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, nítorí tí ìwọ wí i.” Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù fi gbogbo ẹ̀sùn wọn kàn án, Jesu kò dáhùn kan. Nígbà náà ni Pilatu, béèrè lọ́wọ́ Jesu pé, “Àbí ìwọ kò gbọ́ ẹ̀rí tí wọn ń wí nípa rẹ ni?” Jesu kò sì tún dáhùn kan. Èyí sì ya baálẹ̀ lẹ́nu. Ó jẹ́ àṣà gómìnà láti dá ọ̀kan nínú àwọn ẹlẹ́wọ̀n Júù sílẹ̀ lọ́dọọdún, ní àsìkò àjọ̀dún ìrékọjá. Ẹnikẹ́ni tí àwọn ènìyàn bá ti fẹ́ ni. Ní àsìkò náà ọ̀daràn paraku kan wà nínú ẹ̀wọ̀n tí à ń pè Jesu Baraba. Bí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti péjọ síwájú ilé Pilatu lówúrọ̀ ọjọ́ náà, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ta ni ẹ̀yin ń fẹ́ kí n dá sílẹ̀ fún yín, Baraba tàbí Jesu, ẹni tí ń jẹ́ Kristi?” Òun ti mọ̀ pé nítorí ìlara ni wọn fi fà á lé òun lọ́wọ́. Bí Pilatu sì ti ṣe jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́ rẹ̀, ìyàwó rẹ̀ ránṣẹ́ sí i pé, “Má ṣe ní ohun kankan ṣe pẹ̀lú ọkùnrin aláìṣẹ̀ náà. Nítorí mo jìyà ohun púpọ̀ lójú àlá mi lónìí nítorí rẹ̀.” Ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù rọ àwọn ènìyàn, láti béèrè kí a dá Baraba sílẹ̀, kí a sì béèrè ikú fún Jesu. Nígbà tí Pilatu sì tún béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èwo nínú àwọn méjèèjì yìí ni ẹ̀ ń fẹ́ kí n dá sílẹ̀ fún yín?” Àwọn ènìyàn sì kígbe padà pé, “Baraba!” Pilatu béèrè pé, “Kí ni kí èmi ṣe sí Jesu ẹni ti a ń pè ní Kristi?” Gbogbo wọn sì tún kígbe pé, “Kàn án mọ́ àgbélébùú!” Pilatu sì béèrè pé, “Nítorí kí ni? Kí ló ṣe tí ó burú?” Wọ́n kígbe sókè pé, “Kàn án mọ́ àgbélébùú! Kàn án mọ́ àgbélébùú!” Nígbà tí Pilatu sì rí i pé òun kò tún rí nǹkan kan ṣe mọ́, àti wí pé rògbòdìyàn ti ń bẹ̀rẹ̀, ó béèrè omi, ó sì wẹ ọwọ́ rẹ̀ níwájú ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó wí pé, “Ọrùn mí mọ́ nípa ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yìí. Ẹ̀yin fúnrayín, ẹ bojútó o!” Gbogbo àgbájọ náà sì ké pé, “Kí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wà lórí wa, àti ní orí àwọn ọmọ wa!” Nígbà náà ni Pilatu dá Baraba sílẹ̀ fún wọn. Lẹ́yìn tí òun ti na Jesu tán, ó fi í lé wọn lọ́wọ́ láti mú un lọ kàn mọ́ àgbélébùú. Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ogun gómìnà mú Jesu lọ sí gbọ̀ngàn ìdájọ́ wọ́n sì kó gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ-ogun tì í Wọ́n tú Jesu sì ìhòhò, wọ́n sì wọ̀ ọ́ ní aṣọ òdòdó, Wọ́n sì hun adé ẹ̀gún. Wọ́n sì fi dé e lórí. Wọ́n sì fi ọ̀pá sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá ọba. Wọ́n sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n fi í ṣe ẹlẹ́yà pé, “Kábíyèsí, ọba àwọn Júù!” Wọ́n sì tu itọ́ sí i lójú àti ara, wọ́n gba ọ̀pá wọ́n sì nà án lórí. Nígbà tí wọ́n fi ṣẹ̀sín tán, wọ́n bọ́ aṣọ ara rẹ̀. Wọ́n tún fi aṣọ tirẹ̀ wọ̀ ọ́. Wọ́n sì mú un jáde láti kàn án mọ́ àgbélébùú. Bí wọ́n sì ti ń jáde, wọ́n rí ọkùnrin kan ará Kirene tí à ń pè ní Simoni. Wọ́n sì mú ọkùnrin náà ní túláàsì láti ru àgbélébùú Jesu. Wọ́n sì jáde lọ sí àdúgbò kan tí à ń pè ní Gọlgọta, (èyí tí í ṣe Ibi Agbárí.) Níbẹ̀ ni wọn ti fún un ni ọtí wáìnì tí ó ní egbòogi nínú láti mu. