Mat 27:1-5
Mat 27:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBATI o di owurọ̀, gbogbo awọn olori alufa ati awọn àgbãgba gbìmọ si Jesu lati pa a: Nigbati nwọn si dè e tan, nwọn mu u lọ, nwọn si fi i le Pontiu Pilatu lọwọ ti iṣe Bãlẹ. Nigbana ni Judasi, ẹniti o fi i hàn, nigbati o ri pe a dá a lẹbi, o ronupiwada, o si mu ọgbọ̀n owo fadaka na pada wá ọdọ awọn olori alufa ati awọn àgbãgba. O wipe, emi ṣẹ̀ li eyiti mo fi ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ hàn. Nwọn si wipe, Kò kàn wa, mã bojuto o. O si dà owo fadaka na silẹ ni tẹmpili, o si jade, o si lọ iso.
Mat 27:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, gbogbo àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbà ìlú jọ forí-korí nípa ọ̀ràn Jesu, kí wọ́n lè pa á. Wọ́n dè é, wọ́n bá fà á lọ láti fi lé Pilatu, gomina, lọ́wọ́. Nígbà tí Judasi, ẹni tí ó fi Jesu fún àwọn ọ̀tá rí i pé a dá Jesu lẹ́bi, ó ronupiwada. Ó bá lọ dá ọgbọ̀n owó fadaka pada fún àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbà. Ó ní, “Mo ṣẹ̀ ní ti pé mo ṣe ikú pa aláìṣẹ̀.” Wọ́n bá dá a lóhùn pé, “Èwo ló kàn wá ninu rẹ̀? Ẹjọ́ tìrẹ ni.” Judasi bá da owó náà sílẹ̀ ninu Tẹmpili, ó jáde, ó bá lọ pokùnso.
Mat 27:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní òwúrọ̀, gbogbo àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù tún padà láti gbìmọ̀ bí wọn yóò ti ṣe pa Jesu. Lẹ́yìn èyí, wọ́n fi ẹ̀wọ̀n dè é, wọ́n sì jọ̀wọ́ rẹ̀ fún Pilatu tí i ṣe gómìnà. Nígbà tí Judasi, ẹni tí ó fi í hàn, rí i wí pé a ti dá a lẹ́bi ikú, ó yí ọkàn rẹ̀ padà, ó sì káàánú nípa ohun tí ó ṣe. Ó sì mú ọgbọ̀n owó fàdákà tí ó gba náà wá fún àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù. Ó wí pé, “Mo ti ṣẹ̀ nítorí tí mo ti ta ẹ̀jẹ̀ aláìlẹ́ṣẹ̀ sílẹ̀.” Wọ́n dá a lóhùn pẹ̀lú ìbínú pé, “Èyí kò kàn wá! Wàhálà tìrẹ ni!” Nígbà náà ni Judasi da owó náà sílẹ̀ nínú tẹmpili. Ó jáde, ó sì lọ pokùnso.