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó tọ́ ọ wò, ó kọ̀ láti mu ún. Lẹ́yìn tí wọ́n sì ti kàn án mọ́ àgbélébùú, wọ́n dìbò láti pín aṣọ rẹ̀ láàrín ara wọn. Nígbà náà ni wọ́n jókòó yí i ká. Wọ́n ń ṣọ́ ọ níbẹ̀. Ní òkè orí rẹ̀, wọ́n kọ ohun kan tí ó kà báyìí pé: “èyí ni jesu, ọba àwọn júù” síbẹ̀. Wọ́n kan àwọn olè méjì pẹ̀lú rẹ̀ ní òwúrọ̀ náà. Ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, àti èkejì ní ọwọ́ òsì rẹ̀. Àwọn tí ń kọjá lọ sì ń bú u. Wọ́n sì ń mi orí wọn pé: “Ìwọ tí yóò wó tẹmpili, ìwọ tí yóò sì tún un mọ ní ọjọ́ kẹta. Bí ó bá jẹ́ pé Ọmọ Ọlọ́run ni ìwọ, sọ̀kalẹ̀ láti orí igi àgbélébùú, kí ó sì gba ara rẹ là!” Bákan náà àwọn olórí àlùfáà pẹ̀lú àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn àgbàgbà Júù sì fi í ṣe ẹlẹ́yà. Wọ́n kẹ́gàn rẹ̀ pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là, kò sí lè gba ara rẹ̀. Ìwọ ọba àwọn Israẹli? Sọ̀kalẹ̀ láti orí àgbélébùú nísinsin yìí, àwa yóò sì gbà ọ́ gbọ́. Ó gba Ọlọ́run gbọ́, jẹ́ kí Ọlọ́run gbà á là ní ìsinsin yìí tí òun bá fẹ́ ẹ. Ǹjẹ́ òun kò wí pé, èmi ni Ọmọ Ọlọ́run?” Bákan náà, àwọn olè tí a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀ fi í ṣe ẹlẹ́yà. Láti wákàtí kẹfà ni òkùnkùn fi ṣú bo gbogbo ilẹ̀ títí dé wákàtí kẹsànán ọjọ́ Níwọ̀n wákàtí kẹsànán ní Jesu sì kígbe ní ohùn rara wí pé, “Eli, Eli, Lama Sabakitani” (ní èdè Heberu). Ìtumọ̀ èyí tí í ṣe, “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀?” Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò yé díẹ̀ nínú àwọn ẹni tí ń wòran, nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, Wọ́n wí pé ọkùnrin yìí ń pe Elijah. Lẹ́sẹ̀kan náà, ọ̀kan nínú wọn sáré, ó mú kànìnkànìn, ó tẹ̀ ẹ́ bọ inú ọtí kíkan. Ó fi lé orí ọ̀pá, ó gbé e sókè láti fi fún un mu. Ṣùgbọ́n àwọn ìyókù wí pé, “Ẹ fi í sílẹ̀. Ẹ jẹ́ kí a wò ó bóyá Elijah yóò sọ̀kalẹ̀ láti gbà á là.” Nígbà tí Jesu sì kígbe ní ohùn rara lẹ́ẹ̀kan sí i, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀, ó sì kú. Lójúkan náà aṣọ ìkélé tẹmpili fàya, láti òkè dé ìsàlẹ̀. Ilẹ̀ sì mì tìtì. Àwọn àpáta sì sán. Àwọn isà òkú sì ṣí sílẹ̀. Ọ̀pọ̀ òkú àwọn ẹni mímọ́ tí ó ti sùn sì tún jíǹde. Wọ́n jáde wá láti isà òkú lẹ́yìn àjíǹde Jesu, wọ́n sì lọ sí ìlú mímọ́. Níbẹ̀ ni wọ́n ti fi ara han ọ̀pọ̀ ènìyàn. Nígbà tí balógun ọ̀run àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ tí wọ́n ń sọ Jesu rí bí ilẹ̀ ṣe mì tìtì àti ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ẹ̀rù bà wọn gidigidi, wọ́n wí pé, “Lóòótọ́ ọmọ Ọlọ́run ní í ṣe!” Ọ̀pọ̀ obìnrin tí ó wá láti Galili pẹ̀lú Jesu láti tọ́jú rẹ̀ wọn ń wò ó láti òkèèrè. Nínú àwọn obìnrin ti ó wà níbẹ̀ ni Maria Magdalene, àti Maria ìyá Jakọbu àti Josẹfu, àti ìyá àwọn ọmọ Sebede méjèèjì wà níbẹ̀ pẹ̀lú. Nígbà tí alẹ́ sì lẹ́, ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan láti Arimatea, tí à ń pè ní Josẹfu, ọ̀kan nínú àwọn tí ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Jesu, lọ sọ́dọ̀ Pilatu, ó sì tọrọ òkú Jesu. Pilatu sì pàṣẹ kí a gbé é fún un. Josẹfu sì gbé òkú náà. Ó fi aṣọ funfun mímọ́ dì í. Ó sì tẹ́ ẹ sínú ibojì òkúta tí ó gbẹ́ nínú àpáta fúnrarẹ̀. Ó sì yí òkúta ńlá dí ẹnu-ọ̀nà ibojì náà, ó sì lọ.